Micheal Taiwo Akinkunmi
Micheal Táíwò Akínkúnmi OFR tí wọ́n bí ni ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún 1936,jẹ́ gbajúgbajà òṣìṣẹ́ se fẹ̀yìntì omo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó dìsáínì fúlàgì àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.Ìnagijẹ rẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni fúlàgì.[1][2]
Ìgbésí Ayé ati Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Akínkúnmi jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn,ẹ̀yà Yorùbá, ọmọtáyéwò àgbà ìbejì. Ó gbé pẹ̀lú bàbá rẹ̀ di ọmọ ọdún mẹ́jọ, ó ré kọjá sí apá Àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ́ọ́bẹ̀rẹ̀. Ó padà sí ìwọ̀-oòrùn fún Ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ífẹ̀yìntì bàbá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ní ilé ìwé alákọ́ọ́bẹ̀rẹ̀ Onítẹ̀bọmi, Ìdí ìkán Ìbàdàn. Ó pari ni ọdún 1949, o tún tẹ̀síwájú lọ sí ilé ìwé gíga Ìbàdàn Girama ni ọdún 1950. [3] Akínkúnmi gba ìṣe gẹ́gẹ́ bíi òṣìṣẹ́ àgbẹ̀ ni ile ijoba sekitéríátì ti ìwọ̀ oòrùn ní odún 1955, lẹ́yìn tí ó parí ilé ẹ̀kọ́ gíga girama. Lẹ́yìn tí ó kàwé díẹ̀, o tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ si Kóléjì Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Norwood ni Lọ́ńdọ́nù níbi tí o ti kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ iná.[4] Ìgbàtí ó ń kàwé ni ó dìsáínì fúlàgì orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó padà sí Nàìjíríà ní ọdún 1963, sí ẹ̀ka iṣé ní ilé ìjọba sẹkitéríàtì láti bẹ̀rẹ̀ iṣé níbi tí ó fi a dàgbà ètò rọ̀ sìí. Ó ṣiṣé di ọdún 1994 gẹ́gẹ́ bíi igbá kejì supiritẹńdẹńtì Àgbẹ̀. O gba àmìẹ̀yẹ OFR, olúbánidámọ̀ràn fún Olórí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ọjọ́ kọkàndínlógbọn, oṣù kẹsàn-án, ọdún 2014 ní gbọ̀ngàn ìgbàlejò,Àbújá.[5]
Igbesi Aye Lágbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Akínkúnmi fẹ́ ìyàwó, ó sì bí ọmọ.[6]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Agboluaje, Rotimi (2021-06-25). "Akinkunmi unveils world’s largest flag in Ibadan - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2022-10-26. Retrieved 2022-10-29.
- ↑ Aderinto, S. (2017). African Kingdoms: An Encyclopedia of Empires and Civilizations. ABC-CLIO. p. 113. ISBN 978-1-61069-580-0. https://books.google.com.ng/books?id=NZAwDwAAQBAJ&pg=PA113. Retrieved 2022-10-29.
- ↑ "Among all the houses on Emerald Street, Dugbe, Ibadan, Oyo State, Pa Michael Taiwo Akinkunmi's house stands out! Its uniqueness is neither because it is the most beautiful, nor the most expensive with the state-of-the-art facilities.". Encomium Magazine. 2022-10-29. Archived from the original on 2022-10-26. Retrieved 2022-10-29.
- ↑ National Youth Service Corps (Nigeria) (1991). NYSC Yearbook. The Corps. https://books.google.com.ng/books?id=L0MzAQAAIAAJ. Retrieved 2022-10-29.
- ↑ Yisau, Rukayat (2014-09-30). "Designer of Nigerian Flag, Steward, Driver, Traffic Warden Bag National Honours". TELL. Archived from the original on 2022-10-26. Retrieved 2022-10-29.
- ↑ "Biography of Mr Flag Man, Taiwo Akinkunmi". Boomentertainment. 2018-02-22. Retrieved 2022-10-29.