Dàmọ́lá Ọlátúnjí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Dàmọ́lá Ọlátúnjí
Ọjọ́ìbíỌjọ́ kejì oṣù kejì
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaCollege of Technology (YABA TECH)
Iṣẹ́Osere
Olólùfẹ́Bùkọ́lá Awóyẹmí

Dàmọ́lá Ọlátúnjí tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejì oṣù kejì (February 2nd) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Dàmọ́lá ní ọkọ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, Bùkọ́lá Awóyẹmí , tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Arugbá.[1] Kí Dàmọ́lá tó fẹ́ Arugbá, ìyàwó àkọ́fẹ́ rẹ̀ ni Raliat Abíọ́dún. Wọ́n ti pínyà. [2] [3]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dàmọ́lá Ọlátúnjí jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n bí I lọ́jọ́ kejì oṣù kejì. Láti ìgbà èwe rẹ̀ ni ó ti fẹ́ràn ère tíátà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti kópa nínú eré orí ìtàgé. Ilé Ifẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lo tí kàwé ní kékeré rẹ̀. Ilé ìwé Yaba College of Technology (YABA TECH), ní ìpínlẹ̀ Èkó, níbi tí ó ti kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Yọ̀mí Fash-Láńsò, nígbà náà ló kópa pàtàkì nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Òjò", tí Ọpẹ́yẹmí Ayéọ̀la kọ. Lẹ́yìn èyí, Dàmọ́lá tí kópa, bẹ́ẹ̀ ó sìn ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Akintola, Gabriel (2017-04-04). "Interesting facts about Damola Olatunji's wife and children". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-02-16. 
  2. "Damola Olatunji Biography - Age, Wikipedia, Family & Pictures". 360dopes. 2018-11-20. Retrieved 2020-02-16. 
  3. "My husband criticises me when I don’t kiss well in movies –Bukky Arugba". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-02-16.