Jump to content

Domitila (1996)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Domitilla jẹ́ fíìmù ọdún 1996 ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó ní àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bí i Anne Njemanze, Sandra Achums, Ada Ameh, àti Kate Henshaw. Fíìmù náà dá lórí arábìrin kan tó ń tiraka láti rí jíjẹ-mímu nípa ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ní Èkó.[1][2][3] Apá kejì fíìmù náà, ìyẹn Domitilla 2, jáde ní ọdún 1999, àtúnṣe rẹ̀ sì máa jáde ní ọdún 2023.

Ngozi, tó jẹ́ akọ̀wé ọ́fíìsì kan máa ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ní alẹ́ pẹ̀lú orúkọ ìnágijẹ "Domitilla" ( Anne Njemanze ), pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìyẹn Judith (Kate Henshaw), Anita (Ada Ameh), àti Jenny (Sandra Achums). Àwon owó tó ń rí ò lè gbọ́ àwọn ìnáwó rẹ̀ àti owó ìwòsàn bàbá rẹ̀ (Emmanuel France). Lẹ́yìn ìwọléwọ̀de rẹ̀ pẹ̀lú John (Charles Okafor), ìyẹn fi òpin sí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn ní kété tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe. Domitilla lọ sí àpéjọ ayẹyẹ kan pẹ̀lú àwọn ọlrẹ́ rè, níbi tí ó ti pàdé olóṣèlú ọlọ́rọ̀ kan tí orúkọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Lawson (Enebeli Elebuwa).

Àmọ́ ayé da iyẹ̀pẹ̀ sí gàrí rẹ̀ nígbà tí olóṣellú yìí kú sí hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n jọ sùn sí. Gbogbo ẹ̀rí nawọ́ sí Domitilla...

  1. Augoye, Jayne (27 June 2020). "Sequel of 1996 Nollywood classic, Domitilla, 'in the works'". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 July 2022. 
  2. "Zeb Ejiro… ‘Movie Sheik’ returns with Nollywood classic, Domitila". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 25 July 2020. Archived from the original on 20 July 2022. Retrieved 20 July 2022. 
  3. "A Sequel Of The Nollywood Classic Film Domitilla To Be Released In 2021". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 26 June 2020. Archived from the original on 20 July 2022. Retrieved 20 July 2022. 
  4. "I’m no longer afraid of death –Ada Ameh". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 September 2020. Retrieved 20 July 2022. 
  5. "Nigeria's Fading Movie Stars - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 July 2022.