Ifedayo Olarinde
Daddy Freeze | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ifedayo Olarinde 6 Oṣù Kàrún 1976[1] Cluj-Napoca, Romania |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan |
Iṣẹ́ | Broadcaster, media personality. |
Ìgbà iṣẹ́ | 1996–present |
Ifedayo Olarinde (Wọ́n bí i ní oṣù karùn-ún ọdún 1976), tí gbogbo ayé mọ̀ ní Daddy Freeze, jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ọmọ ilè Nàìjíríà àti Romania, àti olùdarí eto tí wọ́n tí ń fi ọ̀rọ̀-jomi-toro ọ̀rọ̀ lórí rédíò.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Ifedayo Olarinde sí Cluj-Napoca, ní orílẹ̀-èdè Romania. Ọmọ orilẹ̀-èdè Nigerian ni bàbá rẹ̀ tí ìyá rẹ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Romanian.Ó lo ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo State ní ibi tí ó ti lọ sí ilé-ìwé International School, bẹ́ẹ̀ náà ni ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Sociology ní ilé-ìwé gíga University of Ibadan.Ọmọ ìlú Oyan ni ìjọba ìbílẹ Odo Otin ní ìpínlẹ̀ Osun
Iṣẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Freeze bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣé rédíò pẹ̀lú (BCOS) ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní ìlú Ibadan níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olótùú ètò The World Chart Show. Ó darapọ̀ mọ́ Cool FM ní ọdún 2001, ọ̀gá ní ó jẹ́ nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Cool FM ti ìlú Èkó.[2] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò ló ti darí ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà àti òkè-òkun. Òun ni olùdarí #FreeTheSheeple Movement[3]
Ní ọdún 2017, Daddy Freeze bẹ̀rẹ̀ ilé-ìjọsìn ayélujára níbi tí ó ti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí ó sì ń ṣe ìsìn ní ọjọ́ àìkú àti ní àárín ọ̀sẹ̀. Ní ọdún 2020, ó kéde fífi iṣẹ́ silẹ ní Cool FM níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ogún ọdún [4]
Àwọn ìtọka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Daddy Freeze celebrates 43rd birthday with lovely family". P.M. News. May 7, 2019. https://www.pmnewsnigeria.com/2019/05/07/daddy-freeze-celebrates-43rd-birthday-with-lovely-family/. Retrieved June 16, 2019.
- ↑ Oreoluwa Bello (April 28, 2014). "Freeze of Cool FM Itemizes his secret of success". Encomium. http://encomium.ng/freeze-of-cool-fm-itemizes-his-secret-of-success/. Retrieved September 20, 2016.
- ↑ "I never denied christianity, Daddy Freeze declares". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-06-13. Archived from the original on 2021-09-25. Retrieved 2021-09-25.
- ↑ "Daddy Freeze Announces Departure From Cool FM After 20 Years". Guardian Nigeria. AKINWALE AKINYOADE. Archived from the original on 22 April 2021. Retrieved 13 March 2020.