Benito Mussolini

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Benito Mussolini
Mussolini biografia.jpg
40th Prime Minister of Italy
Lórí àga
31 October 1922 – 25 July 1943
Monarch Victor Emmanuel III
Asíwájú Luigi Facta
Arọ́pò Pietro Badoglio (Provisional Military Government)
First Marshal of the Empire
Lórí àga
30 March 1938 – 25 July 1943
Arọ́pò Pietro Badoglio
Duce of the Italian Social Republic
Lórí àga
23 September 1943 – 26 April 1945
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ìbí 29 Oṣù Keje, 1883(1883-07-29)
Predappio, Forlì, Italy
Aláìsí 28 Oṣù Kẹrin, 1945 (ọmọ ọdún 61)
Giulino di Mezzegra, Italy
Ọmọorílẹ̀-èdè Italian
Ẹgbẹ́ olóṣèlú Republican Fascist Party
(1943-1945)
National Fascist Party
(1921-1943)
Italian Socialist Party
(1901-1914)
Tọkọtaya pẹ̀lú Rachele Mussolini
Profession Politician, Journalist
Ẹ̀sìn "Converted" to Roman Catholicism in 1927, atheist in earlier life.

Benito Mussolini je oloselu omo orile-ede Italia. Wón bí Benito ní 1883. Ó kú ní 1945. Òun ni ó dá Fasisti sílè ní Italy. Òun ni ó darí Italy ní 1922 sí 1943. Agbára ni ó fi n darí ilè náà (a dictator). It Duce tí ó dúró fún olórí (the leader) ni àwon èyìn rè máa n pè é. Mussolini àti ìgbìmò Fascist Party ni won jo n darí Italy. Won kò gba alátakò kankan láyè.

Gégé bí ajàfún-mèkúnnù (socialist) ni Mussohni se wo òsèlú. Ó jé olóòtu ìwé-ìróyìn kan tí ó n jé ní Avanti sùgbón ní 1914, ó dá ìwé-ìroyìn tirè sílè. Ó pè é ní IL Popolo d’Italia. Ní odún 1921 ni ó dá egbé òsèlú Fascist sile. Èrò tí ó ní nípa dídá egbé òsèlú yìí sílè ni láti lè tún Italy kó kí ó sì so ó di ìlú tí ó lágbára. Léyìn ìgbà tí àwon Fascist rìn lo sí Róòmù ní 1922 (‘Fascist March on Rome’), Oba Victor Emmanuel III pe Mussoline láti wá gbé ìjoba tirè kalè. Kò pé tí àwon Fascist bèrè síí darí ilè Italy.

Àwon omo ogun Mussoline kolu Ethopia ní 1905 wón sì ségun ibè léyìn òpòlopò ìjà tí ó gbóná. Kò pé tí Mussolini ní kí àwon omo ogun òun lo ran General Franco lówó nínú ogun abélé ilè Spain. Ní 1940, Italy bèrè síí kópa nínú ogun àgbáyé kejì. Italy dúró gbá gbá gba ti Germany sùgbón wón ségun Italy. Won di ebi ifidíremi Italy yìí ru Mussolini. Wón gba ìjoba lówó rè wón sì so ó sí èwòn. Àwon German gba á sílè ó wa di olórí ìjobá tí kò fesè múlè kan. Ní odún 1945, àwon tí ó n jà rí i mú, wón sì pa á.


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]