Faithia Balogun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Faithia Williams
ÌbíFebruary 5, 1969 (1969-02-05) (ọmọ ọdún 51)
Ikeja, Lagos State, Nigeria
Iṣẹ́
 • Actor
 • filmmaker
 • producer
 • director
Awọn ọdún àgbéṣe1978–present

Faithia Williams (tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1969) jẹ́ òṣèré, olóòtú ati olùdarí fíìmù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí i ní ìlú Ikeja ní oṣù kejì ọdún 1969. Ó wá láti ìlú Okpara ní ìpínlẹ̀ Delta. Ó kàwé ni ilé-ìwé alákòóbẹ̀rẹ̀ Maryland àti Maryland Comprehensive Secondary School ní ipinlẹ Eko, níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí ti West African School Certificate kí ó tó wá tẹ̀ síwájú ní Kwara State Polytechnic níbi tí ó ti gba ìwé-ẹ̀rí diploma. Ó ti fìgbà kan fẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò mìíràn tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Saheed Balógun, ṣùgbọ́n ìgbéyàwó wọn ti foríṣánpọ́n. [1]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ti kópa nínú, jẹ́ olóòtú àti adarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù ti ilẹ̀ Nàìjíríà fún àìmọye ọdún. Ní ọdún 2008, ó gba àmì ẹ̀yẹ tí Africa Movie Academy fún òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ àti pé fíìmù rẹ̀ "ìránṣẹ́ ajé gba ẹ̀bùn fíìmù tí ó dára jù lọ ní ọdún náà . Ní oṣù kẹrin ọdún 2014, ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Africa Movie Academy lẹ́yìn tí ó yanranntí gẹ́gẹ́ bíi òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ pẹ̀lú Ọdúnladé Adékọ́lá tí ó gba àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi òṣèrékùnrin tí ó dára jù lọ ní ọdún náà. Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ fún fíìmù kan tí ó ṣe tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ìyá alálàkẹ́ ní ọdún 2015 lórí Africa-Magic Viewers' Choice AMVCA

Ìgbésí ayé ara ẹni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìyàwó gbajú-gbajà òṣèré tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́, Saheed Balogun .

Àwọn fíìmù tí ó ti gbé jáde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Farayola (2009)
 • Aje metta (2008)
 • Aje metta 2 (2008)
 • Awawu (2015)
 • Teni Teka (2015) [2]
 • Omo Ale (2015)
 • Agbelebu Mi (2016)
 • Basira Badia (2016)
 • Adakeja (2016)
 • Eku Eda (2016)
 • OBIRIN MI (2018)

Awọn itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]