Memry Savanhu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Memry Savanhu
Ọjọ́ìbíMemry Savanhu
Zimbabwe
Orílẹ̀-èdèZimbabwean
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2008 - present
Gbajúmọ̀ fún
  • '76 (2016)
  • Maria's Vision (2014)
  • Distance Between (2008)

Memry Savanhu (tí a tún le kọ bíi Memory Savanhu ) jẹ́ òṣèré Nollywood ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Sìmbábúè, olùgbéré-jáde, àti olùṣòwò tí ó n gbé ní ìlú Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹ́hìn tí ó kó kúrò ní ìlú Lọ́ndọ̀nù. Ó ṣe àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Distance Between ní ọdún 2008.[1] Ó ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nollywood láti ìgbà náà tó fi mọ́ One Fine Day[2], On Bended Knees[3] àti '76. Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbéréjáde kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Memkay Productions.[4][5][6]

Ètò ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A gbọ́ wípé orílẹ̀-èdè Sìmbábúè ni wọ́n bí Savanhu sí, ó sì sọ di mímọ̀ pé ẹ̀yà Zezuru ni òún jẹ́. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ eré ṣíṣe ní ìlú Lọ́ndọ̀nù àti ìmọ̀ fíìmù ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York Film Academy tí ó wà ní Abu Dhabi, UAE.[7]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Savanhu ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe Distance Between ní ọdún 2008. Olùdarí eré náà ni Izu Ojukwu tí àwọn olùkópa síì pẹ̀lú Rita Dominic, Mercy Johnson, Kalu Ikeagwu àti Yemi Blaq. Lára àwọn eré rẹ̀ míran tí ó gbé jáde ni One Fine Day, Cougars Reloaded, Catwalq àti On Bended Knees. Ní ọdún 2016, ó kópa gẹ́gẹ́ bi "Eunice" nínu eré Izu Ojukwu kan tító dá lóri ìtàn ogun tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ '76.[8] Àwọn olùjọkópa rẹ̀ tún pẹ̀lú Rita Dominic, Ramsey Nouah, Chidi Mokeme, Ibinabo Fiberesima àti Daniel K. Daniel. Fíìmù náà jáde ní 3 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2016.[9][10][11]

Ní ọdún 2014, wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ "Best Actor UK Female" níbi ayẹyẹ Zulu African Academy Awards (ZAFAA), tí ó wáyé ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù Maria's Vision. [12]

Ní ọdún 2015, wọ́n tún yàán fún àmì-ẹ̀yẹ Sìmbábúè International Women Awards (ZIWA) tí ó wáyé ní ìlúBirmingham tí ó wà ní UK ní Oṣù Kẹẹ̀wá ọdún náà, gẹ́gẹ́bí ìwé ìròyìn The Herald ti Sìmbábúè ti ṣe gbe síta.[13]

Àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Fíìmù Ipa Akọ́sílẹ̀ Ìtọ́kasí
2016 '76 Actress (Eunice) Drama, Romance [14][15]
2015 One Fine Day Actress Drama, Romance [16]
2014 Maria's Vision Actress (Maria) Romance, Drama [17]
2013 On Bended Knees Actress Drama [18]
2009 Nnenda Actress Drama [19][20]
2008 Distance Between Producer Romance, Drama [21]

Eré tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Fíìmù Ipa Àkọsílẹ̀ Ìtọ́kasí
2012 - Catwalq (also Lagos Catwalk) Actress TV series, Soap opera, Drama [22][23][24]

Àwọn ìgbóríyìn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Ayẹyẹ Àmì-ẹ̀yẹ Èsì
2015 ZIWA Nollywood contribution Yàán
2014 ZAFAA Best Actor UK Female Yàán

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé ìròyìn Pulse Nigeria jẹ́ kó di mímọ̀ wípé Savanhu ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ti ní àwọn ọmọ méjì.[25]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Distance Between". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  2. "One Fine Day". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  3. "On Bended Knees". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  4. Kachingwe, Kelvin (August 17, 2014). "Zambian author writes Zim movie". Zambia Daily Mail. Retrieved November 19, 2020. 
  5. "Local Film Premieres in UK". Zimbabwe Online News. August 22, 2014. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  6. Mamazita! (January 20, 2011). "Five upcoming actresses to look out for in 2011!". Naija Rules!. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  7. "Memry Savanhu: From Zimbabwe with love". Guardian. November 19, 2016. Retrieved November 18, 2020. 
  8. Okoroafor, Cynthia (November 12, 2016). ""IT'S A VERY EXCITING TIME FOR NOLLYWOOD", SAYS CHIOMA UDE, AFRIFF FOUNDER, AS THE FILM FESTIVAL "EMBRACES THE WORLD" THIS YEAR". Ventures Africa. Retrieved November 18, 2020. 
  9. Augoye, Jayne (October 24, 2016). "Nollywood flick, 76, gets more laurel". Premium Times. Retrieved November 18, 2020. 
  10. Izuzu, Chibumga (September 11, 2016). "War drama "76" reveals an adept actress you should know". Pulse Nigeria. Retrieved November 18, 2020. 
  11. Mamazita! (January 20, 2011). "Five upcoming actresses to look out for in 2011!". Naija Rules!. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  12. "ZAFAA Global Awards 2014 Nominees announced". Zafaa.org. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  13. Tanyanyiwa, Peter (September 23, 2015). "Zimbabwe: Zim Actress Shines in Nigeria". All Africa. Harare: The Herald. Retrieved November 18, 2018. 
  14. "ANOTHER GREAT "NOLLYWOOD" FILM FOR THIS YEAR'S TIFF-GOERS TO SEE". Fordham PR. Retrieved November 18, 2020. 
  15. "'76 (2016)". IMDb. Retrieved November 18, 2020. 
  16. "One Fine Day". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  17. "Local Film Premieres in UK". Zimbabwe Online News. August 22, 2014. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  18. "On Bended Knees". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  19. "NNENDA (2009) - Film en Streaming |The best full movies playing, online and free.". French TV Movies. Retrieved November 19, 2020. 
  20. "Nnenda (2009)". IMDb. Retrieved November 18, 2020. 
  21. "Distance Between". Nollywood REinvented. Retrieved November 18, 2020. 
  22. "Lagos Catwalk". TVDb. Retrieved November 18, 2020. 
  23. "Lagos Catwalk". TV Time. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 18, 2020. 
  24. "PHOTOS: MEDIA LAUNCH OF CATWALQ TV SERIES". Loladeville. February 6, 2012. Archived from the original on October 8, 2021. Retrieved November 19, 2020. 
  25. Izuzu, Chibumga (September 11, 2016). "War drama "76" reveals an adept actress you should know". Pulse Nigeria. Retrieved November 18, 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]