Human Trafficking in Nigeria
Kíkó Àwọn Ènìyàn lọ Sókè Òkun Lọ́nà Àìtọ́ láti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ìrìn àjò tó ní ṣe pẹ̀lú gbígbé obìnrin, ọmọdé àti ọkùnrin lọ́nà àìtọ́ láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sí òmíràn látàri pípa iró tàbí títan àwọn ènìyàn tó ń wá ìgbésí ayé ìrọ̀rùn jẹ.
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2001, àjo NAPTIP ṣe àfilólè wí pé wón ní àjọsepò pẹ̀lú orílẹ̀-èdè France, Gambia, Italy, Spain, Sweden àti Switzerland làti ṣe ìwádìí lórí ẹjọ́ mókànlélógún tó ní ṣe pẹ̀lú kíkọ́ àwon ènìyàn lo sí òkè-òkun lọ́nà ẹ̀bùrú.[1][2]
Ní ọdún 2019, ẹ̀tàlénígba ẹjọ́ lórí kíkó àwọn ènìyàn lọ sí òkè òkun ní ọ̀nà àìtọ́ ni àjọ NAPTIP ti jábọ̀ tí wọ́n sì tọ ọpinpin rẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà. Ọ̀kànléàádọ́rin àwọn afurasí ni àwọn Nigerian Police mu, ṣùgbọ́n áàdínlọ́gbọ̀n nínú wọn ni adé ìbàjẹ́ yìí ṣímọ́ lórí, tí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ò jábọ̀ púpọ̀ nípa irú ẹjọ́ báyìí, àwọn àjọ NAPTIP ti yọ àwọn olùfaragbá ẹgbèrúnléèjìléláàdọ́jọ kúrò nínù ìkó-ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ ní ọdún 2019.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ (UNODC) United Nations Office on Drugs and crime ṣe sọ, ìdá mẹ́wàá àwọn tí wọ́n fi ipá fà sí iṣẹ́ àṣéwó ní òkè òkun jẹ́ obìnrin láti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, tí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Èyí rí bẹ̀ nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn orílé-èdè tí ó wà ní apá Ìwọ̀orùn Áfríkà ni ó fi ojú téḿbẹ́lú obìrin, pàápàá ní orílè-èdè Nàìjíríà, èyí sì jẹ́ kí ó rọrù láti kó àwọn obìnrin lo sí òkè òkun ní ọ̀nà àìtọ́ [3]
Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ilè adúláwò ni ó bu iyán obìnrin kéré ní àwùjọ wọn. Wọ́n fún okùnrin ní ọ̀wọ̀ tó pọ̀ ju obìnrin lọ, fún ìdí èyí, wọ́n fi àyè gba ẹlẹ́yàmẹyà láàárín ẹ̀yà ìbí. Ọ̀pọ̀ òbí ni wọ́n fẹ́ràn àti náwó sí orí Ọmọkùnrin ju Obìnrin lọ. Àìní ẹ̀kó Ìwé tó péye fún ọmọbìnrin máa fà àìní iṣẹ́ gidi, èyí sì máa ń jẹ́ kí ó rọrùn láti kó wọn lọ sí òkè òkun ní ọ̀nà àìtọ́.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn afipá-múnisì yìí gbà láti tan àwọn ènìyàn jẹ, jí wọn gbé, tàbí mú wọn tipátipá. wọ́n tilẹ̀ sọ fún àwọn Obìnrin mìíràn pé iṣẹ́ ni wọn fẹ́ lọṣe láìmọ̀ pé wọ́n ti ta àwọn lẹ́rú. Ìròyìn àṣejèrè àwọn onínàbì tí wọn wà ní ilè òkèèrè jẹ́ ìdí tí àwọn mìíràn ṣe ń lọ láti yọ ara wọn kúrò nínú ìṣẹ́. Wàyìí, àwọn obìnrin wọ̀nyí kò mò pé iṣẹ́ búrúkú ní wọ́n fẹ́ fi àwọn ṣe láti fi wọ́n pawó. Yàtò sí èyí, àwọn òbí mìíràn tilẹ̀ máa ń ran ọmọ wọn lọ òkè òkun nítori ìròyìn tí wọ́n gbọ́ nípa ọrọ̀ àti àǹfàní tí ó wà ni Europe, èrò wọn nipé àwọn ra ayé tó dáa fú àwọn ọmọ àwọn. Bẹ́ẹ̀ wọn kò mò pé àwọn tí wọ́n pè ní olùrànlọ́wọ́ fẹ̀jẹ̀ sínú, tutọ́ funfun jáde ni. Ẹrú àti òwò nàbì ni wọ́n fi àwọn ọmọ náà ṣe.[4]
Ọ̀kùnfà Kíkó Àwọn Ènìyàn lọ Sókè Òkun Lọ́nà Àìtọ́ láti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láti dẹ́kun kíkó àwọn ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtó láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, a ní láti mọ ìdí ti irú ǹnkan bàyìí ṣe ń ṣẹlẹ̀. Lára àwọn ohun tí ó bí kíkó àwọn ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ láti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí ni:
- Ìṣẹ́
- Àìní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìwé
- Ìṣe káríayé
- Ìwà ìbàjẹ́
- Àìdọ́gba ẹ̀yà ìbí.
Ìṣe káríayé yìí máa ń fún àwọn afipá-múnisin yìí ni ààyè àti máa sọṣẹ́ láàárín àlà orílẹ̀-èdè. Èyí jẹ́ ìpènijà nítorí pé tí ọwọ́ bá tẹ ọ̀kan nínú àwọn afipá-múnisin yìí, yóò dínà àti mú àwọn yòókù. Ìwà ìbàjẹ́ ni ò jẹ kí mímú àwọn ọ̀daràn yìí ó rọrùn, pàápàá láàárín àwọn Olóṣèlú. Bẹ́ẹ̀ ni kò fún àwọn tó fara kááṣá ní àǹfaní láti fi ọwọ́ òfin mú àwọn oníṣẹ́ ibi yìí.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Nigeria". United States Department of State. 2021-08-05. Retrieved 2022-03-29.
- ↑ Carling, Jørgen (1 July 2005). "Trafficking in Women from Nigeria to Europe". migrationpolicy.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 January 2021.
- ↑ Arshad, Muhammad; Journal, Casestudies (2018-01-01). "Human Trafficking In Nigeria: Implications to National Development". Academia.edu. Retrieved 2022-03-29.
- ↑ "Human Trafficking in Nigeria". Africa Faith and Justice Network. 2017-07-28. Retrieved 2022-03-29.