Erékùṣù Mozambique

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Infobox UNESCO World Heritage Site Erékùṣù Mozambique (Pọrtugí: Ilha de Moçambique) ni o wà ní ẹ̀yìn àríwá ilẹ̀ Mozambique, láàrín Mozambique Channel àti ẹsẹ̀ odò Mossuril, ó sì wà ní ara Nampula Province. Ṣáájú ọdún 1898, òun ni olú-ìlú fún Portuguese East Africa ní àsìkò ìmúnisìn. Erékùṣù Mozambique ni ó wà lára àwọn UNESCO World Heritage site látàrí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ati afara ti o joju ti o wa nibe, o si wa lara awon ilu ti o n dagba soke ti o si n fa ogoro awon eniyan olubewo wa si ibe. Ilu yi ni awon olugbe ti won to egberun merinla, papko ofurufu ti o wa nibe ni o wa ni Nmpula. Oruko ti ilu yi Mozambique n je ni won fa yo lati ara bi ile ilu won se ri.


Itan[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn amọ̀ tí wọ́n rí ní orí ilẹ̀ Mozambique ni ó fi hàn wípé wọ́n ti dá ìlú yí sílẹ̀ ní nkan bí ọ̀rùndún kẹrìnlélógún sẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bi ìtàn ṣe sọ, àwọn ará ilẹ̀ Swahili ni wọ́n wá láti Kilwa. Àwon adarí ti wọ́n dàbí Ọba ni wọ́n ní nkan ṣe pẹ̀lú Angoche àti Quelimane ní nkan bi ọ̀rùndún kẹẹ̀dógún. Ni ọdún 1514, Duarte Barbosa kọ ọ́ sílẹ̀ wípé àwọn ẹlẹ́sìn Musulumí ni wọ́n pọ̀ jùlọ ti wọ́n sì n sọ èdè Swahili gẹ́gẹ́ bí ti awọn Angoche.[1]

Orúkọ ìlú yí ni o ń jẹ́ (Pọrtugí: Moçambique, tí wọ́n ń pe báyí [musɐ̃ˈbiki]) ni wọ́n ṣe àfàyọ rẹ̀ láti ara Ali Musa Mbiki (Mussa Bin Bique), tí ó jẹ́ sultan (Oba) fún erékùṣù náà ní àsìkò Vasco da Gama. Orúkọ yí ni wọ́n gbé lárugẹ tí ó sì di orúkọ orílẹ̀-èdè Mozambiquelóní, wọ́n sì ṣe àtúntò orúkọ náà sí Ilha de Moçambique (Island of Mozambique). Àwọn Potogí kọ́ agọ́ àwọn ọmọ ogun orí omi síbẹ̀ ní ọdún 1507, wọ́n sì tún kọ́ Chapel of Nossa Senhora de Baluarte ní ọdún 1522, èyí tí ó di ilé tí ó dàgbà jùlọ nínú ilé tí àwọn ará Yúróòpù ti kọ́ sí Southern Hemisphere. Ní nkan bí ọ̀rùndún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn, wọ́n kọ́ Fort São Sebastião tí ó jẹ́ ìletò tí a mọ̀ sí (Stone Town) èyí tí ó di olú-ìlú fún ìletò àwọn Portuguese East Africa. Erékùṣù yí tún di ojúkò pàtàkì fún àwọn ajíyìnrere nígbà náà. Erékùṣù yí fojú winá àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Dutch ní ọdún 1607 àti 1608, ó sì tún jẹ́ ibi tí àwọn Potogí ti m ń sinmi nígbà tí wọ́n ba ń re kọjá lọ si apá ilẹ̀ India. Erékùṣù yí kan náà tún jẹ́ ibi tí wọ́n ti ma ń ṣe òwò oríṣiríṣi bii: òwò ẹrú òwò ohun jíjẹ ati [[góòlù]. Yàtọ̀ sí ààbò tí wọ́n ṣe sí ìlú náà láyé àtijọ́, pupọ̀ lára àwọn agbègbè inú ìlú náà ni ó kún fún àpáta ati àwọn òkúta rìbìtìrìbìtì tí eọ́n sì fi wọ́n kọ́lé. ilé-ìwòsàn tí wọ́n kọ́ pẹ̀lú ọ̀ṣọ́ neo-classical ni eọ́n kọ́ ní ọdún 1877 láyi ọwọ́ àwọn Potogí, wọ́n fi odò ẹja ṣeé lọ́jọ̀ àti odi oríṣiríṣi. Wọ́n tún ilé-ìwòsàn yí kùn lẹ́yìn ogun Mozambican Civil War. Ilé-ìwòsàn yí ni ó jẹ́ èyí tí ó tóbi jùlọ ní gbogbo apá Ìlà-Oòrùn Sàhárà fún ọdún pípẹ́.[2] Lẹ́yìn tí wón ṣí Suez Canal tán,i iyì ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí parẹ́ diẹ̀ diẹ̀. Wọ́n gbe gbe olú-ìlú rẹ̀ lọ sí Lourenço Marques tí ó di (Maputo) báyí ní ọdún 1898. Nígbà tí yóò fi di ọ̀rùndún ogún, Nacala ni ó gbapò lọ́wọ́ erékùṣù náà tán pátá.

Àwọn ohun tí ó fani mọ́ra níbẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lára àwọn ilé ìṣẹ̀mbáyé tí ó jọjú tí ó wà níbẹ̀ ni ààfin Oba ati Chapel of São Paulo, tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1640, Jesuit College tí wọ́n padà yí sí ilé ìgbé Gómìnà, tí òun náà ti di ilé ìṣẹ̀mbáyé báyí; ilé ìṣẹ̀mbáyé Ọnà tí ó wà ní ilé-ìjọsìn Misericórdia tí àwọn House of Mercy, ni ó ń ṣàfihn Makonde tí ó ke yọ yọ. Bákan náà ni crucifix; ati ilé-ìjọsì Santo António;ilé-ìjọsìn Misericórdia; ati Chapel of Nossa Senhora de Baluarte. Erékùṣù náà ti wá di ìlú ńlá báyí, tí ọpọ̀lọpọ̀ mọ́sálásí, ilé-ìjọsìn Hindu temple ti lalẹ̀ hù níbẹ̀. Wọ́n kọ́ afárá afárá oní kìlómítà 3 km kan sí àárín ìlú náà ní ọdún 1960. Ìlú yí gẹ́gẹ́ bí erékùṣù kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, pupọ̀ àwọn olùgbé ìlú náà ni wọ́n ń gbé ní ọwọ́ àríwá nínú ilé rere ní Mukuti Town.

Àwọn àwòrán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Erékùṣù yí tún súnmọ́ àwọn ìletò bii: Chocas Mar, tí ó jẹ́ etí òkun tí ó gùn gidi ní ìwọ̀n 40 km ní apá aríwá sí bèbè odò Ilha de Moçambique across the Mossuril àti Cabaceiras.

Ẹ tún lè wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Newitt, Malyn. "Mozambique Island: The Rise and Decline of an East African Coastal City" 2004. Page 23
  2. Patrick Lagès, The island of Mozambique, UNESCO Courier, May, 1997.