Caroline Danjuma
Caroline Danjuma | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Caroline Uduak Abasi Ekanem |
Ẹ̀kọ́ | University of Calabar Edinburgh Business School |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004-2007; 2015-iwoyi |
Olólùfẹ́ | Musa Danjuma (sep. 2016) |
Àwọn ọmọ | 3 |
Caroline Danjuma, tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ bi Caroline Ekanem, jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà kan. Ó ṣe ìṣàfihàn àkọ́kọ́ rẹ̀ lóju amóhù-máwòran ní ọdún 2004, níbi tí ó ti kópa nínu àwọn gbajúmọ̀ fíìmù kan láti ọwọ́ Chico Ejiro. Lẹ́hìn fífi iṣẹ́ fíìmù sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, ó ṣe ìpadàbọ̀ ní ọdún 2016, tí ó sì kópa nínu eré afìfẹ́hàn aṣaragágá kan ta pe àkọ́lé rẹ̀ ní Stalker, èyí tí ó ṣe pé òun náà ló ṣe àgb́ejáde rẹ̀.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Caroline ni a bí sí ọwọ́ bàbá tí n ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Skọ́tílàndì àti ìyá rẹ̀ tí n ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Òun ni àkọ́kọ́ àwọn ọmọ mẹ́ta ti òbí rẹ̀.[3] Ó kẹ́ẹ̀kọ́ ìṣàkóso ààbò àyíká, ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ayé àti ṣ́iṣètò agbègbè ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Calabar.[4] Ó tún gba ìwé-ẹ̀rí àṣeyọrí nínu ìmọ̀ ìhùwàsí ààjọ láti Edinburgh Business School ní ọdún 2016.[5][6]
Iṣẹ́ òṣèré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nípasẹ̀ Rita Dominic, Chico Ejiro ṣe àfihaǹ Danjuma níbi fíìmù 2004 kan Deadly Care. Lẹ́hìn náà ló kópa nínu àwọn fíìmù aláṣeyọrí míràn tó fi mọ́ Deadly Kiss (2004), Missing Angel (2004), The Captor (2006), Foreign Affairs, Real Love, The Twist, A Second Time àti The Beast and the Angel. Fíìmù titun rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ni Stalker, tó n sàfihàn Jim Iyke àti Nse Ikpe Etim.Ní Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 2017, ààjọ Pan-African kan dá Danjuma lọ́lá fún àwọn ètò àgbàwí rẹ̀ tí ó dá lóri mímú ìlọsíwájú bá àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.[7]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Danjuma di ẹni tí kìí kópa mọ́ lóòrèkóòrè nínu eré Nollywood lẹ́hìn ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lu Musa Danjuma, àbúrò Theophilus Danjuma ní ọdún 2007.[8][9] Àwọn tọkọtaya náà ní àwọn ọmọkùnrin méjì àti ọmọbìnrin kan.[10] Wọ́n pínyà ní ọdún 2016.[11]
Àríyànjiyàn lóri ọjọ́ orí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀jáde n tọ́ka sí ọdún bíbí rẹ̀ láti jẹ́ ọ̀kan láàrin 1980 tàbí 1981,[12] Danjuma ti sọ láìmọye ìgbà pé 26 Oṣù Kẹẹ̀fà, Ọdún 1987 ni ọjọ́ ìbí òun.[13][14][15]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Caroline Danjuma is 34 years old". Pulse GH. Archived from the original on 13 October 2016. Retrieved 23 June 2016.
- ↑ "Nollywood actress Danjuma turns 33". The Eagle Online. Retrieved 23 June 2016.
- ↑ "I have never compromise my body for money.......Caroline Ekanem Danjuma". Modern Ghana. Retrieved 23 June 2016.
- ↑ "Why I married Danjuma". Newswatch Times. Archived from the original on 30 April 2016. Retrieved 23 June 2016. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Actress Caroline Danjuma to embark on MBA in Oil & Gas". Nigerian Voice. Retrieved 21 September 2016.
- ↑ "Actress Caroline Danjuma flaunts MSc certificate". 9jaflaver. Retrieved 20 September 2016.
- ↑ "Caroline Danjuma Wins 2017 Mandela Award". TheTideNewsOnline.com. Nigeria: Rivers State Newspaper Corp. 11 August 2017. Retrieved 2 December 2017.
- ↑ "Caroline Ekanem stages comeback". http://www.vanguardngr.com/2013/07/caroline-ekanem-stages-comeback/. Retrieved 25 June 2016.
- ↑ "The Lady Behind Caroline Danjuma’s Marriage Crash Finally Revealed". Stargist. Iconway Media. Retrieved 24 June 2016.
- ↑ "Caroline Danjuma & Husband Celebrate the 1st Year Birthday of their Daughter Elizabeth". Bella Naija. 4 October 2015. Retrieved 31 July 2016.
- ↑ "Caroline Danjuma & Husband Celebrate the 1st Year Birthday of their Daughter Elizabeth". Bella Naija. 4 October 2015. Retrieved 31 July 2016.
- ↑ "Actress Caroline Ekanem stages comeback". Vanguard. Retrieved 20 July 2013.
- ↑ "Caroline Danjuma Shares Photo of Her Master's Degree ID Card to Prove She is 28". Gistmania. Retrieved 20 September 2015.
- ↑ "Actress/Businesswoman Caroline Danjuma Full Biography,Life And News". takemetonaija. Retrieved 19 October 2015.
- ↑ "Caroline Danjuma Biography And Movies". naijaquest. Retrieved 10 March 2016.