Jump to content

Ìpínlẹ̀ Kebbi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ipinle Kebbi)
Kebbi
Image showing the yearly Argungu Fishing Festival held in Argungu
Image showing the yearly Argungu Fishing Festival held in Argungu
Seal of Kebbi State
Seal
Nickname(s): 
Location of Kebbi State in Nigeria
Location of Kebbi State in Nigeria
Coordinates: 11°30′N 4°00′E / 11.500°N 4.000°E / 11.500; 4.000Coordinates: 11°30′N 4°00′E / 11.500°N 4.000°E / 11.500; 4.000
Country Nigeria
Date created27 August 1991
CapitalBirnin Kebbi
Government
 • BodyGovernment of Kebbi State
 • Governor
(List)
Nasir Idris (APC)
 • Deputy GovernorAbubakar Umar Argungu (APC)
 • LegislatureKebbi State House of Assembly
 • SenatorsC: Adamu Aliero (PDP)
N: Yahaya Abdullahi (PDP)
S: Bala Ibn Na'Allah (APC)
 • RepresentativesList
Area
 • Total36,800 km2 (14,200 sq mi)
Area rank10th of 36
Population
 (2006 census)
 • Total3,256,541[1]
 • Rank22nd of 36
Demonym(s)Kebbian
GDP (PPP)
 • Year2023
 • Total$16.6 billion[2]
 • Per capita$2,896[2]
Time zoneUTC+01 (WAT)
postal code
860001
ISO 3166 codeNG-KE
HDI (2018)0.339[3]
low · 37th of 37
Websitekebbistate.gov.ng

Ìpínlẹ̀ Kébí tí ìfohùnpè rẹ̀ lèdè Hausa àti àwọn èxè míràn ń jẹ́ (Àdàkọ:Lang-ha; Fulfulde: Leydi Kebbi 𞤤𞤫𞤴𞤣𞤭 𞤳𞤫𞤦𞥆𞤭) jẹ́ ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ tí ó wà ní apá òkè ọya àti ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ pààlà pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ míràn bíi: Ìpínlẹ̀ Sokoto, Ìpínlẹ̀ Zamfara Ìpínlẹ̀ Niger àti orílẹ̀-èdè olómìnira Benin.[4] Wọ́n ṣẹ̀dá Ìpínlẹ̀ yí látara Ìpínlẹ̀ Sokoto ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n.oṣù kẹjọ ọdún 1991, tí wọ́n sì sọ olú-ìlú ìpínlẹ̀ náà ní Birnin Kebbi.[5] Of the 36 states of Nigeria, Kebbi is the tenth largest in area and 22nd most populous, with an estimated population of about 4.4 million as of 2016.[6] Orúkọ ìnagijẹ ìpínlẹ̀ náà á ma jẹ́ ilẹ̀ ẹ̀tọ́ (land of equity]][4] Bí a bá ní kí á wo ilẹ̀ ìpínlẹ̀ náà, ìpínlẹ̀ yí jẹ́ ilẹ̀ igbó tí òjò sì ma ń rọ̀ níbẹ̀ dára dára. Lára àwọn ohun tó mú ìpínlẹ̀ yí yàtọ̀ sí àwọn ìpínlẹ̀ tó yiká ni wípé oní iṣàn omi odò tí ó ń bọ̀ láti Ìpínlẹ̀ Sokoto tí omi náà sì ṣàn lọ sí inú adágún odò Kainji. Lára àwọn àrà tí ó tún wà ní ìpínlẹ̀ yí náà ni àwọn ẹja àràmàndà tí àwọn apẹja ma ń pa lásìkò ọdún ẹja Argungu, bákan náà ni àwọn ẹrankoerinmilókun, erin igbó ati àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ pe sí jùlọ.[7]

Oríṣiríṣi ẹ̀yà bíi: Nupe, Fúlàní, Zaram àti àwọn ẹ̀yà Hausa ni wọ́n ń gbé ìpínlẹ̀ yí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ẹ̀yà bíi: Achipa (Achipawa), Boko-Bala, Dendi, Dukawa, Kambari, Kamuku, Lela, Puku, àti àwọn Shanga náà ń gbé ní agbègbè apá ìwọ̀ àti ìlànà Oòrùn ìpínlẹ̀ náà. Púpọ̀ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ìdá ọgọ́rin lé mẹ́rin ni wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí nígbà tí àwọn tókù jẹ́ ẹlẹ́sìn Krìstẹ́nì ati àwọn ẹlẹ́sìn Bori.[8] Ibi tí ó di Ìpínlẹ̀ Kebbi lóní láyé àtijọ́ ni ó wà lábẹ́ ìṣàkóso ilẹ̀ Ọba Kebbi tí wọ́n jẹ́ Hausa bakwai state, tí tí si ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1800 kí àwọn ajìjà ẹ̀sin Fúlàní gba dí ẹ̀ lára ilẹ̀ náà sí abẹ́ ìṣàkóso ìjọba Gwandu Emirate lábẹ́ ìṣàkóso Sokoto Caliphate. Lẹ́yìn ìjà ẹ̀sìn yí, àwọn ọmọ ìlú Kebbi ti ń bá àwọn ènìyàn Sókótó jà ní gbogbo ìgbà ṣáájú kí àwọn gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn tó fipá gba ilẹ̀ náà tí wọ́n sì ń ṣakóso rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ 1900 títí di 1910 títí di ọdún 1960 tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gba òmínira. [9].

Àwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Unsourced section

Ìpínlẹ̀ Kebbi ní ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún àti ilẹ̀ Ọba mẹ́rin (Gwandu, Argungu, Yauri and Zuru),

Àwọn ẹ̀ka èdè ibẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn èdè tàbí ẹ̀ka èdè tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ kébi pọ̀, àmọ́ èdè Hausa ni ó gbajú-gbajà jùlọ. [10]

LGA Languages
Argungu Dendi; Zarma
Bagudo Bisã; Boko; Dendi; Kyenga
Birnin Kebbi Zarma
Bunza Zarma
Donko-Wasagu C'Lela
Dukku us-Saare
Jega Gibanawa
Ngaski Cishingini; Lopa; Tsikimba; Tsishingini; Tsucuba; Tsuvadi
Sakaba Cicipu; C'Lela; Damakawa; ut-Ma'in
Shanga Shanga
Wasagu-Danko us-Saare; Gwamhi-Wuri
Yauri Reshe; us-Saare
Zuru C'Lela; ut-Ma'in

Àwọn èdè míràn tí wọ́n tún ń sọ níbẹ̀ ni èdè Fulfulde, Ut-Hun, àti Sorko.[10]

Ìpínlẹ̀ Kebbi gẹ́gẹ́ bí àwọn ìpínlẹ̀ tókù ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ń lo gómìnà, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. [11]Àwọn ohun àlùmọ́nì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpínlẹ̀ Kebbi ní àwọn ohun àlùmọ́nì oríṣiríṣi tí ó lè mú ìdàgbà-sókè bá ìlú àti àwọn ènìyàn ibẹ̀. Lára rẹ̀ ni: [12]


Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
 1. "2006 PHC Priority Tables – NATIONAL POPULATION COMMISSION". population.gov.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-10-10. Retrieved 2017-10-10.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
 2. 2.0 2.1 "TelluBase: Nigeria Extract" (PDF). Tellusant. Archived from the original (PDF) on 2024-01-06. Retrieved 2023-06-01. 
 3. "Sub-national HDI - Area Database - Global Data Lab". hdi.globaldatalab.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-09-13. 
 4. 4.0 4.1 "Kebbi State". Nigerian Investment Promotion Commission (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-01-07. Retrieved 2022-02-27. 
 5. "This is how the 36 states were created". Pulse.ng. 24 October 2017. Retrieved 22 December 2021. 
 6. "Population 2006-2016". National Bureau of Statistics. Retrieved 21 December 2021. 
 7. Ojo, Demola. "Family of Elephants Make Kebbi Their Home". ThisDay. Retrieved 25 December 2021. 
 8. Okpanachi, Eyene (2011). "Between Conflict and Compromise: Lessons on Sharia and Pluralism from Nigeria Kaduna and Kebbi States". Emory International Review 25 (2): 900. https://scholarlycommons.law.emory.edu/eilr/vol25/iss2/7. 
 9. George Steinmetz (1999). State/culture: state-formation after the cultural turn. Cornell University Press. p. 231. ISBN 0-8014-8533-9. https://books.google.com/books?id=3B-WGiysQGMC&pg=PA231. Retrieved 25 December 2021. 
 10. 10.0 10.1 "Nigeria". Ethnologue. https://www.ethnologue.com/country/NG. 
 11. "Premium Times". 
 12. Diala, Sam; THEWILL (2021-09-26). "State Of The States: Kebbi". thewillnigeria.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-04. 

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Nigeria states Àdàkọ:Authority control Àdàkọ:Portal bar