Mohammadu Maccido

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Muhammadu Maccido
Sultani ilu Sokoto
Orí-ìtẹ́1996-2006
Orí-oyè21 April 1996
AṣájúIbrahim Dasuki
Arọ́pọ̀Sa'adu Abubakar
BàbáSiddiq Abubakar III
ÌyáHauwa

Ibrahim Muhammadu Maccido dan Abubakar (20 April 1928 – 29 October 2006) lo je Sultani ilu Sokoto 19k (lati April 20, 1996, titi di ojo iku re ni odun 2006), olori agba ni ilu Sokoto ni apaariwa Nigeria, ati olori Nigerian National Supreme Council for Islamic Affairs. Gege bi Sultani Sokoto, won gba bi baba agba awon musulumi ni Naijiria[1]. Ohun lo sakojo fun ipade to waye ni ojo 7 Osu Keta 2000 ni Kaduna to fa idasile Arewa Consultative Forum waye lati soju awon itelogun Apaariwa ni Naijiria.[2]

Ni ojo 29 Osu Kewa, 2006, Maccido ku ninu ijanba baalu ADC Airlines Flight 53[3], lati Abuja losi Sokoto [4] lapapo mo opo awon onibise ijoba agba Ipinle Sokoto, ninu won na ni omo re, Badamasi Maccido (alagba asofin) wa, ati eyi tii se omoomo re kan soso.

Maccido ni omokunrin akoko fun Sultani 17k, Siddiq Abu Bakar dan Usuman, to wa nipo Sultani fun ju adota odun lo.[5] Maccido ko dipo baba re gege bi Sultani taarata. Leyin ti Ibrahim Dasuki, Sultani 18k, je fifowoofinmu, to si je lile kuro lori ite latowo Ogagun Sani Abacha to je olori ijoba ologun nigba na, Maccido je yiyan sipo bi Sultani.[6]


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Estelle Shirbon, Reuters (2006-10-30). "Nigerian plane crash kills 99". Retrieved 2007-01-17. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "History of Arewa Consultative Forum". NigerianBestForum. June 22, 2008. Retrieved 2010-04-02. 
  3. Boeing 737 — SBS TV News
  4. New York Times (October 29, 2006). "Jet With 104 Aboard Crashes in Nigeria". Retrieved 2007-01-17.  (registration required)
  5. John N. Paden, Dawodu.com. "The Sokoto Caliphate and its Legacies (1804-2004)". Retrieved 2007-01-17. 
  6. Abubakar Umar, Niger Delta Congress. "Maccido Marks Five". Archived from the original on 2004-10-20. Retrieved 2007-01-17. (dead as of June 10, 2007, at Internet Archive)