Freedom Park (South Africa)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Freedom Park wà lórí Salvokop ní Pretoria. Wọ́n sì kọ orúkọ àwọn tí ó sọ èmí wọn nù nínú àwọn Ogun South African, Ogun Àgbáyé Kìíní, Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì àti ní ìgbà apartheid.[1]

Isivivani - Freedom Park. Pretoria, South Africa
Memorial - Freedom Park
Amphitheatre - Freedom Park
Eternal Flame - Freedom Park

Kíkọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣiríṣi àwọn alágbàṣe ni wọ́n gbà láti kọ́ ilé náà ní ìsòrí, àwọn bi Stefanutti Stocks, WBHO, Trencon, Concor àti àwọn mìíràn.[2]

Mongane Wally Serote ni ó dárí kíkọ́ rẹ̀ pátápátá.[3]

Fífi orúkọ síbẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní Oṣù Kẹta ọdún 2009, wọ́n mú àbá wá láti fi orúkọ àwọn ènìyàn mẹ́rìnlélógún tí ó sọ èmí wọn nù nínú ìjà fún òmìnira sí pákì náà. Díè nínú wọn ni Steve Biko, Oliver Tambo, Helen Joseph, Albert Lutuli, àti Bram Fischer.

Wọ́n tún ka orúkọ àwọn adarí orílẹ̀ èdè míràn tí ó sa ipá wọn nínu òmìnira South Africa tàbí fún òmìnira fún àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú ìnira. Àwọn adarí yìí ni Samora Machel àti Amílcar Cabral. Àwọn orúkọ tí ó tún wà níbẹ̀ ni Che Guevara, àti Toussaint Louverture, tí ó jà nínú ìjà òmìnira Haiti.[4]

Àwọn Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Freedom Park.co.za". 
  2. "Stefanutti’s work on Freedom Park nears completion". Engineering News. 13 August 2009. Retrieved 4 August 2011. 
  3. "Mongane Wally Serote (1944– )". The Presidency of South Africa. Archived from the original on 3 October 2018. Retrieved 4 August 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Trust Honours Struggle Heroes[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́] March 18, 2009