Kadaria Ahmed

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kadaria Ahmed
Ọjọ́ìbíKadaria Ahmed
Orílẹ̀-èdèNigerian, British
Iléẹ̀kọ́ gígaBayero University Kano, Goldsmiths, University of London
Iṣẹ́Journalist, entrepreneur, editor
Parent(s)Hafsat Abdulwaheed (mother)
Websitedaria.media

Kadaria Ahmed tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ akọ̀rọ̀yìn,[1] oníṣòwò ìgbéròyìnjáde àti olùgbàlejò lórí tẹlifíṣọ́ọ̀nù.[2] BBC ní ìlú London ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó yàn láàyò. Ó sì ti ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde, rédíò, tẹlifíṣọ́ọ̀nù àti àwọn àwùjọ ìgbéròyìnjáde lórí ẹ̀rọ ayélujára.[3]

Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ahmed gboyè MA nínú Television ní Goldsmiths, University of London, àti Bachelor'sBayero University Kano. Ó tún jẹ́ Chevening Scholar.[4]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó yàn láàyò ní BBC[5] níbi tí ó ti jẹ́ olóòtú àgbà tó ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ètò bíi Focus on Africa àti Network Africa tó ń gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi.[6]

Nígbà tó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi alátùnńkọ fún Next (Nigeria) èyí tí ó jẹ́ àgbéjáde-ìwé tó ń gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi. Níbẹ̀ ni ó ti mójú tó yàráìkọ̀ròyìn tó ní bíi ọgọ́fà èèyàn àti ọgbọ̀n òṣìṣẹ́ mìíràn láti jíròrò lórí ìṣàtúnkọ ìwé tọ́ ń gbé jáde. Ilé-iṣẹ́ náà dáwọ́ ìgbéwèéjáde dúró ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2011.[7][8]

Ní ọdún 2011, ó ṣatọ́kùn ìtàkurọ̀sọ láàárín àwọn olùdìbò fún ipò Ààrẹ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún náà.[9][10][11]

Ní ọdún 2014, ó ṣolóòtú Straight Talk tó jẹ́ ètò ìgbàlejò àwọn tó ń rí sí dídá ìpinnu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[12] Ètò náà di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà tí iye àwọn èèyàn tó ń wò ó ju mílíọ̀nù mẹ́rin lọ. Díẹ̀ lára àwọn èèyàn tó gbà lálejò tí ó sì ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú wọ́n lórí ètò náà ni Ibrahim Babangida, Tonye Princewill,[13] Babatunde Fashola, Rotimi Amaechi, Ali Baba, Oby Ezekwesili.[14]

Ní ọdún 2017, ó gbétò tuntun kan The Core kalẹ̀ lórí Channels TV.[15][16][17] Ní oṣù July ọdún 2017, ó ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Nnamdi Kanu tí ó jẹ́ olórí àwọn Indigenous People of Biafra (IPOB)[18] tí ó sì ń kéde Biafra tàbí ikú.[19]

Ní ìgbáradì fún ìdìbò ọdún 2019, ó ṣatọ́kùn Town Hall Meeting fún àwọn olùdìbò fún ipò Ààrẹ àti igbákejì wọn.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, Ahmed jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ onídàájọ́ fún Wole Soyinka Centre for Investigative Journalism [20] àti ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ olùtọ́jú ti Premium Times Centre for Investigative Journalism [21] àti Promasidor Quill awards. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Nigerian Guild of Editors àti Nigerian Institute of Directors.

Ní ọdún 2017, ó dá Daria Media Ltd sílẹ̀, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó rí sí ìgbélárugẹ iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn.[22][23]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìròyìn tí Ahmed ti kọ lóríṣiríri ni wọ́n ti ṣàgbéjáde ẹ̀ nínú àwọn ìwéìròyìn nílẹ̀ wa àti lágbàáyé bíi Daily Trust, The Guardian, àti the Financial Times of London.

Ó sì ti ṣàtúnkọ iṣẹ́ àgbéjáde méjì. Àkọ́kọ́ ni Nigeria the Good News, ní ọdún 2012,[24][25]

Ní ọdún 2014 Henrich Boell Foundation fún láṣẹ láti ṣàgbéjáde ìwé tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ‘Lagos – A Climate Resilient Megacity’.[26]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Stocks". Bloomberg L.P. Retrieved 22 November 2017. 
 2. Matazu, Hafsah Abubakar (15 April 2017). "Why IBB is one of my favourite guests on Straight Talk". The Daily Trust. Archived from the original on 1 December 2017. https://web.archive.org/web/20171201033038/https://www.dailytrust.com.ng/news/general/-why-ibb-is-one-of-my-favourite-guests-on-straight-talk/193679.html. 
 3. "Kadaria Ahmed". kabafest.org. Retrieved 27 November 2017. 
 4. "AHMED, Kadaria". Biographical Legacy and Research Foundation. 2019-01-17. Retrieved 2020-05-03. 
 5. "Kadaria Ahmed". kabafest.org. Retrieved 22 November 2017. 
 6. "Kadaria Ahmed's schedule for IPI World Congress 2018". IPI World Congress 2018. 2013-12-17. Retrieved 2020-05-03. 
 7. Matazu, Hafsah Abubakar (2017-12-17). "Kadaria at 50: Giving back to the media – Daily Trust". Daily Trust. Retrieved 2020-05-03. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
 8. siteadmin (23 September 2011). "234Next Newspaper To Shut Down Print Edition This Weekend | Sahara Reporters". Sahara Reporters. http://saharareporters.com/2011/09/23/234next-newspaper-shut-down-print-edition-weekend. 
 9. "Watch the NN24 Nigerian Presidential Debate Moderated by Kadaria Ahmed Part 1 (Video) | Ladybrille®Nigeria | LadybrilleNigeria". ladybrillenigeria.com. Archived from the original on 1 December 2017. Retrieved 27 November 2017. 
 10. "Thoughts on the Nigerian Presidential Debate". Naijarules.com. Archived from the original on 19 April 2019. https://web.archive.org/web/20190419103222/https://www.naijarules.com/index.php?threads/thoughts-on-the-nigerian-presidential-debate.39812/. 
 11. "Nigeria Presidential Debates » All Things Nigeria". allthingsnigeria.com. Retrieved 27 November 2017. 
 12. "Kadaria Ahmed of defunct NEXT newspapers launches news and current affair programme on Channels TV – Premium Times Nigeria". Premium Times Nigeria. 2 April 2014. https://www.premiumtimesng.com/news/157955-kadaria-ahmed-defunct-next-newspapers-launches-news-current-affair-programme-channels-tv.html. 
 13. "Explosive Interview With Kadaria Ahmed: Amaechi, APC Far Worse Than Jonathan—Princewill". Nigerian Voice. https://www.thenigerianvoice.com/news/150893/1/explosive-interview-with-kadaria-ahmed-amaechi-apc.html. 
 14. "Your favorite newspapers and magazines.". PressReader.com. 2017-06-04. Retrieved 2020-05-03. 
 15. Newsdiaryonline (6 June 2017). "'The Core' Debuts on Channels TV, Anchored by Kadaria Ahmed Newsdiaryonline". Newsdiaryonline. https://newsdiaryonline.com/core-debuts-channels-tv-anchored-kadaria-ahmed/. 
 16. Egbas, Jude. "Kadaria Ahmed: Ace journalist anchors new TV show". http://www.pulse.ng/entertainment/movies/kadaria-ahmed-ace-journalist-anchors-new-tv-show-id6802293.html. 
 17. "Daria Media's 'The Core' debuts on Channels TV, to be anchored by Kadaria Ahmed – Daily Times Nigeria". Daily Times Nigeria. 6 June 2017. https://dailytimes.ng/entertainment/daria-medias-core-debuts-channels-tv-anchored-kadaria-ahmed/. 
 18. "It is either Biafra or death – Nnamdi Kanu insists [VIDEO – Daily Post Nigeria"]. Daily Post Nigeria. 6 July 2017. http://dailypost.ng/2017/07/06/either-biafra-death-nnamdi-kanu-insists-video/. 
 19. "It is either Biafra or death – Nnamdi Kanu insists [VIDEO – Daily Post Nigeria"]. Daily Post Nigeria. 6 July 2017. http://dailypost.ng/2017/07/06/either-biafra-death-nnamdi-kanu-insists-video/. 
 20. "Wole Soyinka Centre for Investigative Journalism  » Judges". ng.wscij.org. Archived from the original on 30 November 2017. Retrieved 27 November 2017. 
 21. "Foremost journalist Kadaria Ahmed debuts new show with focus on petroleum industry bill – Premium Times Nigeria". Premium Times Nigeria. 7 June 2017. https://www.premiumtimesng.com/news/top-news/233293-foremost-journalist-kadaria-ahmed-debuts-new-show-with-focus-on-petroleum-industry-bill.html. 
 22. "Daria Media announces training, scholarships for Nigerian journalists – Premium Times Nigeria". Premium Times Nigeria. 7 November 2017. https://www.premiumtimesng.com/news/more-news/248622-daria-media-announces-training-scholarships-for-nigerian-journalists.html. 
 23. "Are you a female journalist? This opportunity could be yours – TheCable". TheCable. 10 November 2017. https://www.thecable.ng/female-journalist-opportunity. 
 24. "Nigeria the good news - www.channelstv.com". Channels Television. 27 October 2012. https://www.channelstv.com/2012/10/27/nigeria-the-good-news/. 
 25. "Nigeria the good news". Nglifestyle. Archived from the original on 1 December 2017. https://web.archive.org/web/20171201033725/https://nglifestyle.me/ng/videos/nigeria-the-good-news/. 
 26. "Megacity Lagos". Heinrich Böll Stiftung Nigeria. https://ng.boell.org/megacity-lagos.