Jump to content

Esther Audu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Esther Audu
Esther in Apartment 24
Ọjọ́ìbíEsther James Audu
March 22, 1986 (1986-03-22) (ọmọ ọdún 38)
Ikeja, Lagos State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Jos BA in Business Management
Iṣẹ́Actress

Esther Ene Audu tí wọ́n bí ní ọjó Kejìlélógún oṣù Keta ọdún 1986 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ati sinimá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] She is popularly known for starring in the films Dinner (2016), Mystified (2017) and Order of the Ring (2013).

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé ati ẹ̀tò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Esther ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Kẹ́ta ọdún 2986, sí inú ẹbí òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì nílé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà kan ọ̀gbẹ́ni James Audu . Bàbá rẹ̀ lo gbogbo ayé rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ekó ní inú bárékè ológun tí ó wà ní ìlú Ìkẹjà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Ọmo bíbí ìlú Olamaboro ní Ìpínlẹ̀ Kogi ni wọ́n. Esther ni ó jẹ́ àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ márùn ún tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ Èkó àmọ́ òun ati àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí ìlú Àbújá ní ọdún 2002, tí ó sì lọ parí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ girama, ó wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì Jos ní Ìpínlẹ̀ Plateau láti kẹ́kọ́ gbawé érí ní inú ìmọ̀ Business Management ní ọdún 2006 tí ó aì jáde ní ọdún 2010.[2]

Esther bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré orí-ìtàgé síṣe láti ìgbà tí ó ti wà ní ilé-ékọ́ girama tí ó sì ma ń ṣojú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ níbi eré oníṣẹ́ ìtà gbangba. Ní ọdún 1996, ó wà lára àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ tí wọ́n yàn láti.ṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nínú ìdíje Kidafest ní orílẹ̀-èdè Gánà. Látàrí èyí, ó di ẹni tí ó nífẹ́ sí láti máa ṣeré dá àwọn ènìyàn lára yá. Ó kọ́kọ́ kópa nínú eré Ungodly romance and Sins of Racheal in Jos, eré tí Alex Mouth kọ. Esther fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé eré yí ni ó jẹ́ kí òun láńfàní láti di òṣèré Nollywood lóní. Ó tún kópa nínú àwọn eré bíi: Fatal Mistake .[2]

Ó ṣe ìg ìyàwó pẹ̀lú ògbẹ́ni Philip Ojire tí ó jẹ́ oníṣòwò. [3][4]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Eré Ipa tí ó kó Notes
Ungodly Romance
Sins of Rachael
Fatal Mistake
2009 Behind a Smile
2010 Best Interest
2010 Best Interest
2012 Two Hearts
Royal Grace
Judas Game
Bachelors Hearts
2013 Return of The Ring
2016 Dinner
2017 Mistified

Awards and nominations

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìtàkùn ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control