Ayodele Olofintuade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayodele Olofintuade
A picture of Ayodele Olofintuade
Ọjọ́ìbíAyọ̀délé Ọlọ́fintúádé
1970 (ọmọ ọdún 53–54)
Ìbàdàn, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
WebsiteOfficial website

Ayọdele Ọlọfintuade jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, oníròyìn àti ẹ̀yà abo. Ó ti ṣe àfihàn ara rẹ̀ gẹgẹ bíi ẹni tí kii ṣe alákọméjì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí ó ṣe ìlòdì sì LGBTQ .

Ìgbésí ayé e rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ayọdele Ọlọfintuade ní ìlú Ìbàdàn, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1970. Ní àárín Eko, Ibadan atí Abeokuta ni Olofintuade dàgbà sí. Ó ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ara rẹ̀ lórí ìwé kíkọ tí ó Yàn láàyò. Ní pàtàkì ni ó jé wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó ti kọ ni wọ́n dá lórí i ẹ̀yà abo ni ilé Áfíríkà, àwọn ohun tí ẹ̀mí ní ilẹ̀ Yorùbá (káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà títí tí o fí dé ẹ̀yà adúláwọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè ìlú aláwọ̀ funfun), LGBT ní orílè-èdè Nàìjíríà ní agbègbè àti èyà tí kò ní ìbámu ní orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọmọ méjì ni Ayọdele Ọlọfintuade bi. Orúkọ wọn a máa jẹ́ Alexander àti Kisha. A dáamọ̀ gégé bí queer, ati èyà abo tí kìí ṣe alákọméjì.

Àwọn ìwé tí ó ti kọ.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ pàtàkì tí ó jẹ tí Lítíréṣọ̀ ni ìtàn Eno, èyítí ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wé Cassava Republic ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọdún 2010, ìwé lórí ìtàn àwọn ọmọdé èyí tí wọ́n yàn láti gba ẹ̀bùn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fun ìwé Lítíréṣọ̀ tí ó dára jùlọ ní ọdún 2011. Ìwé Lítíréṣọ̀ yí sọ̀rọ̀ lórí gbígbé àwọn ọmọdé káàkiri láti lọ máa fí wọ́n ṣe òwò ẹrú, èyí tí ó ti ń mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọjọ́ tí ó tipẹ́.[1]

Ìwé átíkù pàtàkì àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ kọ lórí àwọn ènìyàn LGBTQ ti ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí àkọlé rẹ ń jẹ́ Ìbálòpọ̀ tí A-B-C lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà èyí tí àtẹ̀jáde rẹ̀ wáyé ní ọdún 2014 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́hìn tí wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò òfin ìgbéyàwó ako sí akọ àti abo sí abo ti ọdún 2013 gẹ́gẹ́ bí èyà lára àwọn irinṣẹ́ tí àwọn adájọ́ yio lò fún ìkéde òfin náà.[2] Ní àkókò yí kanna ni Olofintuade ṣe àtẹ̀jáde lára àwọn nofeli rẹ èyí tí àkọlé rẹ njé Adunni: eni arẹwà tí kò i tíì kú, èyí tí wọ́n tẹ jáde ní ọdún 2014 sí orí Brittle Paper nínú èyí tí díẹ̀ nínú àwọn tí ó kó ipa jẹ́ Queer.

Ọlọfintuade ma ńkọ ìwé fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọdé ní pàtàkì àwọn ọmọdé láti àwọn agbègbè tí kò fi bẹẹ ní anfààní tó. Óò tún jẹ́ ajà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn. Ìwé rẹ àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2011 ni ó wà lára àwọn ìwé tí wọ́n yà sí ọ̀tọ̀ fún ẹ̀bùn ti Nàìjíríà fún ti ìwé Lítíréṣọ̀. Orísirísi àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé àkọsílẹ̀ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wón ti ṣe àtẹ̀jáde àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó fi mọ́ Nigeriana Talk àti Anathema. Olofintuade tún jẹ́ Olùdarí àti Alàkóso fún ojú òpó tí wẹẹbu kan tí ó wà fún ipá òdì tí aidọgba.[3][4][5]

Ọlọfintuade ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣe, ẹ̀mí àti àṣà Yorùbá, ó jẹ́ lílọ pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́ òṣèré. Pẹ̀lú ka Laipo, ó pèsè àtìlẹ́yìn ètò A-B-C fún àwọn ọmọdé láti ìpínlè títí lọ dé ìpele ilé-ìwé gíga.[6][7][8]

Ìwé ìtàn àkọọ́lẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Eno's Story (Cassava Republic, 2010)
  • Lakiriboto Chronicles
  • The Whirlwind
  • Adunni: The Beautiful One Has not Yet Died
  • King of the Heap
  • King of the Heap Learns to Read
  • Children of the Rainbow

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "I Simply Write From A Place of Truth - In Conversation with Ayodele Olofintuade – Syncity NG". Syncity NG – Your hangout zone for everything African literature. 2019-07-17. Archived from the original on 2021-09-13. Retrieved 2021-09-13. 
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2014-07-05. Retrieved 2021-09-04. 
  3. "[Interview] Ayodele Olofintuade". Conversations with Writers. 2011-09-16. Retrieved 2021-09-13. 
  4. Ryman, About Geoff (2018-04-27). "Ayodele Olofintuade". Strange Horizons. Retrieved 2021-09-13. 
  5. Murua, James (2018-10-17). "Ayodele Olofintuade’s ‘Lakiriboto Chronicles’ is really good.". James Murua's Literature Blog. Archived from the original on 2019-10-08. Retrieved 2021-09-13. 
  6. Emelife, Jennifer (2018-12-17). "The Pen and The Sword: Ayodele Olofintuade". Praxis Magazine for Arts & Literature. Retrieved 2021-09-13. 
  7. Adejunmobi, M.; Coetzee, C. (2019). Routledge Handbook of African Literature. Taylor & Francis. p. 533. ISBN 978-1-351-85937-0. https://books.google.com.ng/books?id=ayeNDwAAQBAJ&pg=PT533. Retrieved 2021-09-13. 
  8. Branch, A.; Mampilly, Z. (2015). Africa Uprising: Popular Protest and Political Change. African Arguments. Zed Books. p. 118. ISBN 978-1-78032-999-4. https://books.google.com.ng/books?id=UhBkDgAAQBAJ&pg=PT118. Retrieved 2021-09-13.