Kofoworola Abeni Pratt
Olóyè Kofoworola Abeni Pratt Hon. FRCN | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1910 Nàìjíríà |
Aláìsí | Ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù kẹfà ọdún 1992 |
Orílẹ̀-èdè | Ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjióríà |
Iṣẹ́ | Olùtọ́jú aláìsàn |
Olóyè Kofoworola Abeni Pratt Hon. FRCN (1910–1992) jẹ́ olùtọ́jú aláìsàn tí wọ́n bí sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó jẹ́ olùtọ́jú aláìsàn dúdú tí ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú National Health Service.[1] Ó sì jẹ igbákejì ààrẹ ti International Council of Nurses àti ènìyàn dúdú àkọ́kọ́ tí ó má a jẹ́ Chief Nursing Officer fún Nàìjíríà, tí ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Federal Ministry of Health.[2][3]
Wọ́n bí Pratt is ẹbí olókìkí kan ní Nàìjíríà, ó kàwé láti dí olùkọ́ ní United Missionary College ní Ibadan, lẹ́yìn tí bàbà rẹ̀ kò fi taratara fọwọ́sí pé kí ó ṣe iṣẹ́ ìtọ́jú aláìsàn.[4] Lati 1936 sí 1940 ó jẹ́ olùkọ́ ní Church Missionary Society girls' school ní Nàìjíríà.[4]
O fẹ́ òyìnbó, Dr. E. S. O. Pratt,[4] lẹ́yìn tí ó kọjá sí England ní ọdún 1946,[4] ó kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìtọ́jú aláìsàn ní Nightingale School tí ó wà ní St Thomas' Hospital, ní London,[1][3] ó sì yege gẹ́gẹ́ bí State Registered Nurse ní ọdún 1950.[4] Kò wọ́pọ̀ kí wọ́n gba ẹni tí ó ti lọ́kọ lati ṣisẹ́ ìtọ́jú aláìsàn ní àkókò yẹn.[3]
Ní àkókò rẹ̀ ní London, ó jáfáfá ní ẹgbẹ́ West African Students' Union,[4] ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ́ lati àwọn orílẹ̀ èdè tó wà ní ìwọ oòrùn Afíríkà tí wọ́n ń kàwé ní United Kingdom, tí ó sì jẹ́ pé ní ọdún 1942, wọ́n jà fitafita fún òmìnira àwọn ìletò ìwọ oòrùn Gẹ̀ẹ́sì.[5]
Pratt padà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ọdún 1954. Wọ́n yàn-án ní ògá àwọn olùtọ́jú aláìsàn lóbìrin ní University College Hospital ní Ibadan nínú ọdún mẹ́ẹ̀wá, tí ó jẹ́ pé òhun ní ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí ó má a di ipò yìí mú.[4] Ó jẹ́ alábójútó fún ètò ìléra ti ìlú èkó ní bí ọdún 1970.[6]
Ní ọdún 1973 ó gba ẹ̀bùn Florence Nightingale Medal lati ọwọ́ International Committee of the Red Cross.[7]
Ààrẹ Nigerian Red Cross Society, Sir Adetokunbo Ademola, ní ó fun ní ẹ̀bùn yìí ní ọjọ́ ọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún1973.[8]
Ní ọdún 1979 wọ́n sọọ́ dí ọmọ ẹgbẹ́ Royal College of Nursing; èyí tí wọ́n fi dáa lọ́la[9]
Ó kú ní ọjọ́ kejìdínlógún Oṣù kẹfà ọdún 1992.[10]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Wonderful adventures: How did Mary Seacole come to be viewed as a pioneer of modern nursing?". Times Literary Supplement: p. 14-15. 6 December 2013. Archived from the original on 4 April 2016. https://web.archive.org/web/20160404064726/http://www.uoguelph.ca/~cwfn/short/tls-seacole.htm. Retrieved 11 July 2016.
- ↑ Bell, L. M. (October 1967). "Kofoworola Abeni Pratt; third vice-president, International Council of Nurses". Int Nurs Rev. 14 (5): 7–10. PMID 4864502.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 "Listener Week".
- ↑ 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 4.5 4.6 Matera, Marc (May 2008). Black Internationalism and African and Caribbean Intellectuals in London 1919–1950. doi:10.7282/T38S4Q7V. https://rucore.libraries.rutgers.edu/rutgers-lib/24439/. Retrieved 11 July 2016.
- ↑ Hakim Adi, West Africans in Britain 1900–1960: Nationalism, Pan-Africanism and Communism, London: Lawrence & Wishart, 1998.
- ↑ "Kofoworola Abeni Pratt" Archived 2016-08-05 at the Wayback Machine..
- ↑ "Twenty-fourth award of the Florence Nightingale Medal". International Review of the Red Cross (146): 242. May 1973. https://www.loc.gov/rr/frd/Military_Law/pdf/RC_May-1973.pdf. Retrieved 11 July 2016.
- ↑ "Twenty-fourth award of the Florence Nightingale Medal". International Review of the Red Cross (147): 250. May 1974. https://www.loc.gov/rr/frd/Military_Law/pdf/RC_May-1974.pdf. Retrieved 11 July 2016.
- ↑ "RCN Fellowship and Honorary Fellowship Roll of Honour"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́] (PDF).
- ↑ "In the estate of Kofoworola Abeni Pratt deceased". The Times: p. 16. 24 April 1993. http://find.galegroup.com/ttda/newspaperRetrieve.do?sgHitCountType=None&sort=DateAscend&tabID=T003&prodId=TTDA&resultListType=RESULT_LIST&searchId=R1&searchType=BasicSearchForm¤tPosition=1&qrySerId=Locale%28en%2C%2C%29%3AFQE%3D%28tx%2CNone%2C22%29Kofoworola+Abeni+Pratt%24&retrieveFormat=MULTIPAGE_DOCUMENT&userGroupName=lancs&inPS=true&contentSet=LTO&&docId=&docLevel=FASCIMILE&workId=&relevancePageBatch=IF501975871&contentSet=TDA&callistoContentSet=TDA&docPage=article&hilite=y. Retrieved 11 July 2016.