Carol King (actress)
Carol King | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Caroline Eferamor King 24 July 1963[1] Lagos, Lagos State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Ahmadu Bello University Lagos State University |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 1999–present |
Olólùfẹ́ | Kolawole King |
Àwọn ọmọ | 3 |
Carol King (tí a bí ní 24 Oṣù Keèje, Ọdún 1963) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ jùlọ fún ipa rẹ̀ bi "Jùmọ̀kẹ́" nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Everyday People.[2] Carol jẹ́ ẹnìkan tí ó maá n sábà kó ipa ìyá lọ́pọ̀lọpọ̀ nínu àwọn eré, ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ hàn nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò bíi The Gods Are Still Not To Blame àti Dazzling Mirage ti Túndé Kèlání.[3]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Carol ní Ìlú Èkó, sí ọwọ́ àwọn òbí tí wọ́n wá láti Ìpínlẹ̀ Ẹdó. Carol lọ sí ilé-ìwé St. Soweto Primary School àti Awori Anglican Comprehensive High School ní Ìlú Èkó, fún ètò ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama rẹ̀.[4] Ó tẹ̀síwájú láti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ Ìmáàdánidófò ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Àmọ́dù Béllò ṣáájú kí ó tó tún wá gba oyè-ẹ̀kọ́ míràn nínu ìmọ̀ Ẹ̀sìn krìstẹ́nì láti Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó.[5]
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Caroline King ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ó sì ti di aládélórí pẹ̀lú fífẹ́ Captain Kọ́láwọlé King, ẹnití ó ti bí ọmọ mẹ́ta fún.
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ òṣèré Carol bẹ̀rẹ̀ nígbà kan tí ó fi lọ fún àyẹ̀wò eré rẹ́díò kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ I Need To Know ṣáájú kí ó tó tẹ̀síwájú láti kópa nínu eré Everyday People.[6] Ó kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré ìpele àti àwọn sinimá àgbéléwò tó fi mọ́ Dazzling Mirage, Pasito Dehinde àti The Gods Are Still Not To Blame. Fún ipa rẹ̀ láti mú ìlosíwájú débá agbo eré sinimá ṣíṣe, wọ́n yẹ́ Carol sí pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ "African Youth Role Model Award" ní ọdún 2009.[7]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- I Need To Know
- Everyday People
- Tinsel
- Everyday People
- Edge of Paradise
- Blaze of Glory
- Eko Law[8]
- Emerald
- Skinny Girl In Transit
Eré ìpele
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- V Monologues
- Ajayi Crowther
- Five Maidens of Fadaka
- Prison Chronicles
- The Wives[9]
Àwọn sinimá àgbéléwò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Pasito Dehinde
- Dazzling Mirage
- For Colored Girls
- The Gods Are Still Not To Blame
- Journey To Self
- North East
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Chidumga Izuzu (24 July 2015). "Top 5 films of the talented veteran". Pulse Nigeria. Archived from the original on 24 September 2015. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Adeola Adeyemo (18 April 2013). "From TV to the Big Screen! Nigerian Soap Opera Sweetheart Carol King stars in "The Gods Are Still Not To Blame" alongside Ireti Doyle, Nobert Young, Gabriel Afolayan & More, Speaks on Her Family, Career & Movie Role". BellaNaija. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Olamide Jasanja (10 April 2013). "Bukky Ajayi, Dele Odule, Ireti Doyle, Nobert Young star in movie adaptation of ‘The gods are not to blame'". Nigerian Entertainment Today. Archived from the original on 20 June 2017. https://web.archive.org/web/20170620050548/http://thenet.ng/2013/04/bukky-ajayi-dele-odule-ireti-doyle-nobert-young-star-in-movie-adaptation-of-the-gods-are-not-to-blame/. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Nike Bakare (15 March 2014). "Carol King: Nudity not big deal". The Sun. http://www.sunnewsonline.com/new/carol-king-nudity-big-deal/. Retrieved 25 August 2015.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Samuel Olatunji (14 April 2013). "Caroline King: Nollywood and my 22-year-old marriage". The Sun. http://sunnewsonline.com/new/caroline-king-nollywood-and-my-22-year-old-marriage/. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Chidumga Izuzu (30 July 2015). "Do you remember hit TV series 'Everyday People?'". Pulse Nigeria. Archived from the original on 3 August 2017. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Chidumga Izuzu (30 July 2015). "Do you remember hit TV series 'Everyday People?'". Pulse Nigeria. Archived from the original on 3 August 2017. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ Chidumga Izuzu (23 July 2015). "Watch Monalisa Chinda, Carol King, Bimbo Manuel, Ronke Oshodi Oke in teaser". Pulse Nigeria. Archived from the original on 19 August 2015. Retrieved 25 August 2015.
- ↑ "Kate Henshaw, Carol King, Others Star In The Wives". P.M. News. 11 July 2011. http://www.pmnewsnigeria.com/2011/07/11/kate-henshaw-carol-king-others-star-in-the-wives/. Retrieved 25 August 2015.