Jesse King
Jesse King tí gbogbo ayé mọ̀ sí "BÙGÁ" jẹ́ olórin ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ìwọ́hùn orin rẹ̀ jẹ́ ti èdè Yorùbà tí gbogbo orin rẹ̀ sìjẹ́ èyí tí ó ǹ gbé àṣà àti èdè Yorùbà lárugẹ. Ní ọdún 2016, ó pè fún ìkún -lápá àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti dìbò gbé ÀàrẹMuhammadu Buhari wọlé kí Ààrẹ náà lè mù ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Nàìjíríà dúró ṣinsin.[1]
Ìgbòkè-gbodò Iṣẹ́ orin rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Jesse King gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó sọọ́ di ìlúmọ̀ọọ́ká jáde ní ọdún 2006 tí ó porúkọ rẹ̀ ní "BUGA". Àmọ́ ṣáájú ìgbàyí, ó ma ń ṣe ìpolongo àti ìpolówó ọjà lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì, tí ó sì tún bá àwọn ẹlòmíràn gné àwo orin wọn jáde farayé gbọ́. Ó ti fìgbà kan rí jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ asọ̀rọ̀-mágbè sì ti ìpínlẹ̀ Òndó àti ti d Ìpínlẹ̀ Èkìtì . Jesse King tí wọ́n bí ní ìlú Auchi ṣùgbọ́n tí ó gbé ní ìlú Èkó , kẹ́ ẹnintì orin rẹ̀ gbajúmọ̀ láàrín àwọn ẹ̀yà Yorùbá pàápàá ní ìpínlẹ̀ Òndó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe Adékúnlé Ajáṣin ní ìpínlẹ̀ Òndó ní ọdún 1999.[2][3][4]
- ↑ "Jesse ‘Buga’ King Urges Support For Buhari - Greennews.ng" (in en-US). Greennews.ng. 2016-05-31. Archived from the original on 2016-07-09. https://web.archive.org/web/20160709062920/http://greennews.ng/jesse-king-buga-urges-nigerians-to-support-buhari/.
- ↑ "WHY I SING WITH MY QUEENS – JESSE KING" (in en-GB). ModernGhana.com. https://www.modernghana.com/movie/1580/why-i-sing-with-my-queens-jesse-king.html.
- ↑ "Why I’m staging a concert to explain Eko-Benin connection - Jesse King ‘Buga’ - Vanguard News" (in en-US). Vanguard News. https://www.vanguardngr.com/2013/10/im-staging-concert-explain-eko-benin-connection-jesse-king-buga/.
- ↑ "I am married to many wives – Jesse King" (in en-gb). Nigeriafilms.com. https://www.nigeriafilms.com/music-news/78-musical-news/5532-i-am-married-to-many-wives-jesse-king.