Jump to content

Charlotte Obasa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Oloori
Charlotte Ọbasá
Ọjọ́ìbíJanuary 7, 1874
Lagos
AláìsíDecember 23, 1953(1953-12-23) (ọmọ ọdún 79)
Lagos
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànCharlotte Blaize
Iṣẹ́Philanthropist
Gbajúmọ̀ fúnBeing the founder of the Anfani Bus Service
Olólùfẹ́Omoba Orisadipe Obasa
Àwọn ọmọ5
Àwọn olùbátanAkinola Maja (son-in-law)

Lola Maja (great-granddaughter )

Kòfowórọlá Adémọ́lá (niece)

Charlotte Olajumoke Ọbasá (tí orúkọ ìbí rẹ̀ ń jẹ́ Blaize; Ọjọ́ keje oṣù kìíní, ọdún 1874 sí Ọjọ́ ẹ̀tà lè lógún oṣù kẹwàá ọdún 1953) jẹ́ ẹni àrà ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti onínúure.Ó jẹ́ ọmọbìnrin oníṣòwò R.B Blaize àti ìyàwó oníṣègùn Orisadipe Obasa.

Sàró Obasá kan ni wọ́n bí gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn ọmọ Richard Beale Blaize, ọlọ́rọ̀ àti ọlọ́jà olóṣèlú, àti ìyàwó rẹ̀ Emily Cole Blaize. Ó lo àwọn ọdún ìgbékalẹ̀ rẹ̀ ní ìlú Èkó, níbití bàbá rẹ̀ ti ṣe àtẹ̀jáde àwọn ìwé ìròyìn ti orílẹ-èdè The Lagos Times ati Gold Coast Colony Advertiser àti The Lagos Weekly Times. [1] Ó ka ẹ̀kọ́ dáradára, àkọ́kọ́ ni ilé-ìwé ti àwọn ọmọbìnrin Anglican lónìí ní Ìlú Èkó, lẹ́hìn náà ní ilé-ẹ̀kọ́ kan ní England.

Ní ọdún 1902, ó ṣe ìgbéyàwó sí ọmọ ọba Sàró, Prince Orisadipe Obasa. Bàbá rẹ̀ fún tọkọtaya ní ilé titun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ìgbéyàwó; Nígbẹ̀yìn náà ni wọ́n wá ń pè é ní Ilé Babafunmi. Obasa àti ọkọ rẹ̀ tẹ̀síwájú láti bí ọmọ márùn ùn papọ̀.

Ẹ̀gbọ́n sí Kofo, Lady Ademola, Obasa jẹ́ òǹtajà àti onínúure tí ó ṣe àgbéga ètò àwọn obìnrin àti ẹ̀kọ́. Ní ọdún 1907, Ilé-ìwé àwọn ọmọbìnrin ti Èkó, tí wọ́n wá ń pè ní Wesleyan Girls High School, tí ṣíṣí rẹ̀ wá nípasẹ̀ ìgbìyànjú rẹ̀ ní fífún ohun-ìní kan tí ó yá ilé-ìwé náà. Ní ọdún 1913 ó dá ilé-iṣẹ́ gbígbé ọkọ̀ àyọ̀kẹ́lẹ́ àkọ́kọ́ ní Èkó, èyí tí ó jẹ́ Anfani bus service, ó sì ní àwọn ọkọ̀ ńlá mẹ́ta, tàkìsi mẹ́ta àti ọkọ̀ akérò mẹ́fà tí ń ṣiṣẹ́ ní ọdún 1915. [2]

Obasa tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olókìkí esotericist. Ní ọdún 1914, ó dá àjọ Reformed Ogboni Fraternity sílẹ̀. Wọ́n dá a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Iya Abiye àkọ́kọ́, tàbí ọ̀gá obìnrin, ní ọdún kan náà. [3]

Ó kú ní ọdún 1953. [4]

  • Akintola, Akinbowale (1992). The Reformed Ogboni Fraternity (R.O.F.): The Origins And Interpretation Of Its Doctrines And Symbolism. 
  • George, Abosede (2014). Making modern girls: a history of girlhood, labor, and social development in colonial Lagos. 
  • Muritala, Monsuru (2019). Livelihood In Colonial Lagos. 
  • Schoonmaker, Trevor (2003). Fela: From West Africa to West Broadway. 
  1. "Olajumoke Obasa: The Selfless Social-Worker who established first bus service in Lagos to ease pain of commuters". Neusroom.com. Retrieved October 28, 2020. 
  2. Schoonmaker 2003, p. 13.
  3. Akintola 1992, pp. 9 and 10.
  4. Akintola 1992, pp. 85 and 86.