Matthew Blaise

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Matthew Nwozaku Chukwudi Blaise [1] jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó má ń jafitafita lórí àwọn ẹ̀tọ́ nípa queer.[2]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù kẹta ọdún 2020, lẹ́hìn tí wọ́n pa ọmọkùnrin Gay kan ní ilé Nàìjíríà, Blaise ṣe ìdásílẹ̀ ìpolongo lórí ẹ̀rọ ayélujára tí Twitter pẹ̀lú Ani Kayode, Somtochukwu àti Victor Emmanuel. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe àṣeyọrí nípa ṣíṣe ẹ̀dà hashtag tí wọ́n sọ ní "#EndHomophobiain Nigeria"" àṣà lórí ẹ̀rọ ayélujára tí ó jẹ́ Twitter àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

Lẹ́hìn tí ó ti wà ní àtìmọ́lé àti nínú ewu ti àwọn olópàá dìgbòlùjà tí wọ́n n dojú kọ àwọn adigunjalè fún ìwòye pé ó ń lówó nínú ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo, Blaise ṣe akitiyan nínú ti EndSARS ti tí ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹwàá ọdún 2020, níbití wọ́n ti buẹnuàtẹ́ lù wọ́n fún gbígbé àkọlé tí àwọn ọ̀rọ̀ orí rẹ ka báyìí pé "Queer Lives Matter."[3] Wọ́n tún ṣètò fún àwọn ẹgbẹ́ queer míràn láti darapọ̀ mọ́ àwọn ìwọ́de ẹ̀hónú yìí.

Lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ yín yin ìbọn pa àwọn tí wọ́n n fi ẹ̀hónú hàn ẹ̀yí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Lekki ní ọdún 2020, Blaise bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ Safe HQuse láti lè ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ queer ti wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn tí wọn kò sì ṣe àgbákò ikú

Ìgbésí ayé Blaise[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Blaise kìí ṣe alákọméjì àti wípé ó máa n lo àwọn ọ̀rọ̀ òye bíi wọ́n/wọ́n àti òun/òun. Títí di oṣù kẹwàá ọdún 2020 ni wọ́n tí ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìjọba àpapọ̀ ti Alexa Ekwueme ni orílè-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n sì nkó ẹ̀kọ́ láti gba oyè ìjìnlẹ̀ nínú èdè gèésì àti àwọn ẹ̀kọ́ ìwé-kíkọ.[4]

Blaise di ẹni tí ó tún bọ̀ ma ń sọ́rọ́ nípa ìbálòpọ̀ lórí àwùjọ media ti orí ẹ̀rọ ayélujára léhìn tí àlùfáà kan ti bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n fún híhu ìwà ìbàjẹ́ ní ọdún 2019, tí àwọn tí ó wà ní ilé ìjọsìn kò sì dá síi.

Ìdánimọ̀ rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Blaise jẹ́ adarí ọ̀dọ́ àwọn Women Deliver ní ọdún 2020. Wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún ní ìgbà náà. Ní ọdún 2020 bákannáà, àwọn ni wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ ti The Future Awards Africa fún aṣíwájú nípa ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti The Initiative for Equal Rights fún ajàfitafita ẹ̀tọ́ ti SOGIESC ní ọdún yẹn.[5] Ní oṣù kẹfà ọdún 2021, wọ́n fi ara hàn nínú fiimu kúkúrú kan tí Dafe Oboro ṣe, èyí tí ó wà ní ojú ewé àkọ́kọ́ ìtàn ti Dazed tí ó tẹ̀lé ìgbà èèrùn ti ọdún 2021.[6]

Àwọn àkọsílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Blaise máa ńlo àwọn ọrọ oyè bíi wọn/wọn ati òun/òun. Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ yìí ńlo àwọn ọ̀rọ̀ oyè bíi wọ́n/wọ́n nítorí kí àwọn ọ̀rọ̀ má baa tàsé ara wọn.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Are you a robot?". Bloomberg. 2021-03-12. Retrieved 2021-09-20. 
  2. Lagos, Nelson C.J / (2021-02-26). "Queer Nigerians Find Both Community, Bigotry on Clubhouse". Time. Retrieved 2021-09-20. 
  3. "End SARS: Queer Nigerians are being abused, humiliated and killed by a corrupt police unit – and it’s nothing new". PinkNews - Gay news, reviews and comment from the world's most read lesbian, gay, bisexual, and trans news service. 2020-10-21. Retrieved 2021-09-20. 
  4. "Matthew (Blaise) Nwozaku – Women Deliver". Women Deliver. 2020-06-23. Retrieved 2021-09-20. 
  5. Obi-Young, Otosirieze (2020-12-26). "The 2020 Freedom Awards Honour LGBTQ & Feminist Advocates". Open Country Mag. Retrieved 2021-09-20. 
  6. "Meet the resilient Nigerians leading the country’s youth revolution". Dazed. 2021-06-03. Retrieved 2021-09-20.