Denrele Edun
Denrele Edun O | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Adenrele Oluwafemi Edun 13 Oṣù Kẹfà 1981 Hamburg, Germany |
Ẹ̀kọ́ | Yunifásítì ìlú Èkó |
Iṣẹ́ | Television personality |
Ìgbà iṣẹ́ | 1995–present |
Adenrele Oluwafẹmi Ẹdun tí gbogbo ènìyàn mọ sí Denrele (tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà ọdún 1981), jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ma ń gbà àlejò lórí tẹlifísànù. Denrele ni wọ́n ti mọ̀ pẹlú orísirísi àwọn àmì ẹ̀yẹ tí ó ma ń gbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì ẹ̀yẹ ni olùgbàlejò orí tẹlifísànù yí ti gbà, lára wọn ni àmì ẹ̀yẹ fún ènìyàn pàtàkì tí ó dára jùlọ lórí tẹlifísànù níbí ayẹyẹ tí NEAs ní ìlú New York, ọdún 2011, Àmì ẹ̀yẹ ti Dynamix fún òṣìṣẹ́ ọ̀dọ́ orí tẹlifísànù tí ó dára jùlọ fún ti àwọn ọdún 2006/2007/2008, àti àmì ẹ̀yẹ ọjọ́ iwájú fún olùṣètò orí tẹlifísànù tí ó dára jùlọ ní ọdún 2007.
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Denrele ni a bí ní Hamburg, ní orílẹ̀-èdè Jẹmánì. Ọmọ ilẹ̀ Yoruba ni bàbá rẹ nígbàtí ìyá rẹ wá láti orílẹ̀-èdè Indian ní Mauritian. Nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ, òun nìkan ni okùnrin tí àwọn méjì sì jẹ́ obìnrin. Orílè-èdè Jẹmánì ni Denrele dàgbà sí. Nígbàtí ó pé ọmọ ọdún márún ùn, ó wà sí orílè-èdè Nàìjíríà níbití ó ti lọ sí ilé-èkó St Gregory tí ó wá ní Ikoyi àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó.
Ó jẹ́ asíwájú ijó àti akọrin fún "Ẹgbẹ́ Ìrókò Band", ẹgbẹ́ tí olùṣe-fiimu, Dókítà Ọla Balogun ń darí. Léhìn èyí ni ó wá di Backup dancer fún LexyDoo, Ruggedman, Jazzman Olofin, 2Shotz Lady Di àti " Stage Shakers".
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Denrele ni wọ́n mọ̀ nípa ìmúra rẹ àti irú ènìyàn tí ó jẹ́.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ tẹlifísíọ̀nù gẹ́gẹ́ bíi òṣèré ní ọmọ ọdún mọ́kànlá nígbàtí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bii olùfihàn/olùpilẹ̀ṣẹ̀ lórí Kiddievision 101 lórí òpó ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣìonù NTA. Gẹ́gẹ́ bíi akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi aláwòṣe. Léhìn tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba oyè, ó darapọ̀ mọ́ ilé iṣé Sound City gẹ́gẹ́ bíi olùgbétòkalẹ̀ lórí tẹlifísíọ̀nù. Denrele kọ́ ẹ̀kọ́ bí a ti ńkọ́ni ní èdè gẹ̀ẹ́sì ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Èkó.[2]
Denrele jẹ́ ẹni tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ gẹ́gẹ́ bíi adánilárayá tí wọ́n ti ṣe àpèjúwe bí ó ṣe máa ń dá àrà tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi "pọnki ati ìgbádùn". Nínúu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó ṣe pẹlú ModernGhana, ó sọ wípé òun kan ń ṣàlàyé ara òun ni. Ó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn béèrè ìbéèrè yẹn ní ọwọ́ òun, òún á sí sọ pé òun kàn fẹ́ láti jẹ́ ara òun. Ó ní ọ̀pọ̀ ènìyàn rò wípé òun má ń múra nítorípé kí àwọn ènìyàn lè rí òun, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí máa ń ṣe àkíyèsí òun láti ìgbà tí òun ti wá ní èwe.
Denrele ti gba àwọn àmì ẹ̀yẹ mẹ́rìndínlógún àti àwọn ìforúkọ rẹ̀ sílẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ tí ó ju ọgbọ̀n lọ nínú iṣẹ́ rẹ tí ó yàn láàyò. Ó tí ṣe iṣẹ́ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú SoundCity kí ó to dí wípé wọ́n fi ipá leè jáde kí ó tó wá gbéra láti di ọ̀kan lára Channel O's V Js.
Denrele ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn bíi Akon, [3] [4] Beyoncé Knowles, Tyler Perry, Lil 'Kim, Snoop Dogg, Cuba Gooding, Amerie, ati Lloyd. Denrele Ẹdun gba àlejò alága fiimu ti Hoodrush. Denrele ní wọ́n ti gbé oríyìn fún nípa pé òun ni ó wà lẹ́hìn àṣeyọrí Karen Igho, ẹni tí ó borí nínú ìdíje ti Big Brother.[5]
Denrele Ẹdun àti àwọn gbajúmọ̀ òṣèré mìíràn ni wọ́n ṣe àfihàn wọn nínú fiimu ti Nollywood tí àkọlé rẹ ń jẹ́ Make a Move. Àwọn òṣèré bíi Omawumi, 2face Idibia ni wọ́n fi ara hàn nínú fiimu yìí. Niyi Akinmọlayan ni ọ darí rẹ tí ó sì ṣe àfihàn rẹ ní ọjọ́ kẹfà osù kẹfà ọdún 2014.[6] .
Ìgbésí ayé rẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2013, Denrele lọ sí ojú òpó ayélujára tí Twitter rẹ láti kéde pé àwọn adigunjalè ja òun lólè tí wọ́n sì kó ohun gbogbo lọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí mú kí ìyá àgbà rẹ àti bàbá rẹ wà nínú àìbalẹ̀ ọkàn.
Àwọn àmì ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Event | Prize | Result |
---|---|---|---|
2006 | Dynamix Award[7] | Best Youth TV Personality | Gbàá |
2007 | Gbàá | ||
2007 | The Future Award | Best Producer | Gbàá |
2008 | Dynamix Award[7] | Best Youth TV Personality | Gbàá |
2008 | City People Awards[8] | Most Popular TV presenter in Nigeria | Gbàá |
2011 | Nigeria Entertainment Awards | Best TV Personality | Gbàá |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Denrele Edun is a year older today". Pulse Nigeria. 2017-06-13. Retrieved 2021-09-23.
- ↑ Adeyemo, Adeola (2013-01-05). "BN Saturday Celebrity Interview: Inside the “Vivacious” Mind of Channel O TV Presenter Denrele Edun – His Style, His Persona, His Family & More". BellaNaija. Retrieved 2021-09-23.
- ↑ "HAPPY BIRTHDAY TO DENRELE EDUN OF CHANNEL O". 12 June 2012. http://www.gbedunation.com/profiles/blogs/happy-birthday-to-denrele-edun-of-channel-o?xg_source=activity.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "AKON EXCLUSIVE INTERVIEW WITH DENRELE ON CHANNEL O". 22 February 2012. Archived from the original on 12 January 2013. https://web.archive.org/web/20130112002033/http://palmwinevillage.com/videos/akon-exclusive-interview-with-denrele-on-channel-o/.
- ↑ Akinboade, Bola (2013-01-15). "HOW DENRELE EDUN MADE KAREN IGHO RICH AND FAMOUS - nigeriafilms.com". web.archive.org. Archived from the original on 2013-01-15. Retrieved 2021-09-23. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Oyibu, Elijah (2014-03-11). "Denrele Edun, Tuface Idibia, And Omawunmi To Star In A Movie". Pulse Nigeria. Retrieved 2021-09-23.
- ↑ 7.0 7.1 "Denrele and Sause Kid at the 2008 Dynamix Awards – Nigerian Entertainment Today – Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games". Nigerian Entertainment Today – Nigeria's Top Website for News, Gossip, Comedy, Videos, Blogs, Events, Weddings, Nollywood, Celebs, Scoop and Games. http://admin.thenet.ng/2010/12/the-list-of-nominees-for-dynamix-youth-awards-2010/denrele-and-sause-kid-at-the-2008-dynamix-awards-2/.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "People say I'm gay, so what -Denrele". news1.onlinenigeria.com. Archived from the original on 11 February 2017. Retrieved 10 February 2017.
- All articles with dead external links
- Articles with dead external links from July 2019
- Articles with invalid date parameter in template
- Articles with permanently dead external links
- Pages containing cite templates with deprecated parameters
- Pages with citations using unsupported parameters
- Articles with dead external links from September 2023
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1983
- Àwọn ènìyàn alààyè
- Àwọn olùkọ̀wé ará Nàìjíríà