Ijora, Lagos
Ijora je okan lara awon agbegbe ilu Eko, ni orile ede Naijiria.
Itan
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ijora je ile ira omi (swampy and water-logged) ti awon ti won n bo lati Lagos Island ko ni le de ibugbe won, aya fi ki won wo oko oju omi. Idasile ibudoko oko oju irin The establishment of a railway terminus si Ido ti o je ileto kan ti o wa ni itosi Ijora ni ni odun 1919 ni o so Ijora di pataki, eyi ni o mu ki Ijoba Amunisin da ilese Eedu si Ijora lati le ma ko Eedu fun awon oko oju irin ile Naijiria. Ni odun 1923, ijoba da ile ise ti o n yi Ooru pada si ina mana mana si Ijora lati le ma pese ina eletiriki fun awon oko oju irin ati awon agbegbe ti o sun mo Ijora lapapo. Ni odun 1960, ajo ti o n ri si eto ile kiko (town planning authority) ni ipinle Eko ati ijoba apapo pinu lati ya ile kan soto fun akojopo ile ise, ti won si tun gbale die si leyin igba naa ni Ijora.
Awon akojopo ile ise ni won n lo fun ile ise bii: K Maroun, Incar cars ati West African Cold Storage. Ibudo (wharf) Ijora naa ni o tun je ibi ti won n ko eja pamo si.
Awon Adugbo Ijora
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Awon ilu ti o sun mo Ijora ni : Ijora Oloye, Ijora-Badia ati Ijora Olopa. Opo lara awon adugbo yi ni o je wipe ero ti po ju ti opo awon ti o si n gbe ibe je mekunu. Awon afurasi iko aserubalu Boko Haram kan ni won ri gbamu ni Ijora Oloye ni odun 2013[1] ati ni odun 2016.[2]
Ijora-Olopa ni o je ibi ti won ti n ta awon ounje inu yinyin tutu (frozen foods) ni ipinle Eko.[3]
Ijora-Badia je okan lara awon adugbo ipinle Eko ti ko dagba soke sugbon ti o ni ero pupo.[4] Opo lara awon ti won koko gbe agbegbe Ijora-Badia ni won je Ameke (resettlers) lati abule Oluwole Nigba ti ijoba gba adugbo yi fun kiko Gbongan isere National Theatre ti o wa ni Iganmu ni opo eniyan ko wa si itosi ile ise oko oju irin.
Eto irina
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kiko afara Eko Bridge ti o tun je afara elekeji ti o gun ju ni o bere lati Ijora ti o si ja po mo Lagos Island. Opopona Ijora ni o je okan pataki ti won n gba lo si ebute Apapa. Nigba ti titi marose ti Oshodi si Apapa gba Ijora koja. [5]
Eto Oro Aje
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Dida ti won da akojopo ile-ise kale si Ijaora ni o sokun fa dida ile ise ti o n pon oti elerin-dodo(Seven Up) si agbegbe naa. Ijora paa paa tun sunmo ile ise akojopo ti o wa ni Iganmu ati ibudoko reluwee ti o wa ni Iddo .
.[6]
Awon Itoka si
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Agha, Eugene (March 30, 2013). "SIjora Oloye - Lagos Area Where Residents Now Use Back Doors". Daily Trust (Abuja).
- ↑ Agha, Eugene (July 11, 2016). "Six Wanted Boko Haram Suspects Arrested in Lagos". Daily Trust (Abuja).
- ↑ "Energy Crisis: Ijora Frozen Food Traders Destroy Decayed Foods worth N10 million". Metrowatchonline (Lagos). May 27, 2015. http://metrowatchonline.com/energy-crisis-ijora-frozen-food-traders-destroy-decayed-foods-worth-n10-million/.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ijora-Badia: Ghetto in the centre of excellence". Daily Trust (Abuja). August 5, 2015. http://www.dailytrust.com.ng/news/city-news/ijora-badia-ghetto-in-the-centre-of-excellence/105163.html.
- ↑ Oghifo, Bennett (October 26, 2012). "FG Opens Third Mainland Bridge November 6". This Day (Lagos) (Lagos).
- ↑ Home. Cummins West Africa/Cummins Nigeria. Retrieved on August 29, 2017. "Cummins West Africa. 8, Ijora Causeway, Ijora, Lagos"