Jump to content

Dele Bakare

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Dele Bakare
Ọjọ́ìbíOladele Ibukun Bakare
8 Oṣù Kejì 1989 (1989-02-08) (ọmọ ọdún 35)
Orílẹ̀-èdèNigerian,
Iléẹ̀kọ́ gígaAnglia Ruskin University,
Iṣẹ́
  • software developer
  • entrepreneur
Websitefindworka.com

Dele Bakare (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Oladele Ibukun Bakare ni ẃn bí ní 8 February 1989) jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti oníṣòwò tó wá láti ìlú Ìbàdàn, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó ṣe ìdásílẹ̀ Findworka, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń gba àwọn oníṣẹ́-ẹ̀rọ láti pèsè àwọn ohun tó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀rọ. Ó fìgbà kan jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àgbà ní Infinion Technologies and technology, ní BudgIT.[1] Ní ọdún 2016, wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ Future Awards Africa ti ìmọ̀ sáyẹ̀ǹsì àti ìmọ̀-ẹ̀rọ.[2]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí ó tó gba diploma nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ ní NIIT,[3] Dele ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀-ẹ̀rọ ní Infinion technologies. Ó kúrò ní Infinion technologies láti lo ṣèdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ní Nàìjíríà[4] pẹ̀lú Temitayo Olufuwa. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Swiss Africa Business Innovation & Initiative and Founders Gym, èyí tó jẹ́ ẹ̀kọ́ orí-ayélujára tó máa ń kọ́ àwọn olùdásílẹ̀ lóríṣịríṣi láti rí owó fún ilé-iṣẹ́ wọn.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]