Glenrose Xaba
Glenrose Xaba tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹẹ̀wá ọdún 1994 jẹ́ ọmọ orílẹ̀ ède South Africa tí ó n sáré ọlọ́nà jínjìn. Ó parí ìdíje ti ipò àgbà fún àwọn obìrin ní IAAF World Cross Country Championships ní ọdún 2019 tí ó wáyé ní Aarhus, Denmark, [1] Ó parí ní ipò kẹtàdínláàádọ́rin.
Iṣẹ́-ṣíṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin kéékèèké ti IAAF World Cross Country Championships ti ọdún 2013 tí ó wáyé ní Bydgoszcz, Pólándì.
Ní ọdún 2015, ó gba ààmì-ẹ̀yẹ fàdákà níbi eré sísá mítà 10,000 ti àwọn obìnrin níbi ìdíje South African Athletics Championship tí ó wáyé ní Stellenbosch, South Africa. Ó tún gba ààmì-ẹ̀yẹ idẹ níbi ayẹyẹ eré mita ẹgbẹ̀rún-máàrún ti àwọn obìnrin. Ní ọdún 2016, ó kópa nínú ìdíje mita ẹgbẹ̀rún-mẹ̀wá ti àwọn obìnrin níbi African Championship tí ó wáyé ní Durban, South Africa.
Ní ọdún 2017, ó kópa nínú ìdíje eré sísá àwọn obìnrin àgbà níbi IAAF World Cross Country Championships tí ó wáyé ní Kampala, Uganda. Ó parí ní ipò kẹrìnlélọ́gọ́ta. Ní ọdún 2018, ó kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin àgbà níbi African Cross Country Championship tí ó wáyé ní Chlef orílẹ̀ ède Algeria.
Kò gbéwọ̀n láti kópa fún2020 Summer Olympics ní Tokyo, Japan torí pé ó ṣeléṣe.[2]
Àwọn àṣeyọrí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Representing Gúúsù Áfríkà | |||||
---|---|---|---|---|---|
2020 | World Championships (HM) | Gdynia, Poland | 16th | Half marathon | 1:09:26 |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Senior Women's races - World Cross Country Championships - REVISED PREVIEW - PREVIEW". worldathletics.org. 2004-03-19. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ "Women’s Month: Glenrose Xaba’s quest to run faster beats standing records". IOL. 20 August 2021. https://www.iol.co.za/lifestyle/health/fitness/womens-month-glenrose-xabas-quest-to-run-faster-beats-standing-records-019d2702-5ac9-40ce-9f4e-c5f05dd5c03f.
ìjápọ̀ ìta
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Glenrose Xaba níbi World Athletics