Elbs reaction
Elbs reaction jẹ́ ìṣètò ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ organic tí ó ṣàpèjúwe pyrolysis ti ortho methyl tí wọ́n fi rọ́pò benzophenone lati yọ omi kúrò nínú polyaromatic. Wọ́n sọ orúkọ dàpapọ̀ ṣiṣẹ́ yìí lórúkọ ẹni tí ó ṣàwárí rẹ̀, onímọ̀ chemistry ọmọ jamaní, Karl Elbs tí ó tún ṣètò Elbs oxidation. Wọ́n tẹ ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ jáde ní ọdún in [1][2][3]
Elbs pàápàá jùlọ kò túmọ̀ àbájáde ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ dárádára nítorí àìní ìmọ̀ tó péye nípa ìrísí naphthalene.
Ìmọ̀ nípa rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ Elbs n jẹ́ kí a lè ṣètò aromatic tí kò lómi. Gẹ́gẹ́ bí Elbs ti ṣàfihàn rẹ̀ ní ọdún 1884 wípé óṣeéṣe lati rí anthracene nínú dehydration. ìṣètò aromatic nlá bíi pentacene tún ṣeéṣe. Ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ yìí kìí ṣẹlẹ̀ ní ìgbésẹ̀ kan ṣùgbọn ó maa ń kọ́kọ́ jásí dihydropentacene tí wọ́n maa ń yọ hydrogen kúrò nínú rẹ̀ ní ìgbésẹ̀ kejì pẹ̀lú copper gẹ́gẹ́ bí amúlọsíwájú bá ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́.[4]
A lè rí àwọn ìdàpọ̀ kẹ́míkà acyl tí a nílò ní ì dàpapọ̀ ṣiṣẹ́ yìí látàrí Friedel-Crafts acylation pẹ̀lú aluminum chloride.[2][4]
Àwọn ìyàtọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó tún ṣeéṣe kí a ṣètò àwọn ìdàpọ̀ kẹ́míkà heterocyclic lati ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ Elbs. Ní ọdún 1956 ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ Elbs ti thiophene tí ó jẹyọ di àtẹ̀jáde. A kò rí èsì àbájáde tí à ń reti nítorí ìyípadà nínú ètò ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ìṣètò ti agbedeméjì àkọ́kọ́ tí ó fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbésẹ̀ Ìdàpapọ̀ ṣiṣẹ́ àwọn radical tí kò lólúwa.[5]