Enoch Adébóyè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Enoch Adejare Adeboye
Enoch Adeboye
Ọjọ́ìbí2 Oṣù Kẹta 1942 (1942-03-02) (ọmọ ọdún 78)
Ifewara, Osun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Pastor, profesor
EmployerRedeemed Christian Church of God, University of Lagos
Olólùfẹ́
Foluke Adenike Adeboye (m. 1967)
WebsiteÀdàkọ:Official URL

Pastor Enoch Adéjàré Adébóyè (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹta ọdún 1942) jẹ́ òjíṣẹ̀ Ọlọ́run ọmọ bíbí Ifẹ̀wàrà ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Pásítọ̀-àgbà yànyàn ati Olùdarí ìjọ oníràpadà, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí The Redeemed Christians Church of God.[1][2]

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run àgbà yìí, Enoch Adéjàré Adébóyè ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹta ọdún 1942 ni Ifẹ̀wàrà ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìlú Ifẹ̀wàrà wà ní ìtòsí Ilé-Ifè. Ó kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ ìṣirò (Mathematics) ni ifáfitì ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, the University of Lagos lọ́dún 1967. Ṣíwájú àkókò yìí, ó ti kọ́kọ́ lọ sí the University of NIgeria (UNN) ní ìlú Nsukka ṣùgbọ́n Ogun Biafra kò jẹ́ kó kàwé gboyè níbẹ̀. Ó fẹ́ aya rẹ̀, Folúkẹ̀ Adéníkẹ̀ẹ́ lọ́dún 1967 bákan náà, wọ́n sìn bímọ mẹ́rin.[3] Lọ́dún 1969, ó kàwé gboyè dìgírì kejì (Master Degree) nínú ìmọ̀ hydrodynamics láti University of Lagos. Ó dára pọ̀ mọ́ ìjọ Oníràpadà, the Redeemed Christian Church of God lọ́dún 1973, ó sìn bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Oǹgbufọ̀ fún Pásítọ̀ ìjọ náà nígbà náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pásítọ̀ Josiah Olúfẹ́mi Akíndayọ̀mi. Lọ́dún 1975, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́, ó sìn kàwé gboyè Ọ̀mọ̀wé (Ph.D.) nínú Applied Mathematics láti the University of Lagos. Ó gboyè ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú ìmọ̀ ìṣrọ̀ ni University of Lagos bákan náà.[4] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. About the author (2019-12-15). "Pastor Enock Adeboye: Trademark of humility – Zambia Daily Mail". Zambia Daily Mail – Without fear or Favour. Retrieved 2019-12-15. 
  2. vanguard (2018-03-02). "76 Garlands for Adeboye". Vanguard News. Retrieved 2019-12-15. 
  3. Ikeke, Nkem (2015-02-21). "Pastor Adeboye Reveals 4 Equations Of Marriage (NO. 3 Will Make You Laugh)". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-12-15. 
  4. Published (2015-12-15). "Adeboye's story: From lecture hall to global pulpit". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-15. 
  5. "Obafemi Awolowo University, Ile-Ife » Endowment of Professorial Chair in Mathematics: Pastor Adeboye gives fifty (50) Million Naira to OAU". oauife.edu.ng. 2014-06-05. Archived from the original on 2014-06-05. Retrieved 2019-12-15.