Mary Lazarus
Mary Lazarus | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Mary Lazarus 5 Oṣù Kàrún 1989 Abia State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2002–Present |
Màríà Lásárù (tí a bí ní ọjọ́ karùn ún oṣù karùn ún ọdún 1989)[1] jẹ́ òṣèré àti ò ǹṣe fiimu ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó gba àmì ẹ̀yẹe lórí fiimu àwọn ènìyàn ìlú fún òṣèré tí ó ní ìlérí tí ó dára jùlọ ní ibi ẹ̀buǹ eré ìdárayá ti i àwọn ènìyàn ìlú (City People Entertainment Awards) ti odun 2018[2], wọ́n sì tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i òṣèré tí ó dára jùlọ nínú ipa olùdarí ní ọdún kanná àn níbi ayẹyẹ ẹ̀bùn fún àwọn òṣèré Nollywood tí ó dára jùlọ (Best of Nollywood Awards).[3]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ àti ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lásárù wá làti Ìpínlẹ Abia ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ Abia wà ní agbègbè gúúsù ìla oorun ti oríl̀ẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó jẹ wípé àwọn ẹ̀yà Ìgbò ni wọ́n wà níbẹ̀. Ukwa tí ó wà ní Ìjọba Ìbílẹ̀ ìla-oorun ní Ìpínlẹ̀ Abia gangan ni Lásárù ti wá. Ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án ni a bí Lásárù sí èyí tí ìyá, bàbá pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ wa. Ó jẹ́ ìbejì nínú ẹbí yi àti wípé òun àti èkejì rẹ, Joseph tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n bí gbẹ̀yìn.[4] Nígbà tí Lásárù ti lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama tí ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí moyege ní pàtàkì ti girama (West African Senior School Certificate), ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Ìbàdàn (University of Ibadan) níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìwé ẹ̀rí tí ó múnádóko lórí i Àlà-ilẹ̀ (Geography).[5][6]
Iṣẹ́ rẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lásárù tí ó jẹ́ olókìkí jùlọ nínú àwọn ipa tí ó ti kó nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fiimu ti Nollywood, ó ṣe ìṣàfihàn akọ́kọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ní ọdún 2002 kí ó tó wa darí lọ sí ilé-iṣẹ́ fiimu ti Nàìjíríà ní ọdún 2009 pẹ̀lú fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Waiting Years". Lásárù rí ipa kan kó nínú fiimu yi látipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Gbenro Ajibade ẹni tí ó ṣàfihàn rẹ sí John Njamah, ẹni tí í ṣe olúdarí fiimu yi tí ó sì tún wá fún un ní ipa tí yíò kó nígbẹ̀yìn nínú fiimu tí a ti dárúkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lásárù darí ìṣàfihàn fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Dance To My Beat", èyí tí ó tún gbé jáde ní ọdún 2017.
Lásárù gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ti fi arahàn nínú oríṣiríṣi àwọn ìkéde ti ilé-iṣẹ́ Airtel àti MTN ti ṣe.
Àwòkọ́ṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn Vanguard, Lásárù dárúkọ ọmọtọla Jalade Ekeinde àti Jọkẹ Silva tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà òṣèré Nollywood gẹ́gẹ́ bí i àwọn tí òún ń wò kọ́ ìṣe wọn nínú iṣẹ́ fiimu ní Nàìjíríà. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míràn àn pẹ̀lú àwọn oníròyìn ìwé ìròyìn The Punch, Lásárù dárúkọ òṣèré bìnrin ọmọ ilé Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kimberly Elise gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn tí òún fẹ́ràn nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó ti gbòòrò.[7]
Àmì Ẹ̀yẹ àti yíyàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Lásárù gba àmì ẹ̀yẹ lórí i fiimu ti àwọn ènìyàn ìlú fún òṣer̀é tí ó ní ìlérí tí ó dára jùlọ èyí tí ó wáyé ní City People Entertainment Award ti ọdún 2018.[8]
- A yan Lásárù gẹ́gẹ́ bí i òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa ti olùdarí, èyí tí ó wáyé níbi àwọn ẹ̀bùn ẹ̀yẹ ti BON ní ọdún 2018.
- Wọ́n yan Lásárù níbi ayẹyẹ ti 2020 Africa Magic viewer's choice award gẹ́gẹ́ bí i alátìlẹyìn òṣèré tí ó dára jùlọ lórí oríṣiríṣi ipa kíkó nínú un fiimu tàbí tẹlifísànù fún fiimu ti "Size 12".[9]
Ìgbésí ayé rẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lásárù wá láti ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án. Ìbejì ni Lásárù. Òun àti ìkejì rẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n jẹ́ àbígbẹ̀yìn ìya wọn. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn The Punch, ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ẹnìkan tí ó fẹ́ràn ìgbádùn.
Àwọn àṣàyàn fiimu àti eré oríṣiríṣi lórí tẹlifísànù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- When Life Happens (2020) as Cindy | with Lota Chukwu, Jimmy Odukoya, Wole Ojo
- My Woman (2019) as Zara | with Seun Akinyele, Ujams C'briel
- Accidental Affair (2019) as Kristen
- Clustered Colours (2019)
- Broken Pieces (2018)
- Homely: What Men Want (2018) as Keji
- Dance To My Beat (2017)
- The Road Not Taken II (2017)
- Love Lost (2017) as Rena
- Girls Are Not Smiling(2016)
- What Makes You Tick (2016) as Ann Okojie
- Okafor’s Law (2016) as Kamsi
- Better Than The Beginning (2015)
- Bad Drop (2015)
- Losing Control (2015) as Uche
- Second Chances (2014) as Justina
- Desperate Housegirls (2013)
- Waiting Years (2009)
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Izuzu, Chibumga (2016-05-05). "5 Nollywood movies featuring actress". Pulse Nigeria. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ "Winners Emerge @ 2018 City People Movie Awards". City People Magazine. 2018-09-24. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ "BON Awards 2018: Mercy Aigbe, Tana Adelana shine at 10th edition". Pulse Nigeria. 2018-12-09. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ [nigeria.shafaqna.com "Nigeria News (News Reader)"] Check
|url=
value (help). Nigeria News (News Reader). 2020-10-16. Retrieved 2020-10-16. - ↑ "JUST IN: Nigeria’s Coronavirus cases slump further; total figures surpass 60,000". P.M. News. 2020-10-10. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ Ojoye, Taiwo (2019-08-18). "Many misuse social media –Mary Lazarus". Punch Newspapers. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ punchng (2017-07-02). "Modelling prevented me from making a first-class degree - Mary Lazarus". Punch Newspapers. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ "Winners Emerge @ 2018 City People Movie Awards". City People Magazine. 2018-09-24. Retrieved 2020-10-16.
- ↑ "AMVCA 2020". Africa Magic - AMVCA 2020. 2020-02-06. Retrieved 2020-10-16.