Bùkọ̀lá Awóyẹmí
Bùkọ́lá Àwoyẹmí | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1988 Kwara |
Orúkọ míràn | Arugbá |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | òṣèrébìnrin |
Olólùfẹ́ | Dàmọ́lá Ọlátúnjí |
Bùkọ́lá Àwoyẹmí tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Arugbá, tí wọ́n bí lọ́dún 1988 jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Kwara lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Òun ni ìyàwó gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn tí ó ń jẹ́ Dàmọ́lá Ọlátúnjí.[1]Ó gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Arugbá látàrí ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí ògbóǹtarìgì òní-sinimá, Túndé Kèlání gbé jáde lọ́dún 2008.[2]
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Bùkọ́lá Arugbá ní ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 1988. Láti ìgbà èwe ni Bùkọ́lá tí fẹ́ràn láti di eléré tíátà. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ní Ìlọrin, University of Ilorin. Nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ló ti ń gbìyànjú láti máa ṣeré tíátà, ṣùgbọ́n ìràwọ̀ rẹ̀ kò tàn àfi ìgbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò tí Túndé Kèlání dárí lọ́dún 2008,tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Arugbá. Lẹ́yìn náà o tún kópa nínú "Poisonous Affair" àti àwọn sinimá-àgbéléwò gbankọgbì mìíràn lédè Yorùbá. "Ìgbà Ǹ Bá Jó" ni sinimá àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Bùkọ́lá Àwoyẹmí ṣe agbátẹrù rẹ̀ fún ara rẹ̀ lọ́dún 2013.
Àtòjọ díè nínú àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Arugbá
- Poisonous Affair
- Church on Fire
- Akpochereogu
- Ire Okùnkùn
- Ìgbà Ǹ Bá Jó
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "My husband criticises me when I don’t kiss well in movies –Bukky Arugba – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2020-02-16.
- ↑ Published (2015-12-15). "I’m back to my life –Arugba". Punch Newspapers. Retrieved 2020-02-16.