Bodija

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Bódìjà ni àdúgbò kan ní ìlúÌbàdàn, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Àdúgbò yí di gbajú gbajà pẹ̀lú ilé ìgbé alákọ̀ọ́pọ̀ tí wọ́n kọ́ síbẹ̀ láàrín ìgboro ìlúìbàdàn lẹ́yìn ìgbòmìnira ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1960. Irúfẹ́ ilé ìgbé méjì ni ó wà ní àdúgbò náà, àkọ́kọ́ ni bódìjà ayé àtijọ́ àti bódìjà tìgbàlódé, bẹ́è sì ni ó tún jẹ́ ilé ìgbé fún ọ̀pọ̀lopọ̀ ilé ìwé tí ó wà ní agbègbè náà. Bákan nàá ni àdúgbò yí tún ní ọjà ńlá kan tí tẹrú tọmọ ń ná ìyẹn: Ọjà Bódìjà èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ọjà tí ó tóbi jùlọ ní ìgboro Ìbàdàn.

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]