Jump to content

Ilé kòkó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ilé kòkó

Ilé kòkó, tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1965 tí gíga tó ẹsẹ bàtà mítà márùnlé-lógọ́rún, [1] jẹ́ ilé tí ó ga jùlọ ní iwọ̀ oòru Afíríkà. Dùgbẹ̀ ní iìlú Ibadan ni Ìpínle Ọ̀yọ́, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n kọ sí. Èrè owò ọ̀gbìn (bíi Kòkó, Rọ́bà, igi) ti ìpínle ìwọ̀-oòrún ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n sì fí kọ́ ọ́

Orúkọ àkọ́kọ́ tí wọ̣́n fún ilé náà ni 'Ilé àwọn àgbẹ̀', tí ó túmọ̀ l'éde Gẹ̀ẹ́sì sí 'the house of farmers. Wọ́n padà yí orúkọ yìí sí 'ilé kòkó' nítorí wípé èrè owò ọ̀gbìn pàápàá jùlọ́ owó tí wọ́n rí látàri òwò kíkó kòkó lọ sí òkè òkun ni wón fi kọ́ọ.[2]

  1. Anthony Nkem Ede. Challenges Affecting the Development and Optimal Use of Tall Buildings in Nigeria. The International Journal of Engineering and Science. https://archive.org/stream/Httptheijes.com_201405/B03402012020_djvu.txt. Retrieved April 4, 2014. 
  2. "Explore the history of Nigeria’s Cocoa House, the first skyscraper in West Africa". Face2Face Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-12-20.