Jump to content

Ayo Adesanya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayo Adesanya
Ọjọ́ìbí11 Oṣù Kẹjọ 1969 (1969-08-11) (ọmọ ọdún 55)
Ogun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
  • actress
  • producer
  • director
Ìgbà iṣẹ́1986–present

Ayọ́ Adésànyà (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 1969) jẹ́ àgbà òṣèrébìnrin, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì.[1][2] [3] Ó tún jẹ́ adarí àti olóòtú eré.[4][5] Ayo Adesanya máa ń ṣàfihàn nínuụ eré Yorùbá àti ti Gẹ̀ẹ́sì.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ijagu, ní ìlú Ijebu, ní Ipinle Ogun ni Ayo Adesanya ti wá, ìyẹn ní apá Gúúsù ti apá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Naijiria. Ilé-ìwè St. Anne's ní ìlú Ibadan ni ó ti kàwé, fún ti alákọ̀ọ́bèrẹ̀ àti ti girama. Lẹ́yìn náà, ó lọ University of Ibadan láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Mass Communication.[6]

Ayo Adesanya bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1986 lẹ́yìn tí ó sin orílẹ̀-èdè rẹ̀ tán, ìyẹn NYSC. Ní ọdún 1996, ó darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń ṣe eré àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Naijiria. Fíìmù Tunji Bamishigbin tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Palace ní wọ́n ti kọ́kọ́ se àfihàn rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́.[7] Ó padà darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tí ń ṣe fíìmù Yorùbá. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní darí eré, tó sì ń gbé eré jáde. Ó ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré jáde, ó sì ti darí eré púpọ̀.[8] Ayo Adesanya tún máa ń ṣe fíìmù Yorùbá àti ti Gẹ̀ẹ́sì.[9]

Ayo Adesanya fìgbà kan jẹ́ ìyàwó Goriola Hassan, àmọ́ wọ́n ò fẹ́ ara wọn mọ́ báyìí. Ó bí ọmọkùnrin kan.[10]

Díẹ̀ lára àwọn fíìmù rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Remember Your Mother (2000)
  • Dancer 2 ( 2001)
  • Tears in My Heart 2 (2006)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ayo Adesanya Finds Love Again". THISDAY LIVE. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Ruth Olurounbi. "I would have married Ayo Adesanya - Pasuma". tribune.com.ng. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Chioma, Ella (2021-04-04). "Actress Ayo Adesanya opens up on dating men in Yoruba movie industry". Kemi Filani News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-15. 
  4. "Ayo Adesanya Finds Love Again". THISDAY LIVE. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Ruth Olurounbi. "I would have married Ayo Adesanya - Pasuma". tribune.com.ng. Archived from the original on 24 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "My eyes are blessings from God - Ayo Adesanya - Vanguard News". Vanguard News. Retrieved 24 February 2015. 
  7. "I was never married to Goriola Hassan –Ayo Adesanya". The Punch. Archived from the original on 28 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Simplicity gives my life balance –Ayo Adesanya". The Punch. Archived from the original on 28 February 2015. Retrieved 24 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "I can never go back to my ex-husband –Ayo Adesanya, actress". The Sun (Nigeria). 10 June 2016. Retrieved 15 September 2016. 
  10. Latestnigeriannews. "My ex-husband and I were never legally married Ayo Adesanya". Latest Nigerian News. Retrieved 24 February 2015.