Beni Lar
Beni Lar | |
---|---|
Aṣojú ilé ìgbìmò Asòfin kékeré ti Langtang North, Langtang South Federal Constituency of Plateau State | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | August 12, 1967 |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | People's Democratic Party (PDP) |
Àwọn òbí | Solomon Lar and Prof. Mary Lar |
Occupation | Politician |
Beni Lar (tí a bí ní ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹjọ ọdun 1967) jẹ́ olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ People's Democratic Party láti Ìpínlẹ̀ Plateau, Nàìjíríà. Ó jẹ́ asojú ìkọ̀ Langtang North àti Langtang South ti Ìpínlẹ̀ Plateau ní ilé ìgbìmò asofin kékeré.[1] A kọ́kọ́ yán sí ipò náà ní 2007, wọ́n sì tún dìbò yán ni ọdun 2019 fún sáà kẹrin ní ipò náà.[2]
Ìtàn ayé àti iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òun ni ọmọbìnrin àkọ́kọ́ Solomon Lar, Gómínà ìpínlẹ̀ Plateau tẹ́lẹ̀rí àti ọ̀jọ̀gbọ́n Mary Lar. Beni wípé,
“Bàbá mi kọ́ mi pé kò sí ìyàtọ̀ láàrin ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó kó mi láti jẹ́ onísẹ́ takuntakun; nítorí náà, mo gbìyànjú láti jẹ́ agbẹjọ́rò bi bàbá mi."[3]
Ó gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti má gbàgbé isẹ́ takuntakun tí bàbá rẹ̀ se láti mú ìsokan, àlàáfíà àti ìfẹ́ wà, ó ní pe àwọn nkan yìí jẹ́ àwọn ǹkan tí ó se pàtàkì láti mú kí Nàìjíríà tẹ̀ síwájú.[4]
Ní ọdun 2007, a dìbò yán sí ilé ìgbìmò aṣòfin kékeré.[5] Ní ọdun 2008, ilé ìgbìmò asòfin yàn gẹ́gẹ́ bi alága ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré lórí ọ̀rọ̀ obìnrin.[6]Títí di Oṣù Keje 2014[update], ó jẹ́ asojú Ikọ̀ Langtang North àti South. Ó tún jẹ́ Alága ilé ìgbìmò aṣòfin lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ènìyàn.[7][8]
Ó fọwọ́ sí fífi owó ran ààjọ National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP) lọ́wọ́,[9] fífi owó líle òfin mú àwọn tí ó ń bá ọmọdé ṣe ǹkan àìtó[10] àti dídá ààjọ National Child Protection and Enforcement Agency kalẹ̀.[11]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Lawmaker wants more funds for science and technology". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-20. Archived from the original on 2022-02-22. Retrieved 2022-02-22.
- ↑ "Beni Lar Returns to Reps in a Landslide". The Lagosian Magazine Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-01. Archived from the original on 2020-11-29. Retrieved 2020-02-24.
- ↑ "The pillar of my life is gone, says Beni Lar". Vanguard News. 16 October 2013. http://www.vanguardngr.com/2013/10/pillar-life-gone-says-beni-lar/.
- ↑ "Eight Months Later, Mrs Jonathan Promises To Stand By Lar's Widow". Information Nigeria. 24 June 2014. http://www.informationng.com/2014/06/eight-months-later-mrs-jonathan-promises-to-stand-by-lars-widow.html.
- ↑ "Nigerian Women who will shape Seventh National Assembly". Nigeria Daily News. 6 July 2011. Archived from the original on 29 March 2014. Retrieved 18 July 2014.
- ↑ Godwin, Ihemeje (August 2013). "The need for participation of women in local governance: A Nigerian Discourse". International Journal of Educational Administration and Policy Studies 5 (4): 59–66. https://files.eric.ed.gov/fulltext/EJ1084169.pdf.
- ↑ Hamza Idris; Yahaya Ibrahim (15 July 2014). "Nigeria: 38 Killed As Boko Haram Attacks Borno Village". Daily Trust – AllAfrica. http://allafrica.com/stories/201407150905.html.
- ↑ Murdock, Heather (28 April 2014). "Abuja Blast Impacts Lives, Livelihoods". Voice of America. Retrieved 18 July 2014.
- ↑ "House committee seeks emergency funds for NAPTIP". P.M. NEWS Nigeria. 11 May 2014. http://www.pmnewsnigeria.com/2014/05/11/house-committee-seeks-emergency-funds-for-naptip/.
- ↑ "House C'ttee on Health calls for amendment of law on child abuse". Radio Nigeria: News. Retrieved 18 July 2014.
- ↑ "Establish Child Protection, Enforcement agency- Lar – Vanguard News". Vanguard News. 18 May 2014. http://www.vanguardngr.com/2014/05/establish-child-protection-enforcement-agency-lar/.