Jump to content

Chris Olukolade

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chris Olukolade
Agbẹnusọ fún ológun Nàìjíríà
In office
March 19, 2013 – July 30, 2015
AsíwájúBrig Gen. Mohammed Yerima
Arọ́pòCol. Rabe Abubakar
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí18 Oṣù Kẹta 1959 (1959-03-18) (ọmọ ọdún 65)
Idoani, Ìpínlẹ̀ Ondo, Nigeria
Alma materNigerian Defence Academy
Obafemi Awolowo University
Military service
Allegiance Nigeria
Branch/serviceNigerian Army
Years of service1982–2015
RankMajor general
Commands149 Infantry Battalion
Battles/warsBoko Haram Insurgency War, [peace keeping operations in Liberia, Sierra Leone & Sudan

Chris Olukolade (tí a bì ní Ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù kẹta, Ọdún 1959) jẹ́ ọ̀gágun àgbà tí ó jẹ́ agbẹnusọ fún ológun Nàìjíríà tí ó ti fẹ̀yìn tì. Òhun ni wọ́n yàn lẹ́yìn tí ọ̀gágun Brig Gen. Mohammed Yerima pàrí sáà rẹ̀. Wọ́n sí yàn ọ̀gágun Colonel Rabe Abubakar lẹ́yìn tí òhun náà parí sáà rẹ̀ bákan náà. Kí ó tó fẹ̀yìn tì ní ìpari ́ oṣù keje, ọdún 2015, ó jẹ́ alága fún ẹgbẹ́ Forum of Spokespersons on Security and Response Agencies (FOSSRA) in Nigeria.[1]

Wọ́n bí Maj. Gen. Chris Olukolade ní Ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù kẹta, Ọdún 1959 sí ìlú Zaria, Ìpínlẹ̀ Kaduna , ṣùgbọ́n àwọ́n òbí rẹ̀ wa láti ìlúIdoani, ní Ipinle Ondo, Nigeria. Ó kàwé gboyè ní ilé ìwé yunifásitì Obafemi Awolowo University, Ile Ife ní ọdún 1983, ó sì darapọ̀ mọ́ ológún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún 1982. Wọ́n gbàá wọlé bíi ìgbákejì Lietenant látàrí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó wà ní ipele kẹta gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ́ ológun. [2]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]