Délé Òdúlé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Délé Òdúlé (ọjọkẹtàdínlógún, oṣù kọkànlá ọdún 1961) jẹ́ àgbà òṣèré tíátà àti olótùú-àgbà.[1] Ní ọdún 2014, wọ́n yaǹ-án láti gba àmìn-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré Yorùbá ni (Best of Nollywood Awards) fún ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò "Kori Koto".[2] Òun ààrẹ àwọn òṣèré tíátà àti sinimí àgbéléwò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[3]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Délé Òdúlé ní ìlú Òrù-Ìjèbù, Ní Ìjọba Ìbílè Ijebu North ti ìpínlẹ Ogun ní ọdún 1961[4].  Ibè ni ó ti ka ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti gíga.[5] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Olùkọ̀ onípele kejì (Teachers' Grade II Certificate) ní Oru kí ó tó tẹ̀síwájụ́ ẹ̀kọ́ ní University of Ibadan, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níbi tí ó ti ń kọ́ nípa ìmọ̀ tíátà (Theatre Arts.)[6]

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]