Ilera Eko
Ilera Eko ni ètò ìlera tí ìjọba Èkó gbé kalẹ̀ lábẹ́ ilé-iṣẹ́ Lagos State Health Management Agency (LASHMA) láti lè jẹ́ kí tẹrú-tọmọ, tólówó ti mẹ̀kúnù lẹ́sẹ̀ kùkú ó jẹ mùkútùn ètò ìlera tó péye pẹ̀lú owó pọ́ọ́kú. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó tún gbé ìgbésẹ̀ láti ṣí ẹ̀ka ètò ìlera yí káàkiri gbogbo agbègbè Ìpínlẹ̀ Èkó.[1]
Iṣẹ́ àjọ Ìlera Èkó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn iṣẹ́ tí àjọ ìlera Èkó gbá ń mójútó pọ̀, lára rẹ̀ ni ìpèsè ìléra lórí ìtọ́jú awọn àìsàn pẹ́pẹ̀pẹ́ bí àìsàn ibà, àìsàn ikọ́ fére, HIV. Bákan náà ni wọ́n ń ṣètọ́jú àwọn àìsàn tí kò mú iṣẹ́ abẹ rẹpẹtẹ lọ́wọ́ bíi: àìsàn làkúrègbé, àìsàn ìtọ̀-ṣúgà, àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ojúṣe wọn sì ún ni láti ṣiṣẹ́ gbógun ti ìtàkánlẹ̀ ajàkálẹ̀ arùn ní ìpínlẹ̀ náà. [2]
Àwọn ará ìlú yóò ma jẹ̀gbádùn ètò ìlera olówó pọ́ọ́kú yí nígbà tí eọ́n bá ti forúkọ sílẹ̀ sábẹ́ ilé-iṣẹ́ ọ̀hún pẹ̀lú owó péréte. Wọn yóò láànfàní sí ètò ayẹ̀wò ìlera ọ̀fẹ́, oògùn ọ̀fẹ́ ati bí wọn yóò ṣe lòó.
Ètò Ìforúkọsílẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ènìyàn yóò ma lánfaní sí oògùn ọ̀fẹ́, àyẹ̀wò ọ̀fẹ́, lórí mọ̀lèbí ẹlẹ́ni mẹ́fà. Ìyẹn (Bàbá, Ìyá, àti ọmọ mẹ́rin) pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (#40.000.00), fún odidi ọdún kan gbáko.
Agbékalẹ̀ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àjọ tó ń rí sí agbékalẹ̀ òfin ati àlàkalẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó buwọ́ lu State Health Scheme Law ní inú oṣù Karùn-ún ọdún 2015 èyí tí ó ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ , LASHMA lábẹ́ Lagos State Health Scheme (LSHS) ati the Lagos State Health Fund (LSHF).[3]
Àwọn ìtọ́ka sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "As Lagos spreads the good news of 'Ilera Eko' - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2021-09-15. Retrieved 2022-02-10.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ilera Eko". The Nation Newspaper. 2021-11-03. Retrieved 2022-02-10.
- ↑ "Health insurance: Lagos takes “Ilera Eko” to communities". Vanguard News. 2021-12-08. Retrieved 2022-02-10.