Jump to content

Bilikis Adebiyi Abiola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bilikiss Adebiyi
in 2019
Ọjọ́ìbíLagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànBilikiss Adebiyi Abiola
Ẹ̀kọ́
Gbajúmọ̀ fúnCEO of Wecyclers

Bilikiss Adebiyi tàbí Bilikiss Adebiyi-Abiola jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó dá ilé iṣẹ́ àtúnlò ‘Wecyclers’ sílẹ̀ Èkó.[1] Ní ọdún 2022 ó jẹ́ Olùdarí Gbogbogbòò ti Lagos State Records and Archives Bureau (LASRAB)[2] àti Alákooso ti Lagos State Parks and Gardens Agency (LASPARK).[3] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Board of Trustees ti Employment Trust Fund ti Ìpínlẹ̀ Èkó.[4]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Adebiyi ní ọdún 1983[5]Ìlú Èkó, Nàìjíríà, níbi tí ó ti lọ sí ilé-ìwé gíga Supreme Education Foundation. Ó wọ Yunifásítì Ìlú Èkó, ṣùgbọ́n ó fi sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún kan láti parí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Amẹ́ríkà. Ó gboyè jáde ní Yunifásítì Fisk, lẹ́yìn náà ó lọ sí Yunifásítì Vanderbilt, níbi tí ó ti gba oyè kejì. Ó ṣiṣẹ́ fún IBM fún ọdún márùn-ún ṣáájú kí ó tó pinnu láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n gbà á láti lọ kàwé fún Master of Business Administration (MBA) ní Massachusetts Institute of Technology (MIT).

Bilikiss Adebiyi Abiola on Ndani TV

Ó wá pẹ̀lú ìmọ̀ràn ti ìṣòwò àtúnlò ní àkókò ọdún kejì rẹ̀ ní MIT, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀gbín bí àkọ́lé amọ̀dájú rẹ̀. Èrò tó kọ́kọ́ wá sí i lọ́kàn ni pé kó lè mú kí iye pàǹtírí tó lè kó jọ nínú ilé pọ̀ sí i nípa fífún àwọn èèyàn tíkẹ́tì fún àwọn géémù. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa èyí ní Nàìjíríà nígbà ìsinmi, ó yà á lẹ́nu bí àwọn èèyàn ṣe fi ìtara tẹ̀lé èrò rẹ̀.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Bilikiss Adebiyi-Abiola". The Tony Elumelu Foundation (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-05-27. 
  2. "Principal Officers – Lagos State Record And Archives Bureau, LASRAB" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-11-09. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "Bilikiss Adebiyi-Abiola". The Martin Trust Center for MIT Entrepreneurship (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-08. 
  4. "Principal Officers". Lagos State Parks and Gardens Agency (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-09-24. Retrieved 2022-10-08. 
  5. Adebiyi-Abiola, Bilikiss; founder; WeCyclers.Born1983Lagos, CEO of; University, NigeriaNationalityNigerianAlma materFisk; University, Vanderbilt; WeCyclersWebsitelinkedin, MITOccupationCEO of WeCyclersKnown forfounding. "Bilikiss Adebiyi-Abiola - Disrupting Africa". disruptingafrica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-09-28. Retrieved 2023-09-28.