Kikelomo
Ìrísí
Kíkẹ́lọmọ audio (ìrànwọ́·ìkéde) jẹ́ orúkọ obìnrin tó wọ́pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń fúnni ní orírun Yorùbá tó túmọ̀ sí pé “a gbọ́dọ̀ tọ́jú ọmọ”. Ìdínkù rẹ̀ ni "Kíkẹ́".[1][2]
Orírun àti Ìtumọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kíkẹ́lọmọ jẹ́ orúkọ àbínibí Yorùbá, ní gúúsù ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ní èdè Yorùbá, a máa ń túmọ̀ orúkọ náà lọ́pọ̀ ìgbà láti túmọ̀ sí “kí a kẹ́ ọmọ” tàbí “kí a ṣìkẹ́ ọmọ”. Nítorí náà, orúkọ náà bo ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ àti ipò tí ọmọ wà nínú ẹbí, èyí tí ó fi ìtẹnumọ́ tí àṣà Yorùbá ní lórí ìfẹ́ àti ìdè okun ìdílé hàn.
Gẹ́gẹ́ bí àṣà Yorùbá ti fihàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, orúkọ Kíkẹ́lọmọ yìí ni a sábà máa ń fún àwọn obìnrin, tí ó ń fi ète àti ìgbàgbọ́ àwọn òbí hàn fún ọmọ náà láti rí àpọ̀jù ìfẹ́ àti àbójútó.[2]
Àwọn ènìyàn olókìkí tí ó ń jẹ́ orúkọ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Kikelomo Longe, Olóṣèlú Nàìjíríà
- Florence Kikelomo Ajayi, Agbábọ́ọ̀lù ààbò Nàìjíríà
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Kíkẹ́lọmọ". www.yorubaname.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-10-06.
- ↑ 2.0 2.1 "The meaning and history of the name Kikelomo". Venere. 2024-06-29. Retrieved 2024-10-06.