Cynthia Shalom
Cynthia Shalom | |
---|---|
Cynthia Shalom Ninu aṣọ Áfíríkà rẹ | |
Ọjọ́ìbí | March 18, 1988 Ede, Osun State, Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Port Harcourt |
Iṣẹ́ | Actress, producer, businessperson |
Ìgbà iṣẹ́ | 2015 - present |
Cynthia Shalom (tí a bí ní 18 Oṣù Kẹẹ̀ta, Ọdún 1988) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, agbéréjáde àti olùṣòwò. Ó jẹ́ ajáwé olúborí níbi abala kọkànlá ti ètò, Next Movie Star.[1][2]Láti ìgbà náà ló ti wá kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nollywood. Ó kópa nínu eré alátìgbà-dégbà ti M-net kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́Tinsel.
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Cynthia Shalom ní ìlú Ẹdẹ, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Òun ni àkọ́bí àwọn ọmọ márùn-ún ti òbí rẹ̀. Ó lọ Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama rẹ̀ ní Port Harcourt níbi tí òun àti àwọn òbí rẹ̀ dì jọ n gbé.[3] Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìṣàkóso láti Ilé-ìwé gíga Yunifásítì ìlú Port Harcourt. Ó sì tún gba ìwé ẹ̀rí fún eré ṣíṣe níbi àjọ̀dún Africa International Film Festival (AFRIFF).[4] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú àwọn oníròyìn Vanguard Nigeria, ó sọ di mímọ̀ wípé kíkó lọ òun sí Ìlú Èkó jẹ́ láti lépa iṣẹ́ eré ìtàgé rẹ̀ ní ṣíṣe.[5]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Shalom jẹ́ ajáwé olúborí níbi ètò, Next Movie Star ti ọdún 2015/2016.[6] Ó ṣe àkọ́kọ́ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré nínu ètò tiMonalisa Chinda kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́You&I with Monalisa. Ó wí fún ìwé ìròyìn The Punch pé òun kojú àwọn ìjákulẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí òún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré Nollywood.[7] Ní ọdún 2016, ó kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré An Hour With The Shrink pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Annie Macaulay-Idibia, Gbénró Ajíbádé, àti Segun Arinze.[8] Ó tún dì jọ kópa pẹ̀lú Desmond Elliot nínu eré The Damned tí Irokotv ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀.[9][10] Ní ọdún 2018, Shalom náà dá ilé-iṣẹ́ tó n rísí gbígbé eré jáde sílẹ̀, èyítí ó pe orúkọ rẹ̀ ni Cynthia Shalom Production. Ipa rẹ̀ tó kó nínu ọ̀kan lára àwọn fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Chain,[11] ṣokùn fa yíyàn rẹ̀ fún àwọn àmì ẹ̀yẹ méjì kan níbi ayẹyẹ 2019 Best of Nollywood Awards.[12][13]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn eré àgbéléwò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Next Movie Star (2015/2016)
- Iquo’s Journal (2015).[14]
- An Hour With The Shrink (2016)
- Thorns of love (2016)
- No I Dont (2017)
- The Damned (2017)
- Roberta (2017)
- Karma (2017)
- Ebomisi (Irokotv) (2018).[15]
- Chain (2018)
- Driver (2018)
- Altered Desire (Africa Magic) (2019)
- Beauty in the Broken (Irokotv) (2019)
- The Second Bed (2020).
- Back to the Wild (Irokotv) (2019)
- Love Castle (2019)
- Rachel’s Triumph (2019)
- Shut (2020)
- Fading Blues (Irokotv) (2020)
- Wind of Desire (2020)
- Birth Hurts (2020)
Eré Tẹlifíṣọ́nù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Dear Diary Season 2 (2016).[14]
- Tales of Eve (2017)
- I5ive (2019)
- Jela (2019)
- Tinsel (2017-present)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Sanusi, Sola (2016). "See New Nollywood Star Discovered". Retrieved 2020-08-18.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Cynthia Shalom Shares Her Experience". Encomium. 2016-11-16. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ "I Like Playing Roles That Challenge Me". The Punch. 2020-05-03. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ Nwanne, Chuks (2018-11-24). "AFRIFF Ends on High Note". The Guardian Nigeria News. Retrieved 2020-08-19.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Ajose, Kehinde (2015-02-27). "Im One Of Majid Michels Admirers". Vanguard. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ Bada, Gbenga (2016-12-20). "27 Yr Old Cynthia Shalom Wins". Pulse. Retrieved 2020-08-18.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Samuel, Olajide (2020-01-05). "Nothing Wrong With Marrying Older Lover". The Punch. Retrieved 2020-08-19.
- ↑ "An Hour With The Shrink". Pulse. 2016-03-08. Retrieved 2020-08-18.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "The Damned". Talk African Movies. 2017-07-30. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ Olatunji, Samuel (2016-09-11). "Cynthia Shalom, Next Movie Star". The Punch. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ "Pictures from Nollywood Private Screening of Chain the Movie Produced by Cynthia Shalom". Nigerian women diary. 2018-11-05. Retrieved 2020-08-17.
- ↑ Lenbang, Jerry (2019-09-30). "Nominees for 2019 BOn Awards". The Cable Lifestyle. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ "2019 Bon Awards Nomination". Bella Naija. 2019-09-30. Retrieved 2020-08-18.
- ↑ "Cynthia Shalom Shines in Dear Diary Season 2". The Nigerian Voice. 2016-10-19. Retrieved 2020-08-18.