Jump to content

Basketmouth

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Basketmouth
Basketmouth at AMVCA 2020
Orúkọ àbísọBright Okpocha
Ìbí14 Oṣù Kẹ̀sán 1978 (1978-09-14) (ọmọ ọdún 46)
Lagos State, Nigeria
Medium
  • Stand-up
  • film
  • television
  • music
Ajẹ́ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Years active2000–present
Genres
Subject(s)
Ibiìtakùnbasketmouth.tv

Bright Okpocha (tí a bí ni ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹ́sàn-án ọdún 1978 ní Ìpínlẹ̀ Èkó), tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Basketmouth tí gbogbo ènìyàn mò sí, jẹ́ apanilẹ́rìín àti òṣèré ọmọ Nàìjíríà. Ó ti ṣètò àwọn eré orin àwàdà ìmurasílẹ̀ olókìkí bíi "Basketmouth Uncensored" káàkiri àgbáyé.

Basketmouth ti gbàlejò ìpeníjà àwàdà kan lórí Instagram, tí a pè ní "TwoThingsChallenge" èyí tí ó fa ariwo láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́, lẹ́hìn ìgbàtí ọ̀dọ kan ti fi fídíò kan hàn tí ó sọ àwọn nǹkan àìfọkànbalẹ̀ tí ó jọmọ́ ìbálòpọ̀, pẹ̀lú ọmọ kan ní wíwò ìsúnmọ́ nínú fídíò náà.[1]

Ó jẹ́ olùpìlèsè ti "Ghana Jollof".[2]

Ìtàn Ìgbésí Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n bí Bright Okpocha ṣùgbón ó wá láti ìpínlẹ̀ Abia ní Nàìjíríà. Ó parí ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ ti girama ní Apapa, Ìpínlẹ̀ Èkó, ó sì lọ sí Fásítì ti Benin, Ìpínlẹ̀ Edo láti kọ́ ẹ̀kọ́ fún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa "Sociology" àti "Anthropology". Ó ṣe àwárí ọgbọ́n rẹ̀ ní ìlù lílù ní ọdún 1991 pẹ̀lú atẹ̀le nípa gbígbé "rapping" ní ọdún 1994. Lẹ́hìn náà ó dá ẹgbẹ́ kan tí a pè ní “Da Psychophats” tí ó ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méje àti pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ fún eré àti "rapping" ní ọdún 1995, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n yapa ṣáájú ìdásílẹ̀ èyíkéyìí ohun èlò k'ọkan. Ó tẹ̀síwájú láti dá ẹgbẹ́ "rap" mìíràn tí a mọ̀ sí "Da Oddz" pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Godwin àti Muyiwa Ola-Phillips: wọ́n ṣe eré bíi mélòó kan ṣùgbọ́n wọn kò kógojá nítorí àmì ìyasọ́tọ̀ ti "rap" wọn kò ṣéé gbà ní Nàìjíríà.[3]

Bright parí ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀ ní Apapa (Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà) lẹ́yìn náà ó lọ gbóyè ní Yunifásítì ti Benin níbi tí ó ti ka ẹ̀kọ́ sociology ati anthropology pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ Godwin.[4]

In 2000, Basketmouth appeared in Lagbaja music video titled Gra Gra.

Ní ọdún 2005 àti 2006, Basketmouth gba Ààmì Ẹ̀yẹ Àpanilẹ́rìín ti Orílẹ̀-èdè àti àwọn ẹ̀bùn fún Àpanilẹ́rìín Ìdúró tí ó dára jùlọ ti ọdún náà.

[5] Ó jẹ́ yíyan ní ẹ̀dá ọdún 2021 "maiden edition of The Humour Awards Academy" lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpanilẹ́rìín ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Mr Funny. [6]

Basketmouth farahàn nínú iṣàfihàn Africa Magic "My Flatmates" ní ọdún (2016).

Láìpẹ́ yìí Basketmouth ti gbàlejò olówó àti ọlọlà Nàìjíríà Femi Otedola ní ilé rẹ̀. [7]

Ní Oṣù Kejìlá ọdún 2020, ó bẹ̀rẹ̀ jara eré àwàdà rẹ̀ ti àkọ́lé “Papa Benji”[8]

Ní Oṣù kọkànlá ọdún 2010, Basketmouth fẹ́ ọ̀rẹ́-bìnrin rẹ̀ tipẹ́ Elsie ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà. Wọ́n ní ọmọ mẹ́ta papọ̀. Ní Oṣù Kejìlá ọdún 2022, Basketmouth kéde nípasẹ̀ àkọọlẹ Instagram iṣẹ́ rẹ̀ pé òun àti ìyàwó rẹ̀ ń kọ́ ara wọn sílẹ̀ lẹ́hìn ọdún méjìlá ti ìgbéyàwó. [9] [10]

Àwọn Ààmì Ẹ̀yẹ Àti Yíyan

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Year Award Category Work Result Ref
2022 Africa Magic Viewers' Choice Awards Best Africa Magic Original Comedy Series My Flatmates Wọ́n pèé [11]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. MTVBase (2013-11-22). "Basketmouth arrested in the UK". MTVBase. Retrieved 2013-11-22. 
  2. BellaNaija.com (2021-07-16). "Superstar Comedian Basketmouth serves "Ghana Jollof" – Here's How You can Audition for the Showmax Original". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-08-11. 
  3. "Comedian BASKETMOUTH Full Biography,Life And News". T.I.N. Magazine. 19 July 2015. Retrieved 10 August 2016. 
  4. Informationng (2014-08-02). "Basketmouth's Book: Before I Write A Book Part 2". Informationng. Retrieved 2014-08-02. 
  5. Abisola Alawode & Jumoke Rufus (2014-01-10). "What Did Basketmouth Do Wrong?". Leadership. Archived from the original on 2014-02-23. Retrieved 2014-01-10.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. vanguardngr.com (2021-10-06). "The Humour Awards Academy releases nomination list-Vanguard". Vanguard (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-11-09. 
  7. "Basketmouth Hosts Billionaire, Femi Otedola in His Home – Premium Times International". Archived from the original on 2018-07-31. Retrieved 2018-07-31.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "It's Finally Here! Watch the First Episode of Basketmouth's Comedy Series "Papa Benji"". BellaNaija. BNTV. 2020-12-14. Retrieved 2021-02-18. 
  9. "Comedian Basketmouth Missing in the Cut As Wife Elsie Releases Family Christmas Photo With Their Children". Legit.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-12-25. Retrieved 2022-12-27. 
  10. "Comedian, Basketmouth, announces marriage crash". Vanguard NGR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-12-23. Retrieved 2022-12-27. 
  11. "Queen Osas, best actress, AMVCA 2022". The Cable NG. https://www.thecable.ng/queen-osas-best-actress-amvca-2022.