Jump to content

Joan Fontaine

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Joan Fontaine
Fontaine in 1943
Ọjọ́ìbíJoan de Beauvoir de Havilland
(1917-10-22)Oṣù Kẹ̀wá 22, 1917
Tokyo City, Empire of Japan
AláìsíDecember 15, 2013(2013-12-15) (ọmọ ọdún 96)
Carmel Highlands, California, U.S.
Orúkọ míràn
  • Joan Burfield
Ọmọ orílẹ̀-èdè
  • United Kingdom
  • United States (from 1943)[1]
Iléẹ̀kọ́ gígaAmerican School in Japan
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1935–1994
Olólùfẹ́
Àwọn ọmọ2
Parents
Àwọn olùbátan
AwardsAcademy Award for Best Actress (1941)

Joan de Beauvoir de Havilland tí wọn bí ní Ọjọ́ eejilélógún oṣù Kẹwàá ọdún 1917 – Ọjọ́ àrùnlélógún oṣù Kejìlá ọdún 2013),ẹni tí a mọ̀ sí Joan Fontaine nínú iṣẹ́ òṣèré rẹ̀, jẹ́ òṣèré ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Ó gbajúgbajà jùlọ fún àwọn ipa tí ó ṣe nínú àwọn fíìmù Hollywood ní àkókò tí a mọ̀ sí Àkókò Wúrà ti Hollywood (Golden Age of Hollywood).Fontaine kópa nínú fíìmù tó ju mẹ́rìnlélógójì (45) lọ ní gbogbo iṣẹ́ òṣèré rẹ̀, tí ó gba àkókò tó lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́ta (50).Ó jẹ́ àbúrò òṣèré Olivia de Havilland.ìforígbárí tó wà láàárín àwọn arábìnrin méjèèjì yìí jẹ́ ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àkókò tí Fontaine wà ní góńgó iṣẹ́ òṣèré rẹ̀.

Fontaine bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré fíìmù rẹ̀ ní ọdún 1935,nígbà tí ó fọwọ́ sí àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ RKO Pictures. Ó gba àwọn ipa pàtàkì rẹ̀ àkọ́kọ́ nínú The Man Who Found Himself (1937) àti Gunga Din (1939).Ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ túbọ̀ ṣí sí i lẹ́yìn tí ó ṣe ipa àkọ́kọ́ nínú fíìmù Rebecca (1940), tí Alfred Hitchcock darí.Fíìmù yẹn ló mú kí ó gba ìyànjú àkọ́kọ́ nínú ìyànjú mẹ́ta fún Academy Award for Best Actress. Ní ọdún tó tẹ̀lé, ó gba àmì ẹ̀yẹ náà fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù Hitchcock Suspicion (1941). Ó tún gbà ìyànjú kẹta fún The Constant Nymph (1943).Ní gbogbo ọdún 1940 sí i, Fontaine ṣe púpọ̀ nínú àwọn fíìmù eré(drama), títí kan Letter from an Unknown Woman àti fíìmù apanilẹ́rìn-ín You Gotta Stay Happy (wọ́n méjèèjì jáde ní 1948).Òun àti ọkọ rẹ̀ kejì, William Dozier, ló ṣejádù fíìmù You Gotta Stay Happy nípasẹ̀ ilé-iṣẹ́ wọn, Rampart Productions.Ní ọdún mẹ́wàá tó tẹ̀lé, lẹ́yìn ipa rẹ̀ nínú Ivanhoe (1952), iṣẹ́ òṣèré fíìmù rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, ó sì yí padà sí eré onípele, rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Ní ọdún 1960 sí i, ó ṣe díẹ̀ nínú àwọn fíìmù, títí kan Voyage to the Bottom of the Sea (1961). Ipa fíìmù rẹ̀ tó gbẹ̀yìn ni nínú The Witches (1966), tí a tún mọ̀ sí The Devil's Own.

Ní ọdún 1978, ó tẹ ìwé ìrántí ara rẹ̀ jáde pẹ̀lú àkọlé No Bed of Roses. Ó sì tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ òṣèré títí di ọdún 1994.Àmì ẹ̀yẹ Academy Awards tí ó gba fún Suspicion jẹ́ kó di òṣèré obìnrin kan ṣoṣo tó ti gba Ẹ̀bùn Oscar fún iṣẹ́ òṣèré nínú fíìmù tí Alfred Hitchcock darí.Òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Olivia de Havilland , ṣì jẹ́ àwọn arábìnrin kan ṣoṣo tí wọ́n ti gba àmì ẹ̀yẹ Academy Awards fún ipa àkọ́kọ́ (lead acting).

Fontaine with sister Olivia de Havilland (center) and mother Lilian Fontaine, c. 1922

Joan de Beauvoir de Joan de Beauvoir de Havilland ni wọ́n bí ní ọjọ́ 22 oṣù Kẹwàá, ọdún 1917, ní ìlú Tokyo, ní ilẹ̀ tí a mọ̀ sí Ìjọba Japan (Empire of Japan) nígbà yẹn, láti ọwọ́ àwọn òbí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.Bàbá rẹ̀, Walter de Havilland (1872–1968), kẹ́kọ̀ọ́ ní University of Cambridge. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Imperial University ní Tokyo kí ó tó di agbẹjọ́rò tó ń bójú tó ẹ̀tọ́ ìdasilẹ̀ (patent attorney).Ìyá rẹ̀, Lilian Fontaine (1886–1975), kẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ òṣèré ní Royal Academy of Dramatic Art (RADA) ní ìlú London. Ó di òṣèré eré onípele, ṣùgbọ́n ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ọkọ rẹ̀ lọ sí Tokyo. Lẹ́yìn tí Joan àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Olivia de Havilland, di olókìkí ní ilé iṣẹ́ fíìmù ní ọdún 1940 sí i, ó padà sí iṣẹ́ òṣèré pẹ̀lú orúkọ ìtàgéLilian Fontaine. Arákùnrin bàbá Joan, Sir Geoffrey de Havilland (1882–1965), jẹ́ oníṣe ọkọ̀ òfurufú tó di olókìkí nítorí ọkọ̀ òfurufú de Havilland Mosquito, ó sì tún dá ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú de Havilland sílẹ̀.Bàbá bàbá Joan, Reverend Charles Richard de Havilland, jẹ́ ọmọ ìdílé de Havilland láti erékùṣù Guernsey , tó wà lára àwọn Erékùṣù Channel (Channel Islands).

De Havilland's parents married in 1914 and separated in 1919 when she was two; the divorce was not finalized, however, until February 1925.[2]

Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn dókítà kan, Lilian de Havilland kó Joan, ẹni tí ara rẹ̀ máa ń ṣàìlera, tí ó sì ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ kéré (anaemia) lẹ́yìn tí ó ní àrùn measles àti àkóràn streptococcal papọ̀, pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.[3][2] Ìdílé náà gbé kalẹ̀ ní Saratoga, ìlera Fontaine sì sunwọ̀n sí i gan-an nígbà tó wà ní ọjọ́-ori ọdọ́ rẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga Los Gatos (Los Gatos High School) tó wà nítòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹ̀kọ́ ìsọ̀rọ̀ tó péye (diction) pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Olivia de Havilland. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), Joan padà sí Japan láti lọ gbé pẹ̀lú bàbá rẹ̀. Níbẹ̀, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní American School in Japan, ó sì parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ọdún 1935.[4]

  1. ↑ Weatherford 2009, p. 302.
  2. 1 2 Bubbeo, Daniel (2002). The Women of Warner Brothers: The Lives and Careers of 15 Leading Ladies, with Filmographies for Each. McFarland & Company. p. 55. ISBN 978-0-7864-1137-5. https://books.google.com/books?id=nmjetV92THsC&pg=PP1. Retrieved April 1, 2014.
  3. ↑ Fontaine 1978, p. 19.
  4. ↑ "Prominent Alumni." Archived March 3, 2012, at the Wayback Machine. The American School in Japan. Retrieved October 6, 2011.