Jump to content

Mahmud Hasan Deobandi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Shaykh al-Hind, Mawlānā

Mahmud Hasan Deobandi
3rd Principal of Darul Uloom Deoband
In office
1890–1915
AsíwájúSyed Ahmad Dehlavi
Arọ́pòAnwar Shah Kashmiri
2nd President of Jamiat Ulema-e-Hind
In office
November 1920 – 30 November 1920
AsíwájúKifayatullah Dehlawi
Arọ́pòKifayatullah Dehlawi
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1851
Bareilly, Company rule in India
Aláìsí1920
Delhi, British India
Resting placeMazar-e-Qasmi
Alma materDarul Uloom Deoband

Mahmud Hasan Deobandi (tí a tún mọ̀ sí Shaykh al-Hind; 1851–1920) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí India àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ Ìrìn Òmìnira India, tí ó pẹ̀lú dá Yunifásítì Jamia Millia Islamia sílẹ̀ àti dá Silk Letter Movement fún òmìnira India. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Darul Uloom Deoband. Àwọn olùkọ́ rẹ̀ jẹ́ Muhammad Qasim Nanautawi àti Mahmud Deobandi, ó sì ní àṣẹ nínú Sufism nípa Imdadullah Muhajir Makki àti Rashid Ahmad Gangohi[1].

Hasan ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ àgbà Darul Uloom Deoband, ó sì ṣẹ̀dàá àwọn ẹgbẹ́ bí i Jamiatul Ansar àti Nizaratul Maarif. Ó kọ ìtumọ̀ Kùránì ní Urdu, ó sì kọ àwọn ìwé ìwé bí i Adilla-e-Kāmilah, Īzah al-adillah, Ahsan al-Qirā àti Al-Jahd al-Muqill. Ó kọ́ hadith ní Darul Uloom Deoband àti ṣe àtúnṣe ẹ̀dà Sunan Abu Dawud[2]. Lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbòógì ni Ashraf Ali Thanwi, Anwar Shah Kashmiri, Hussain Ahmad Madani, Kifayatullah Dehlawi, Sanaullah Amritsari àti Ubaidullah Sindhi.

Hasan jẹ́ olódì British Raj paraku. Ó bẹ̀rẹ̀ àwọn ìrìn láti borí agbára wọn ní India ṣùgbọ́n wọ́n mú u ní 1916, wọ́n sì tì í mọ́lé ní Malta[3]. Wọ́n tú u sílẹ̀ ní 1920, wọ́n sì fi oyè "Shaykh al-Hind" fún un (The Leader of India) láti ọwọ́ Khilafat committee. Ó kọ àwọn edicts ẹ̀sìn ní àtìlẹ́yìn Non-cooperation movement, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí oríṣìíríṣìí apá ilẹ̀ India, láti gba àwọn Mùsùlùmí sí inú ìrìn òmìnira[4]. Ó jẹ́ aṣáájú lórí ìpàdé gbogboogbò kejì ti Jamiat Ulema-e-Hind ní oṣù kọkànlá 1920, wọ́n sì yàn án ní Ààrẹ. Wọ́n sọ orúkọ Shaikh-Ul-Hind Maulana Mahmood Hasan Medical College ní ìrántí r rẹ̀. Ní 2013, ìjọba India fi commemorative postal stamp lórí lẹ́tà ìrìn sílíìkìì rẹ̀ léde.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Mahmud Hasan ní 1851 ní ìlú Bareilly (ní Uttar Pradesh òde-òní, India) sínú ìdílé Usmani Deoband.[5][6] Bàbá rẹ̀, Zulfiqar Ali Deobandi, tí wọ́n jọ dá Darul Uloom Deoband, jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Bareilly College, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i igbákejì aṣàyẹ̀wò madrasas.[5][7]

Hasan kẹ́kọ̀ọ́ kùránì pẹ̀lú Miyanji Manglori, àti Persian pẹ̀lú Abdul Lateef.[5] Láàárín 1857 rebellion, wọ́n gbé bàbá rẹ̀ lọ sí Meerut, wọ́n sì ṣí Hasan lọ Deoband, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lítíréṣọ̀ Persian àti Arabic láti kọ́ọ̀sì Dars-e-Nizami pẹ̀lú ọ́ńkù rẹ̀, Mehtab Ali.[5] Ó di akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ ní Darul Uloom Deoband;[8] ó sì kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Mahmud Deobandi.[9] Ó káàdì ẹ̀kọ́ àìgbẹ̀fẹ̀ rẹ̀ ní 1869, ó sì lọ sí Meerut láti kẹ́kọ̀ọ́ Sihah Sittah pẹ̀lú Muhammad Qasim Nanautawi.[10] Ó lọ àwọn àpérò hadith Nanautawi fún ọdún méjì, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ lítíréṣọ̀ Arabic pẹ̀lú bàbá rẹ̀ ní àwọn àkókò ìsinmi .[11] Ó kẹ́kọ̀ọ́jáde ní 1872, ó sì gba ìwérí iyì ní 1873 ní ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àkọ́kọ́ Darul Uloom Deoband.[12][13] Ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Imdadullah Muhajir Makki àti Rashid Ahmad Gangohi nínú Sufism.[14]

Wọ́n yan Hasan gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ ní Darul Uloom Deoband ní 1873, ọdún kan náà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀.[6] Ó di ọ̀gá olùkọ́ ní 1890.[13][15][16] Kò ro ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Deoband gẹ́gẹ́ bí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ibi tí wọ́n dásílẹ̀ fún dídí ìpàdánù 1857 rebellion.[8]

A view of Darul Uloom Deoband

Hasan dá Thamratut-Tarbiyat (The Fruit of the Upbringing) sílẹ̀ ní 1878.[17] Wọ́n dá a sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ibi ọpọlọ láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde Darul Uloom Deoband.[18] Ó wá gba ìrísí Jamiatul Ansar (Àwùjọ àwọn Olùrànlọ́wọ́), tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1909 pẹ̀lú ìpàdé rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó wáyé ní MoradabadAhmad Hasan Amrohi sì darí.[19] Lẹ́gbẹ̀ẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ Ubaidullah Sindhi, Hasan bẹ̀rẹ̀ Nizaratul Ma'arif al-Qur'ānia (Ilé-ẹ̀kọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Kùránì) ní oṣù kọkànlá 1913.[19][20] Ó gbìyànjú láti ṣe àfikún agbára àwọn onímọ̀ Mùsùlùmí lórí àti láti ṣe ìsọfúnni àti kọ àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa Ìsìláàmù.[21] Hussain Ahmad Madani gbèrò pé "ìdí tí ó wà lẹ́yìn ìdásílẹ̀ Nizaratul Maarif ni láti jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ Mùsùlùmí di onígbàgbọ́ tí ó rinlẹ̀, àti láti kìlọ̀ àti láti tọ́ wọn sọ́nà, pàápàá àwọn Mùsùlùmí tí ó kàwé nílànà àwọn Òyìnbó, ní àwọn ẹ̀kọ́ inú Kùránì ní ọ̀nà tó mọ́pọlọ dání tí yóò yọ ipa májèlé tí àwọn ìsọkiri tí ó lòdì sí ti Ìsìláàmù àti àwọn iyèméjì tí wọ́n rí ní ọ̀nà àìtọ́ nípa ìṣe ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà Ìsìláàmù ní ayé òde-òní."[22][23]

Ìrìn Lẹ́tà Sílíìkì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Hasan fẹ́ gba agbára lọ́wọ́ British Raj ní India; láti ṣe èyí, ó tẹjúmọ́ agbègbè ilẹ̀ méjì.[24] Àkọ́kọ́ ni agbègbè àwọn ẹ̀yà tí ó dá dúró tí wọ́n ń gbé láàárín Afghanistan àti India.[24] Asir Adrawi sọ, "èyí ni ìbáyému onítàn pé àwọn ènìyàn tí wọ́n rọ́ wá India gba ọ̀nà náà, àti yíyàn tí Hasan yan agbègbè yìí fún ìrìn rẹ̀ jẹ́ dájúdájú ẹ̀rí tí ó ga jù nípa ìwọ̀túnwòsí rẹ̀ àti àfojúsùn."[25] Agbègbè kejì wà láàárín India; ó fẹ́ nípá lórí àwọn adarí olóòótọ́ tí wọ́n bìkítà fún àwùjọ láti ṣe àtìlẹ́yìn fún èròǹgbà rẹ̀, àti nínú èyí ó ṣe àṣeyọrí díẹ̀.[25] Lára àwọn onímọ̀ tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní ipele àkọ́kọ́ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti àwọn ẹnìkejì bí i Abdul Ghaffar Khan, Abdur-Raheem Sindhi, Muhammad Mian Mansoor Ansari, Ubaidullah Sindhi àti Uzair Gul Peshawari.[26] Wọ́n ṣe ìgbédìde ètò Hasan sínú àwọn agbègbè iwájú àti àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà tí ó dá dúró.[27] Àwọn onímọ̀ tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ipele kejì jẹ́ Mukhtar Ahmad Ansari, Abdur-Raheem Raipuri àti Ahmadullah Panipati.[28] Muhammad Miyan Deobandi sọ, "Shaikhul Hind máa ń rọra wo àwọn ìwà àti agbára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n wá bá a. Ó yan àwọn ènìyàn kan láàárín wọn ó sì pàṣẹ fún wọn láti dé Yaghistan àti mú àwọn ẹ̀yà tí ó dá dúró náà kógun ja India."[29] Ètò tí wọ́n ṣe láti gbaradì fún àwọn ara inú India fún ìlòdìsí tí àwọn ìjọba Afghani àti Turkish bá pèsè ohun ogun fún àwọn ológun àti àwọn ènìyàn láàárín India dìde fún ìlòdìsí nígbà ìkọlù àwọn ológun yìí.[27] Yaghistan jẹ́ àárín ìrìn Mahmud Hasan.[30] Akẹ́kọ̀ọ́ Hasan Ubaidullah Sindhi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ṣe ètò Provisional Government of India , wọ́n sì yan Mahendra Pratap gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.[31]

Hasan fúnra rẹ̀ rin ìrìn-àjò lọ sí Hejaz láti gba àtìlẹ́yìn àwọn German àti Turkish ní 1915.[32] Ó kúrò ní Bombay ní ọjọ́ 18, oṣù kẹsàn-án 1915, àwọn tí wọ́n sì sìn ín ni àwọn onímọ̀ bí i Muhammad Mian Mansoor Ansari, Murtaza Hasan Chandpuri, Muhammad Sahool Bhagalpuri àti Uzair Gul Peshawari.[33][34] Ní ọjọ́ 18, oṣù kẹwàá 1915, ó lọ sí Mecca níbi tí ó ti ní àwọn ìpàdé pẹ̀lú Ghalib Pasha, gómìnà Turkish, àti Anwar Pasha, tí ó jẹ́ mínísítà ààbò Turkey.[35][36] Ghalib Pasha fun ní ìdánilójú lórí ìrànlọ́wọ́, ó sì fún un ní lẹ́tà mẹ́ta, ọ̀kan tí wọ́n kọ sí àwọn Mùsùlùmí India, èkejì sí gómìnà Busra Pasha, àti ìkẹta sí Anwar Pasha.[36] Hasan tún ní ìpàdé pẹ̀lú Djemal Pasha, gómìnà Syria, tí ó gbà pẹ̀lú ohun tí Ghalib Pasha ti sọ.[36] Hasan bẹ̀rù pé tí òun bá padà lọ India, àwọn Òyìnbó lè ti òun mọ́lé, ó sì bèrè kí wọ́n jẹ́ kí òun dé ibodè Afghanistan níbi tí òun ti lè dé Yaghistan.[37] Djemal wá nnkan sọ, ó sì sọ fún un pé tí ó bá ń bẹ̀rù àtìmọ́lé, ó lè dúró ní Hejaz àbí agbègbèkágbègbè Turkey mìíràn.[37] Ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, wọ́n lu awo ètò tí wọ́n pè ní Ìrìn Lẹ́tà Sílíìkì, wọ́n sì ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà mọ́lé.[38] Wọ́n mú Hasan ní oṣù Kejìlá 1916 pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Hussain Ahmad Madani àti Uzair Gul Peshawari, láti ọwọ́ Sharif Hussain, the Sharif of Mecca, tí wọ́n ṣe lòdì sí àwọn Turks tí wọ́n sì sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Òyìnbó.[39][32] Sharif náà wá fi wọ́n lé àwọn Òyìnbó lọ́wọ́,[40] wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé ní Fort Verdala ní Malta.[41]

Wọ́n tú Hasan sílẹ̀ ní oṣù karùn-ún 1920,[41] nígbà tí ó máa di ọjọ́ 8, oṣù kẹfà, 1920, ó ti dé Bombay.[42] Lára àwọn onímọ̀ ńlá àti olóṣèlú tí wọ́n kí i káàbọ̀ ni Abdul Bari Firangi Mahali, Hafiz Muhammad Ahmad, Kifayatullah Dehlawi, Shaukat Ali àti Mahatma Gandhi.[43] Wọ́n rí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbéga ńlá sí Ìrìn Khilafat [43] wọ́n sì fi oyè "Shaykh al-Hind" gbé iyì fún un (Olórí India) láti ọwọ́ àjọ Khilafat.[42]

Hasan jẹ́ ìwúrí fún àwọn onímọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Deoband láti dara pọ̀ mọ́ ìrìn Khilafat náà.[43] Ó ṣe òfin ẹ̀sìn láti yẹra fún àwọn ọjà Òyìnbó; tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Muhammadan Anglo-Oriental College máa ń ṣètò.[44] Nínú òfin rẹ̀, ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti yẹra fún ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún ìjọba lọ́nàkọnà, kí wọ́n yẹra fún àwọn ilé-ìwé àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí ìjọba ń kówó lé, kí wọ́n sì yẹra fún àwọn iṣẹ́ ìjọba.[45] Lẹ́yìn òfin rẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ náà.[46] Òfin yìí ṣe àtìlẹ́yìn Non-cooperation movement.[45] Hasan wá rin ìrìn-àjò lọ sí Allahabad, Fatehpur, Ghazipur, Faizabad, Lucknow àti Moradabad, ó sì tọ́ àwọn Mùsùlùmí sọ́nà ní àtìlẹ́yìn àwọn ìrìn náà.[47]

Jamia Millia Islamia

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ní kí Hasan darí ayẹyẹ ìpìlẹ̀ Jamia Millia Islamia, tí wọ́n mọ̀ sí National Muslim University ní àkókò náà.[48] Olùdásílẹ̀ Yunifásítì yìí ni Hasan pẹ̀lú Muhammad Ali Jauhar àti Hakim Ajmal Khan,[49] tí ìwúrí wọn jẹ́ àwọn ìbéèrè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Aligarh Muslim University (AMU) tí wọ́n ní ìjákulẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ iṣẹ́ àwọn Òyìnbó AMU, tí wọ́n sì fẹ́ Yunifásítì tuntun.[48][50] Àwọn ìránṣẹ́ Hasan, síbẹ̀síbẹ̀, gbà á níyànjú láti má gba ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yìí nítorí ó ti ń ní àìlera, ó sì ti ń rẹ̀ ẹ́ látàrí àsìkò rẹ̀ ní àtìmọ́lé ní Malta.[51][48] Hasan sọ, ní ìdáhùn sí àwọn ẹ̀rù wọn, "Tí jíjẹ Ààrẹ mi bá dùn àwọn Òyìnbó, nígbà náà ni màá kópa nínú ayẹyẹ yìí dájúdájú."[48] Wọ́n gbé e wá sí ibùdókọ̀ ọkọ ojú-irin ní Deoband nínú palanquin, láti ibi tí ó ti rin ìrìn-àjò lọ sí Aligarh.[48]

Hasan ò rí ohunkóhun kọ, ó sì rán akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ Shabbir Ahmad Usmani láti ṣètò ọ̀rọ̀ Ààrẹ rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni ó ṣe àwọn àtúnṣe àti àtúntò sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n pèsè sílẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ jáde. Ní ọjọ́ 29, oṣù kẹwàá 1920, Usmani sì ka ọ̀rọ̀ yìí síta ní ayẹyẹ ìfilélẹ̀ Yunifásítì náà,[52] lẹ́yìn tí Hasan fi òkuta ìpìlẹ̀ Jamia Millia Islamia lélẹ̀.[51] Hasan sọ nínú ọ̀rọ̀ náà pé "àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìmọ̀ láàárín yín mọ̀ dájú pé àwọn olórí àti aṣáájú mi ò pa àṣẹ àìgbàgbọ́ lórí kíkọ́ èdè àjèjì àbí níní ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì àwọn ìran mìíràn. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n sọ ọ́ pé ipa ìkẹyìn ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pé àwọn tí wọ́n ń wá a yálà máa ń kun ara wọn nínú ti Kìrìtẹ̀ẹ́nì àbí kí wọ́n yọ ẹ̀sìn wọn tàbí àwọn ìdàkejì ẹ̀sìn jálẹ̀ àfojúdi àìgbàgbọ́ wọn, àbí kí wọ́n sin ìjọba wọn lọ́wọ́lọ́wọ́; nígbà náà ó dára láti wà nípò àìmọ̀ kàkà kí ènìyàn lọ fún irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀."[53] Ó gbà pẹ̀lú Mahatma Gandhi tí ó sọ pé, "ẹ̀kọ́ gíga àwọn ilé-ẹ̀kọ́ yìí mọ́ bí i wàrà, ṣùgbọ́n tí wọ́n pò pọ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba májèlé díẹ̀" tí wọ́n sì kà sí Muslim National University, gẹ́gẹ́ bí i asẹ́ tí yóò ya májèlé yìí kúrò nínú ẹ̀kọ́.[53]

Hasan jẹ́ adarí lórí ìpàdé gbogboogbò kejì àwọn Jamiat Ulema-e-Hind, tí ó wáyé ní oṣù kọkànlá 1920 ní Delhi.[54] Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ àwọn Jamiat, ipò tí kò ti lè ṣiṣẹ́ nítorí ikú rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ [ní ọjọ́ 30 oṣù kọkànlá ].[55] Wọ́n ṣe ìpàdé gbogboogbò yìí fún ọjọ́ mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ 19, oṣù kọkànlá, àti akẹ́kọ̀ọ́ Hasan, Shabbir Ahmad Usmani sì ka ọ̀rọ̀ Ààrẹ rẹ̀ síta.[56] Hasan jà fún ìrẹ́pọ̀ Hindu-Muslim-Sikh, ó sì sọ pé, tí àwọn ẹlẹ́ṣin Hindu àti àwọn Mùsùlùmí bá sowọ́pọ̀, gbígba òmìnira ò lè le.[57][58] Àpérò ìkẹyìn tí Hasan lọ nìyìí.[58]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Hasan jẹ́ òǹkà ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún.[59] Lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gbòógì ni Anwar Shah Kashmiri, Asghar Hussain Deobandi, Ashraf Ali Thanwi, Husain Ahmad Madani, Izaz Ali Amrohi, Kifayatullah Dihlawi, Manazir Ahsan Gilani, Muhammad Mian Mansoor Ansari, Muhammad Shafi Deobandi, Sanaullah Amritsari, Shabbir Ahmad Usmani, Syed Fakhruddin Ahmad, Ubaidullah Sindhi àti Uzair Gul Peshawari.[13][60][61] Ebrahim Moosa sọ pé "àwọn ọ̀wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí ó dára padà di mímọ̀ nínú ẹ̀ka madrasa, wọ́n sì ṣe àfikún sí ìgbé ayé àwùjọ ní apá Gúúsù Asia ní àwọn pápá tí ó fẹjú bí i ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn, ìṣèlú àti kíkọ́ ilé-ẹ̀kọ́."[62]

Àwọn Iṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà ní àkọsílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣíṣe ìtumọ̀ Kùránì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Hasan kọ ìtumọ̀ Kùránì ní Urdu ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ti ìpìlẹ̀.[63] Lẹ́yìn náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àlàyé ìtumọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ àlàyé, bí ó ṣe jẹ́ ó ṣẹ̀ parí orí kẹrin An-Nisa, nígbà tí ó kú ní 1920.[64] Akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Shabbir Ahmad Usmani ni ó parí Iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ kíkún yìí, wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde gẹ́gẹ́ bí i Tafsir-e-Usmāni.[65] Lẹ́yìn èyí ní àwọn ọ̀wọ́ onímọ̀ kan tú u sí èdè Persia, Mohammed Zahir Shah ni ó gbé iṣẹ́ fún wọn, ọba tí ó jẹ kẹ́yìn ní Afghanistan.[66]

Al-Abwāb wa Al-Tarājim li al-Bukhāri

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Hasan jẹ́ olùkọ́ Sahih Bukhari ní Darul Uloom Deoband fún ìgbà pípẹ́ àti pé, nígbà tí ó wà ní ẹ̀wọ̀n ní Malta, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ iṣẹ́ tí ń ṣàlàyé àwọn àkọ́lé orí rẹ̀.[67] Nínú ẹ̀kọ́ hàdíítì, pípín àkọ́lé orí nínú àṣàyàn iṣẹ́ jẹ́ ohun tí wọ́n rí bí i sáyẹ́ǹsì tí ó yàtọ̀.[68] Hasan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú òfin aléélẹ̀ márùndínlógún lórí orí ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn náà ni ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣe láti inú orí náà lórí ìfihàn àti ṣiṣẹ́ lórí orí tí ó wà fún ìmọ̀ lábọ̀. Wọ́n sọ iṣẹ́ náà ní al-abwāb wa al-tarājim li al-Bukhāri,() ó sì jẹ́ ojú ewé 52.[67]

Bí ìrìn Ahl-i Hadith ṣe ń gbòòrò sí i ni India ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àṣẹ Hanafi school of thought.[69] Onímọ̀ Ahl-i Hadith Muhammad Hussain Batalvi ṣe àkójọpọ̀ ìbéèrè mẹ́wàá [70], ó sì ṣe ìkéde ìpè ìjà pẹ̀lú ẹ̀bùn fún àwọn tó bá ní ìdáhùn, pẹ̀lú rupees mẹ́wàá lórí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan. Wọ́n tẹ èyí jáde láti Amritsar, wọ́n sì fi ránṣẹ́ lọ sí Darul Uloom Deoband.[69] Ìṣe Deoband ni láti yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ náà tí ó ń pín àwùjọ Mùsùlùmí, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ahl-i Hadith fi ipá mú ọ̀rọ̀ náà. Bákan náà, Hasan, ní ìbéèrè olùkọ́ rẹ̀ Nanautawi,[71] ní ìdáhùn béèrè àwọn ìbéèrè kan ní ọ̀nà ìwé, Adilla-e-Kāmilah (), ní ìlérí pé, "tí ẹ bá dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyìí, a máa fún un yín ní ogún rupees lórí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan."[72]

Lẹ́yìn Adilla-e-Kāmilah Mahmud Hasan , onímọ̀ Ahl-i Hadith kan, Ahmad Hasan Amrohwi kọ Misbāh al-Adillah () ní ìdáhùn sí Adilla-e-Kāmilah.[71] Onímọ̀ Deobandi yìí dúró fún àkókò díẹ̀ fún ìdáhùn kankan láti ọ̀dọ̀ oníbèérè àkọ́kọ́ , Muhammad Hussain Batalwi,[73] tí ó kéde lẹ́yìn náà pé iṣẹ́ Amrohwi kún ojú òṣùwọ̀n, àti pé òun ní ti òun ti ko gbogbo èrò láti kọ àwọn ìbéèrè náà kúrò ní ọkàn.[73] Mahmud Hasan, ní ìdáhùn, kọ Izāh al-Adillah (); àsọyé lórí iṣẹ́ rẹ̀ ìṣáájú Adilla-e-Kāmilah.[73]

Hasan ti sọ̀rọ̀ lóri níní ìrun àdúrà ọjọ́-ẹtì ní àwọn abúlé àti ìletò nínú ìwé yìí.[74] Syed Nazeer Husain tí gbé ọ̀rọ̀ yìí dìde, ó sì ti ṣe àtẹ̀jáde àkọsílẹ̀ ẹ̀sìn tí ó sọ pé kò sí ìsọnípàtó ibikíbi [fún àwọn àdúrà ọjọ́ Etì]. Ó sọ pé, níbikíbi tí ó kéré jù ènìyàn méjì bá ti péjọ, àwọn àdúrà ọjọ́ Etì ti ṣe pàtàkì.[74] Amòfin àti onímọ̀ Hanafi, Rashid Ahmad Gangohi, kọ fatwa ó lé ní ojú ewé mẹ́rìnlá ní ìdáhùn, tí ó pè ní Awthaq al-'Urā () láti ojú ìwòye Hanafi school of thought.[74]

Iṣẹ́ Gangohi gba àtúpalẹ̀ lámèyítọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ Ahl-i Hadith; púpọ̀ èyí tí àbájáde wọ́n jẹ́ àwọn àríyànjiyàn kan náà.[74] Akẹ́kọ̀ọ́ Gangohi, Mahmud Hasan rò ó pé èdè inú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí jẹ́ ti àfojúdi, ó sì kọ ìwé tí ó gùn, tí wọ́n pè ní Ahsan al-Qirā fī Tawzīḥ Awthaq al-'Urā (), ní ìdáhùn.[75]

Shah Ismail Dehlvi àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí àtúntò àwọn Mùsùlùmí láti Bidʻah (àwọn àrà ẹ̀sìn tuntun), gba ìbẹnu-àtẹ́-lù ńlá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn àrà tuntun wọ̀nyìí.[76] Wọ́n fi ẹ̀sùn ìsọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀sìn Dehlvi, wọ́n sì yọ ọ́ kúrò nínú Ìsìláàmù.[76] Bákan náà, onímọ̀ Ìsìláàmù Ahmad Hasan Kanpuri, kọ Tanzih al-Raḥmān (), inú èyí tí ó ti dárúkọ Dehlvi láti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbẹ́sìnlérí Muʿtazila.[77] Mahmud Hasan, ní ìdáhùn, kọ Al-Jahd al-Muqill fī Tanzīhi al-Mu'izzi wa al-muzill (), ní ìpele méjì.[78] Ìwé náà sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwọn ìṣesí àti àbùdá Allah pẹ̀lú àwọn kókó ọ̀rọ̀ Ilm al-Kalam, ní títẹ̀lé ìsọ̀rọ̀sí àsọyé Al-Taftazani, Sharah Aqā'id-e-Nasafi, lórí ìgbàgbọ́ al-Nasafi.[77] Hasan ti dáhùn sí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Shah Ismail Dehlvi àti àwọn onímọ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú lílo Ilm al-Kalam.[78]

Wọ́n ṣe ìpamọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó wà ní àkọsílẹ̀ ní yàrá ìkàwé ìran Ìsìláàmù, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹ̀ tí wọ́n dìmú ní Mecca àti Medina.[79] Onímọ̀ India, Ahmad Ali Saharanpuri ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà tí ó wà ní Mecca, ó sì kà wọ́n lẹ́yìn náà pẹ̀lú Shah Muhammad Ishaq. Nígbà tí ó padà sí India, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtẹ̀jáde àwọn ẹ̀dá àtúnṣe àtẹ̀jáde àfọwọ́kọ àwọn hadith wọ̀nyìí láti ilé iṣẹ́ atẹ̀wé rẹ̀.[80] Akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ Muhammad Qasim Nanautawi tẹ̀síwájú lórí ìṣe ṣíṣe ẹ̀dá àwọn ìwé àfọwọ́kọ hàdíítì títí tí gbogbo ìwé náà fi di títẹ̀jáde ní India.[79]

Lẹ́yìn náà, ìdí wà láti ṣe àtúnṣe ẹ̀dà Sunan Abu Dawud, ọ̀kan lára àwọn ìwé mẹ́fà pàtàkì jùlọ hadith. Àmọ́ ṣá, àwọn àtúnṣe tí wọ́n tẹ̀ jáde àti àkọsílẹ̀ ìwé àfọwọ́kọ tó ṣáájú yàtọ̀ gedegbe sí ara wọn .[79] Hasan, fún ìdí yìí gba gbogbo ìwé àfọwọ́kọ tí ó wà nílẹ̀, ó ṣe àtúnṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà, ó sì ṣe àtẹ̀jáde àtúnṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ọ̀nà ìwé. Àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n tẹ̀ jáde ní 1900 láti ilé-iṣẹ́ atẹ̀wé Mujtabai ní Delhi.[81]

Ikú àti Ẹ̀yin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
The Maulana Mahmud Hasan gate of Jamia Millia Islamia.

Ní ọjọ́ 30, oṣù kẹwàá 1920, ọjọ́ kan lẹ́yìn ìpìlẹ̀ Jamia Millia Islamia ní Aligarh, Hasan rin ìrìn àjò lọ sí Delhi ní ìbéèrè Mukhtar Ahmad Ansari. Ọjọ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, ìlera rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dínkù, ó sì gba ìtọ́jú láti ọwọ́ Ansari ní ilé rẹ̀ ní Daryaganj.[82][83] Ó kú ní ọjọ́ 30, oṣù kọkànlá, 1920 ní Delhi.[84] Bí wọ́n ṣe kéde ìròyìn ikú rẹ̀, àwọn Hindu àti àwọn Mùsùlùmí ti àwọn ilé ìtajà wọn, wọ́n sì péjọ síta ilé Ansari láti ṣe ìjúbà sí Hasan.[85] Ansari wá béèrè lọ́wọ́ arákùnrin Hasan, Hakeem Muhammad Hasan tí ó bá fẹ́ kí wọ́n sin Mahmud Hasan sí Delhi pẹ̀lú ìpèsè ètò sí ilẹ̀ ìsìnkú Mehdiyan, tàbí tí ó bá fẹ́ láti sin ín sí Deoband pẹ̀lú ìpèsè ètò fún gbígbé òkú náà lọ.[84] Wọ́n pinnu láti sin ín sí Deoband nítorí ìfẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n sin ín sí ìtòsí sàárè olùkọ́ rẹ̀ Muhammad Qasim Nanautawi.[86] Wọ́n gba àwọn àdúrà ìsìnkú rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Àwọn ará Delhi ṣe àwọn àdúrà náà ní ìta ilé Ansari, àti lẹ́yìn náà wọ́n gbé òkú náà lọ sí Deoband. Bí wọ́n ṣe dé ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú-irin Delhi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ, wọ́n sì ṣe àdúrà ìsìnkú. Bákan náà, wọ́n ṣe àdúrà ní ibùdókọ̀ ọkọ ojú-irin Meerut àti ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú-irin Meerut Cantt .[86] Àdúrà ìsìnkú rẹ̀ karùn-ún àti ìkẹyìn ni àbúrò rẹ̀ Hakeem Muhammad Hasan darí, wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìsìnkú Qasmi.[86]

Mahmud Hasan ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yẹ. Ashraf Ali Thanwi pè é ní "Shaykh al'-'Ālam" (Olórí ayé).[87] Thanwi sọ pé , "Ní òye tiwa, òun ni olórí India, Sindh, àwọn Arab àti àwọn Ajam".[87] Wọ́n sọ ilé-ẹ̀kọ́ ìwòsàn ní Saharanpur ní Shaikh-Ul-Hind Maulana Mahmood Hasan Medical College lẹ́yìn rẹ̀.[88] Ní oṣù kìíní 2013, Ààrẹ India, Pranab Mukherjee ṣe àgbéjáde ontẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ lórí Silk Letter Movement Hassan ní ìrántí .[89]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Mahotsav, Amrit (2023-08-07). "Mahmud Hasan Deobandi". Azadi Ka Amrit Mahotsav, Ministry of Culture, Government of India. Retrieved 2023-09-20. 
  2. Accelerator, Academic (2023-09-20). "Mahmud Hasan Deobandi: Most Up-to-Date Encyclopedia, News & Reviews". Academic Accelerator. Retrieved 2023-09-20. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. Mohammed, Abu (2010-10-26). "Hazrat Shaykhul-Hind (Maulana) Mahmoodul-Hasan Deobandi (RA)". Muftisays Islamic Portal. Retrieved 2023-09-20. 
  4. "Shaikhul-Hind Mahmood Hasan: symbol of freedom struggle". The Milli Gazette — Indian Muslims Leading News Source. 2016-02-12. Retrieved 2023-09-20. 
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 Adrawi 2012, p. 45.
  6. 6.0 6.1 Tayyab 1990, p. 18.
  7. Rizwi 1980, pp. 93–94.
  8. 8.0 8.1 Salam & Parvaiz 2020, pp. 48–49.
  9. Adrawi 2012, p. 46.
  10. Adrawi 2012, p. 47.
  11. Adrawi 2012, p. 48.
  12. Adrawi 2012, p. 49.
  13. 13.0 13.1 13.2 Rizwi 1981, p. 20.
  14. Adrawi 2012, p. 68.
  15. Tayyab 1990, p. 20.
  16. Adrawi 2012, p. 72.
  17. Deobandi, p. 79.
  18. Hasan, Nayab (1 December 2017). "حضرت شیخ الہند کا تصورِ فلاحِ امت" (in ur). Millat Times. https://urdu.millattimes.com/archives/21672. 
  19. 19.0 19.1 Salam & Parvaiz 2020, p. 134.
  20. Deobandi 2013, p. 295.
  21. Khimjee 1999, p. 92.
  22. Salam & Parvaiz 2020, pp. 134–135.
  23. Deobandi 2002, p. 45.
  24. 24.0 24.1 Adrawi 2012, p. 167.
  25. 25.0 25.1 Adrawi 2012, p. 168.
  26. Adrawi 2012, pp. 169–184.
  27. 27.0 27.1 Adrawi 2012, p. 185.
  28. Adrawi 2012, p. 186.
  29. Deobandi 2013, p. 57.
  30. Tabassum 2006, p. 47.
  31. Rizwi 1981, pp. 137–138.
  32. 32.0 32.1 Trivedi 1982, p. 659.
  33. Deobandi 2002, p. 56.
  34. Tayyab 1990, p. 49.
  35. Deobandi 2002, p. 58.
  36. 36.0 36.1 36.2 Deobandi 2013, pp. 59–60.
  37. 37.0 37.1 Deobandi 2013, p. 59-60.
  38. Adrawi 2012, p. 184.
  39. Wasti 2006, p. 715.
  40. Deobandi 2013, p. 61.
  41. 41.0 41.1 Nakhuda, Ismaeel. "Where were Indian Muslim scholars interned in Malta?". Basair. Retrieved 30 July 2021. 
  42. 42.0 42.1 Tayyab 1990, p. 76.
  43. 43.0 43.1 43.2 Khimjee 1999, p. 144.
  44. Adrawi 2012, p. 287.
  45. 45.0 45.1 Adrawi 2012, p. 290.
  46. Tayyab 1990, p. 79.
  47. Tayyab 1990, p. 77.
  48. 48.0 48.1 48.2 48.3 48.4 Deobandi, p. 144.
  49. Basheer, Intifada P. (29 October 2020). "Jamia Millia Islamia: A University That Celebrates Diversity". Outlook India. https://www.outlookindia.com/website/story/india-news-jamia-millia-islamia-a-university-that-celebrates-diversity/363184. 
  50. "Shaikhul-Hind Mahmood Hasan: symbol of freedom struggle". Milli Gazette. 12 February 2016. https://www.milligazette.com/news/13779-shaikhul-hind-mahmood-hasan-symbol-of-freedom-struggle/. 
  51. 51.0 51.1 Nizami 2011, p. 29.
  52. Adrawi 2012, p. 291.
  53. 53.0 53.1 Nizami 2011, p. 33.
  54. Wasif Dehlavi 1970, p. 56.
  55. Wasif Dehlavi 1970, p. 74.
  56. Adrawi 2012, p. 295.
  57. Adrawi 2012, p. 308.
  58. 58.0 58.1 Nizami 2018, p. 132.
  59. Qasmi 1999, p. 64.
  60. Adrawi 2016, p. 233.
  61. Rehman 1967, pp. 217–218.
  62. Moosa 2015, p. 72.
  63. "The Translations of the Quran". The Islamic Quarterly (London: Islamic Cultural Centre) 40–41: 228. 1996. https://books.google.com/books?id=VhVWAAAAYAAJ&q=shaykh+al-hind+interlinear. 
  64. Adrawi 2012, pp. 335–336.
  65. Haqqani 2006, p. 268.
  66. Zaman 2018, p. 292.
  67. 67.0 67.1 Adrawi 2012, p. 336.
  68. "Shaykh (Maulana) Muhammad Zakariyya Kandhlawi". Central Mosque. Archived from the original on 2021-05-19. Retrieved 2022-07-30. Assigning chapter headings in a hadith collection is a science in itself, known among the scholars as al-abwab wa 'l-tarajim [chapters and explanations]. 
  69. 69.0 69.1 Adrawi 2012, p. 338.
  70. Adrawi 2012, p. 344.
  71. 71.0 71.1 Adrawi 2012, p. 351.
  72. Adrawi 2012, p. 339.
  73. 73.0 73.1 73.2 Adrawi 2012, p. 352.
  74. 74.0 74.1 74.2 74.3 Adrawi 2012, p. 345.
  75. Adrawi 2012, p. 346.
  76. 76.0 76.1 Adrawi 2012, p. 347.
  77. 77.0 77.1 Adrawi 2012, p. 348.
  78. 78.0 78.1 Adrawi 2012, p. 349.
  79. 79.0 79.1 79.2 Adrawi 2012, p. 369.
  80. Adrawi 2016, pp. 22–23.
  81. Adrawi 2012, p. 370.
  82. Saad Shuja'abadi 2015, p. 24-25.
  83. Adrawi 2012, p. 309.
  84. 84.0 84.1 Adrawi 2012, pp. 310–311.
  85. Saad Shuja'abadi 2015, p. 26.
  86. 86.0 86.1 86.2 Adrawi 2012, pp. 310–312.
  87. 87.0 87.1 Thanwi, Ashraf Ali. Usmani, Mahmood Ashraf. ed (in ur). Malfūzāt Hakīm al-Ummat. 5. Multan: Idāra Tālīfāt-e-Ashrafia. p. 300. https://archive.org/details/Malfoozat-e-Hakeem-ul-Ummatr.a-Volumes1To12-ShaykhAshrafAli/Malfoozat-e-Hakeem-ul-Ummatr.a-Volume5-ShaykhAshrafAliThanvir.a. 
  88. "Saharanpur medical college to be named after Madni". Times of India. 24 November 2013. https://timesofindia.indiatimes.com/city/lucknow/Saharanpur-medical-college-to-be-named-after-Madni/articleshow/26286915.cms. 
  89. "Prez releases special stamp on 'Silk Letter Movement'". Business Standard. 29 January 2013. https://www.business-standard.com/article/pti-stories/prez-releases-special-stamp-on-silk-letter-movement-113011100608_1.html. 

Àwọn ìwé ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Tí a bá fẹ́ kà sí i

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]