Jump to content

Kudirat Abiola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kudirat Abíọ́lá
Ọjọ́ìbí1951
Zaria, Nigeria
Aláìsí4 June,1996
Lagos
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Olólùfẹ́M. K. O. Abíọ́lá
Àwọn ọmọ7

Kúdíràtù Abíọ̀lá, tí wọ́n bí i ní ọdún 1951, ó sì kú ní ọjọ́ kẹrin Oṣù Kẹfà, ọdún 1996,[1][2] jẹ́ òṣèlú àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó M. K. O. Abíọ́lá.[3]

Wọ́n bí i ní ọdún 1951 ní Zaria, ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Alhaja Kúdíràtù Abíọ̀lá ni ìyàwó kejì ọkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní àkókò ikú rẹ̀, òun ni ìyàwó àgbà.[4]

Wọ́n pa á ní ọjọ́ kẹriin Oṣù Kẹfà, ọdún 1996, nígbà tí ìjọba Nàìjíríà fi ọkọ rẹ̀ sí àtìmọ́lé. Ọkọ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ènìyàn gbàgbọ́ pé ó ṣẹ́gun nínú ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà ti ọdún 1993, ṣùgbọ́n ìjọba ológun Ibrahim Babangida fagilé ìdìbò náà, lẹ́yìn náà ni wọ́n sì fi í sí àtìmọ́lé. Ìpànìyàn Kúdíràtù di ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn tó fa ìwádìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àkọọlẹ̀, àwọn ọkùnrin mẹ́fà ló ṣe ìpànìyàn náà. Kúdíràtù kú lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. Awakọ̀ rẹ̀ náà kú, ṣùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn apànìyàn náà, wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà láìfarapa.[5][4]

Ọkọ rẹ̀ ṣì wà ní àtìmọ́lé láìsí ẹ̀sùn lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ó kú ní ipò tí ó fa ọ̀pọ̀ ìbéèrè ní ọjọ́ keje Oṣù Keje, ọdún 1998, kété ṣáájú ìtúsílẹ̀ rẹ̀.[5][5] [4]

  1. ↑ "The Story of Kudirat Abiola". Archived from the original on 2009-09-26. Retrieved 2009-10-05.
  2. ↑ Obituary: Kudirat Abiola
  3. ↑ "Kudirat Abiola, Politicians, Entreprenuer, Prominent Nigerian, Nigeria Personality Profiles". Nigeriagalleria. 1996-06-09. Retrieved 2022-05-19.
  4. 1 2 3 The Brutal Assassination of Kudirat Abiola: Here Is The Complete Story, 20 January 2016, Daily Mail (Nigeria), Retrieved 7 February 2016
  5. 1 2 3 Moshood K.O. Abiola: From Wealth to Troubled Politics to Flawed Symbol, Michael T. Kaufman, New York Times, July 8, 1998