Dèbórà Adébọ́lá Fáṣọyin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Dèbórà Adébọ́lá Fáṣọyin ni wọ́n bí ní ìlú Ọ̀yọ́ ní ọdún 1944, sí ìdílé Pa Afọlábí. Ó jẹ́ ọ̀kánlàwọ́n ọmọ obìnrin àti àbíkẹ́yìn ọmọ nínú ẹbí náà. [1]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọrin ìjọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dèbórà bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ láti inú ìjọ Micheal Anglican Church gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ, ó dara pọ̀ mọ́ ìjọ C.A.C ní ọdún 1961 lẹ́yìn tí ó ṣègbeyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ìjọ C.A.C, tí ó sì mú iṣẹ́ orin kíkọ lọ́kùnkúndùn.[2] Sisí Olúwaṣọyin (bí ó ti fẹ́ kí wọ́n ma pèé) ni ó jẹ́ adarí ẹgbẹ́ akọrin obìnrin rere nínú ìjọ Christ Apostolic Church, ní ìlú Ìbàdàn ní ọdún 1970, àmọ́ ó di gbajú gbajà akọrin ní ọdún 1980 lẹ́yìn tíó ṣe àwo rẹ̀ tó gbe jáde Ọdún ń lọ sópin. [3]

Ẹbí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dèbórà Fáṣọyin ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọ̀gbẹ́ni Fáṣọyin tí ó jẹ́ ọmọ ìjọ C.A.C.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "C.A.C Good Woman Choir, Ibadan. Led By Mrs D.A Fasoyin". Boomplay music (in Èdè Latini). 2018-10-13. Retrieved 2019-12-31. 
  2. "I nearly fainted when I was chosen to lead Good Women Choir". Fasoyin – Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-12-31. 
  3. Tayo, Ayomide O. (2017-12-10). "The story of the CAC Good Women Choir and the evergreen song". Pulse Nigeria. Retrieved 2019-12-31. 
  4. "I Was Destined To Sing". P.M. News. 2012-12-07. Retrieved 2019-12-31. 

Ó bí ọmọ mẹ́rin, ó sì ní ọmọmọ pẹ̀lú.