Mabel Oboh
Mabel Akomu Oboh | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹrin 1964 Edo State, Nigeria |
Iṣẹ́ | Broadcaster, Journalist, Actress, Producer, Director |
Olólùfẹ́ | Michael Ini Udoh |
Mabel Akomu Oboh tí a mọ̀ sí Mabel Oboh tí wọ́n bí ní 18 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1964 jẹ́ òṣèrébìnnrin, atọ́kùn ètò orí tẹlifíṣọ̀nù àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ Mabel Oboh Centre for Save our Stars (MOCSOS). Ó jẹ́ àkọ́kọ́ ẹni tí yóó dánìkan gbé eré tẹlifíṣọ̀nù jáde pẹ̀lú eré rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Victims, tí ó jẹ́ gbígbé jáde lóri ìkànnì Nigerian Television Authority (NTA).[1][2][3][4][5][6]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mabel wá láti Ìpínlẹ̀ Ẹdó ṣùgbọ́n ìlú Èkó ni àwọn òbí rẹ̀ bi sí. Ó gboyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ nípa òràn dídá láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Buckinghamshire New University.
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mabel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ lágbo eré ìdárayá ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980. Ó jẹ́ ẹ̀kejì obìnrin tí yóó kọ́kọ́ dánìkan ṣe adarí eré àti olùgbéréjáde pẹ̀lú ṣíṣe eré rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Victims. Ní ọdún 2000, ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí. yóó gbàlejò lóri ètò tẹlifiṣọ̀nù pẹ̀lú ètọ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Chat with Mabel" tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì NTA.[7][8][9][10]
Ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ NTA ní àwọn ọdún 1990 gẹ́gẹ́ bi olùgbéròyìn ṣááju kí ó tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Aajọ Agbaye. Lẹ́hìn náà ni ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ aṣojú Britani ní orílẹ̀-èdè Pólàndì.[11][12]
Òṣèlú ṣíṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lọ́wọ́lọ́wọ́, Mabel jẹ́ alágbàsọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress (ADC).[13][14][15][16]
Ó gbégbá ìbò ní ọdún 2020 fún ti ètò ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ẹdó.
Mocsos
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ Mabel Oboh Centre for Save our Stars (MOCSOS), léte láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìlera àwọn òṣèré Nàìjíríà.[17][18][19][20]
Ọ̀rọ̀ ayé ara rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ti bí àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta, orúkọ ọkọ rẹ̀ náà sì ń ṣe Michael Ini Udoh.[21]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "mabel oboh set to remarry". vanguardngr.com. 2019-05-10.
- ↑ "men were my greatest headache as broadcaster". sunnewsonline.com. 2019-05-25.
- ↑ "ex-boxing champion peter oboh thumbs up for actress sister". vanguardngr.com. 2020-03-25.
- ↑ "sisters launch saveourstars campaign". tribuneonlineng.com. 2017-03-20.
- ↑ "Nigeria reggae star undergoing surgery cries for help". premiumtimesng.com. 2016-03-20.
- ↑ https://www.vanguardngr.com/2017/09/27-years-afterveteran-actress-mabel-oboh-plans-return-nollywood
- ↑ "men were my greatest headache as broadcaster". sunnewsonline.com. 2019-05-25.
- ↑ "mabel oboh honoured ajegunle". thenationonlineng.net. 2018-03-25.
- ↑ "how i found love again". sunnewsonline.com. 2020-03-20.
- ↑ "history of Nigeria broadcasting production". journals.sagepub.com. 2004-01-20.
- ↑ "actress mabel oboh condoles Ben Bruce over wife death". sunnewsonline.com. 2020-03-20.
- ↑ "My father had unconditional love for my mother". thepointng.com. 2016-03-20.
- ↑ "ADC fault lasgs acceptance of China donation". independent.ng. 2020-04-20.
- ↑ "Edo ADC chair Chris ineghedion wins party DNA award". sunnewsonline.com. 2019-03-20.
- ↑ "Mabel oboh joins politics becomes AFC spokesperson". aljazirahnews.com. 2020-04-20. Archived from the original on 2021-04-27. Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "Day actress mabel oboh meet obasanjo". sunnewsonline.com. 2020-03-20.
- ↑ "reggae star yellow banton bounces back after cancer scare". punchng.com. 2020-03-20.
- ↑ "sisters on a mission to save failing entertainers". m.guardian.ng. 2017-01-20.
- ↑ "saves sadiq Daba project". vanguardngr.com. 2018-03-20.
- ↑ "Ex NTA staff sadia daba recuperating". nationalinsightnews.com. 2020-03-20.
- ↑ "mabel oboh married Michael udoh". sunnewsonline.com. 2020-03-20. Archived from the original on 2021-02-26. Retrieved 2020-11-21.