Jump to content

Balogun Yakub Abiodun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Balógun Yakub Abíọ́dún)
Yakub Abiodun Balogun
Member of the Federal House of Representatives of Nigeria
In office
2011–2015
ConstituencyLagos, Lagos Island Federal Constituency II
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí5 Oṣù Kẹrin 1951 (1951-04-05) (ọmọ ọdún 73)
Lagos State, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress (APC)
ResidenceLagos and Abuja
Alma materUniversity of Ibadan

Yakub Abiodun Balogun (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù karun ọdún 1951) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria tí ó mọ̀ nípa ètò ọrọ̀-ajé, olùdarí ètò ìṣèjọba, aṣòfin ní Ileé aṣojú-ṣòfin kéréré ní orílẹ̀-èdè Naijiria, tí ó ń ṣojú fún Lagos Island Federal Constituency II, Ipinle Eko, South-West Nigeria àti olùtọ́jú aṣojú ti ìpínlẹ̀ Èkó nígbà kan rí. [1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Balogun Yakub ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún, ọdún 1951 ní Lagos Island.[3] Ilé-ìwé Fazil-Omar Ahmadiyya ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni ó lọ kí ó tó lọ ilé-ìwé girama ti Ansar-Ud-Deen ní Surulere, àmọ́ ó gba ìwé-ẹ̀rí WAEC ní Ahmadiyya College, ní Agege. Ó gboyè B.Sc. àti masters nínú ẹ̀kọ́ EconomicsUniversity of Ibadan ní ọdún 1976 àti 1983 kí ó tó lọ Royal Institute of Public Administration níbi tí ó ti gb a ìwé-ẹ̀rí Public administration ní ọdún 1996.

Ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìjọba ti ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1977 gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé kékeré ní ẹ̀ka tó ń rí sí ìdàgbàsókè àti ìfilélẹ̀ ètò ajé. Ní ọdún 1990, ó lọ sípò olùdaríkejì fún àwọn orí-orí, ní àjọ tó ń rí sí ètò-ìṣúná.[4][5] Lẹ́yìn tó ti sìn ní onírúurú ọ̀nà, wọ́n yàn án sípò akọ̀wé àgbà ní àjọ tó ń rí sí ètò ìṣúná, ní ọdún 1997. Ó sì wà nípò yìí títí wọ́n tún fi yàn án sípò olórí àwọn òṣìṣẹ́, ní ọdún 1999, lábẹ́ ìṣèjọba olóyè Bola Tinubu, tó fìgbà kan jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, àti adarí àgbà ẹgbé òṣèlú All Progressives Congress (APC).[1] Ní oṣù kaùn-ún, ọdún 2010, ó fẹ̀yìntì nídìí iṣẹ́ ìjọba láti wọ ẹgbẹ́ òṣèlú.[6]

Iṣẹ́ òṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù kẹrin, ọdún 2011, ódíje fún ipò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, Lagos Island Federal Constituency II, tí ó sì wọlé.[7] Balogun jẹ́rìí sí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, tó dúró fún, Lagos Island Federal Constituency II, Lagos State, ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹfà, ọdún 2011.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "In APC, Consensus Arrangements Take Away the Fire of Competition, Articles - THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2015-03-20. Retrieved 2015-04-16.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Lagos National Assembly Members Endorse Ambode as next Lagos Governor". TheNigerianVoice. 
  3. "Balogun Yakub Abiodun". notablenigerians.com. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 16 April 2015. 
  4. "Fashola’s ‘Boys’ Gunning For Elective Posts - P.M. NEWS Nigeria". pmnewsnigeria.com. 
  5. "Former HOS, Hon. Yakub Balogun Wins APC Primaries in Lagos". starconnectmedia.com. Archived from the original on 2015-05-26. Retrieved 2015-04-16.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Accolades As Lagos HOS Bows Out, Eyes House Of Reps Seat - P.M. NEWS Nigeria". pmnewsnigeria.com. 
  7. "Lagos APC primaries: Dabiri, Bamigbetan withdraw as newcomers floor incumbents". Vanguard News. 
  8. "LASG urges residents to quit flood prone areas". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2015-04-16. Retrieved 2015-04-16.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)