Gbenga Omotoso
Gbenga Omotoso | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | November 11, 1961 |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Journalist, writer, columnist and commissioner for information and strategy |
Organization | Lagos State Ministry of Information and Strategy |
Gbenga Omotoso (tí wọ́n bí ní ọjọ́ 11 oṣù November, ọdún 1961) jẹ́ akọ̀ròyìn àti òǹkọ̀wé. Òun ni olóòtú ìwé-ilròyìn The Nation títí tí wọ́n fi yàn án sípò Commissioner tó ní ṣe pèlú Lagos State Ministry of Information and Strategy. Gómínà Ìpínlẹ̀ Èkó, ìyẹn Babajide Sanwo-Olu mu ṣèbúra láti wọ iṣẹ́ ní ọdún 2019.[1][2][3][4]
Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá ọdún 1961 ni wọ́n bí Omotoso. Ó wá láti Ipinle Osun, tó wà ní apá Gúúsù mọ́ Ìwọ-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínú ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Lítíréṣọ̀ ní University of Benin (Nigeria) ní ọdún 1984. Ó tẹ̀síwájú láti gboyè Masters nínú ẹ̀kọ́ Public and International Affairs ní University of Lagos, Akoka, tí ó parí ní ọdún 2007.[5][6]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Omotoso ti lo ọdún márùndínlógójì nínù iṣẹ́ ìròyìn. Ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gé bíi akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kọ́ nípa iṣẹ́ olóòtú ní ilẹ́-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn The Guardian. Ó padà di igbákejì olóòtú ti Guardian Express, níbi tí ó ti di olóòtú Saturday Guardian. Ní ọdún 1999, ní ìbẹ̀ẹ̀rè ìwé-ìròyìn Comet, wọ́n yàn án sípò aṣáájú-ọ̀nà olóòtú ìwé ìròyìn.
Ní ọdún 2006, ó tún di olóòtú aṣáájú-ọ̀nà ti ìwé-ìròyìn The Nation. Ó ti ṣètọ́jú ìwé kan "Àkọsílẹ̀ Olóòtú" ní The Nation, níbi ti ó ti kọ̀wé lórí àwọn ọ̀ràn inú ìlú, látàri lílo ọ̀nà àwàdà láti fi ṣàfihàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.[7] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Nigeria Guild of Editors (NGE) àti Nigeria Union of Journalist (NUJ).[8]
Ó jẹ́ olùfẹ́ eré-ìdárayá lọ́pọ̀lọpọ̀, pàápàá jù lọ bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá. Ó ti ní láti fi ẹ̀bùn rẹ̀ hàn níbi ìṣàfihàn kan tó ti bá bọ́ọ̀lù náà pẹ̀lú akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó wà ní ipò ogún lágbàáyé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aruna Quadri, tí ó sì ṣe dáadáa.[9]
Àtòjọ àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Omotoso ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ fún iṣẹ́ títayọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn. Díẹ̀ nínú àwọn àmì-ẹ̀yẹ náà ni; àmì-ẹ̀yẹ ti Dame ní ọdún 2010, àmì-ẹ̀yẹ ti Nigeria Media fún olóòtú tó dára jù lọ ní ọdún 2013, àmì-ẹ̀yẹ Nigeria Media Merit fún olóòtú tó dára jù lọ ní ọdún 2015, àti àmì-ẹ̀yẹ Nigeria Media Merit fún olóòtú tó dára jù lọ ní ọdún 2017.[10]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "LIST: Lagos State Commissioners and Special Advisers – 2019 – 2023". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). August 21, 2019. Retrieved 2022-09-20.
- ↑ "Former The Nation Editor Gbenga Omotosho sworn-in as Lagos Commissioner for Information" (in en-US). Marketing Edge Magazine. August 20, 2019. https://marketingedge.com.ng/former-the-nation-editor-gbenga-omotosho-sworn-in-as-lagos-commissioner-for-information/.
- ↑ Aderinola, Tayo (July 2, 2020). "Gbenga Omotoso: A Veteran Journalist par excellence". Lagos Panorama (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.
- ↑ Kehinde, Seye (January 27, 2020). "I Have Enjoyed Moving From Journalism To Public Service – LAGOS Info Comm., GBENGA OMOTOSO". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.
- ↑ Kehinde, Seye (January 27, 2020). "I Have Enjoyed Moving From Journalism To Public Service – LAGOS Info Comm., GBENGA OMOTOSO". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.
- ↑ "MR. GBENGA OMOTOSO – HONOURABLE COMMISSIONER". Ministry of Information & Strategy (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.
- ↑ "Who edits The Nation?". Media Career Services (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). August 5, 2019. Archived from the original on 2022-09-20. Retrieved 2022-09-20.
- ↑ "Gbenga Omotoso Grows Tall". Independent Newspaper Nigeria. Retrieved 2022-09-20.
- ↑ Anwankwo, Akan (August 17, 2021). "Lagos information commissioner Omotoso competes with Quadri in table tennis game". SportsBrief – Sport news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.
- ↑ "MR. GBENGA OMOTOSO – HONOURABLE COMMISSIONER". Ministry of Information & Strategy (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-20.