Godwin Emefiele

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Godwin Emefiele
Godwin Emefiele (lọ́wọ́ ọ̀tún) pàdẹ́ Jacob J. Lew àti Sarah Bloom Raskin
Gómìnà banki àpapò Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
3 June 2014
AsíwájúSarah Alade (Acting)[1]
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí4 Oṣù Kẹjọ 1961 (1961-08-04) (ọmọ ọdún 62)
Agbor, Delta State, Nigeria.
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
(Àwọn) olólùfẹ́Margaret Emefiele
Àwọn ọmọ2
EducationMaster of Arts degree in Finance
Alma materYunifásitì ti Nàìjíríà

Godwin Emefiele (tí a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdun 1961) jẹ́ olóṣèlú ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2][3] àti Gómìnà-àná Ilé ìfowó pamọ́ àgbà Nàìjíríà láti ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà ọdun 2014 títí di ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹfà ọdún 2023 tí Ààrẹ Bọlá Ahmed Tinubu pàṣẹ láti dá a dúró lẹ́nu iṣẹ́ nítorí ẹ̀sùn àwọn ìwà àjẹbánu kan.[4] [5]

Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Emefiele lọ Ansar Udin Primary School àti Maryland Comprehensive Secondary ní ìpínlẹ̀ Èkó, kí ó tó lọ Yunifásítì ilẹ̀ Nàìjíríà (UNN) láti tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú. Ó gba àmì-èye nínú ìmò Banking and Finance, Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó yege jù láàrin àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìyókù rẹ̀. Léyìn ìgbà tí Emefiele sin ilẹ̀ baba rẹ̀, ó padà sí Yunifásitì ti Nàìjíríà láti gba àmì-ẹyẹ Masters Degree nínú ìmò Finance ní ọdun 1986. Ni Oṣu Kẹfa Ọjọ 10, Ọdun 2023, Ẹka Awọn Iṣẹ ti Ipinle ṣe idaniloju imuni Emefiele nipasẹ oju-iwe Twitter osise rẹ. Iroyin fi to wa leti wipe won gbe e wa fun iforowero gege bi ara iwadii ninu ofiisi re.[1]. Ni Oṣu Kini ọdun 2024, ile-ẹjọ kan ni Abuja paṣẹ fun ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria lati san 100 milionu naira (€100,000) ni bibajẹ fun Godwin Emefiele fun atimọle arufin.[2].

Àwọn Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]