Elfrida O. Adebo
Elfrida O. Adebo, tí orúkọ àbíso rẹ̀ jẹ́ Olaniyan (tí wọ́n sì bí ní ọdún 1928) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti Núrsì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní ọdún 1984, ó di ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Núrsì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Adebo ní ìlú Abeokuta, Ìpínlẹ̀ Ògùn,[2] ní ọjọ́ kẹta osù kẹta ọdun 1928.[3] Ó bèrè ipa rẹ̀ nínú iṣẹ́ Núrsì ní London,[1] ibè ló tí kó nípa ìṣẹ́ Núrsì àti gbígbẹ̀bí ní St Mary's Hospital, London láàrin ọdún 1957 sí 1958.[3] Ní ọdún 1959, ó padà sí Nàìjíríà láti di Núrsì ní Ibadan.[1] O gba àmì ẹyẹ D.P.H. nínú ìmò isẹ Núrsì ní ọdun 1961, àti àmì ẹyẹ Bachelor of Nursing ní ọdún 1962.[2] Lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣiṣẹ́ díè gẹ́gẹ́ bi olùbádá ìmọ̀ràn ní School of Hygiene ti ìlú Ibadan, ó di olùkọ́ ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn.[1] Ó dára pọ̀ mọ́ ẹ̀ka isẹ Núrsì ní oṣù Kẹ̀wá ọdún 1967, ó sì di adarí ẹ̀ka náà ní ọdún 1970.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 Michael Orodare, Dr Doyin Abiola, Prof. Elfrida Adebo, Major General Aderonke Kale – Extraordinary Nigerian women who made history in male-dominated fields, Neusroom, 14 May 2020. Accessed 17 January 2021.
- ↑ 2.0 2.1 Adetunji Akinyotu (1989). Who's who in Science and Technology in Nigeria. Federal University of Technology. p. 10. ISBN 978-978-2475-00-8. https://books.google.com/books?id=ojEJAQAAIAAJ.
- ↑ 3.0 3.1 Joseph A. Balogun (2020). Healthcare Education in Nigeria: Evolutions and Emerging Paradigms. Taylor & Francis. p. 2. ISBN 978-1-00-031961-3. https://books.google.com/books?id=WjINEAAAQBAJ&pg=RA2-PA6.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedTijani2003