Moji Olaiya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Moji Olaiya
Ọjọ́ìbí (1975-02-27)Oṣù Kejì 27, 1975
Aláìsí May 17, 2017(2017-05-17) (ọmọ ọdún 42)
Canada
Iṣẹ́ eléré orí-ìtàǵe

Moji Olaiya (bíi ní ọjọ́kẹtàdínlọ̀gbọ̀n Oṣù kejì ọdùn 1975 – ọjọ́kẹtàdínlogún Oṣù karún ọdún 2017) jẹ́ eléré orí-ìtàǵe Yorùbá Ilẹ̀ Nàìjííria.[1]

Ise re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Moji jẹ́ omo Victor Olaiya gbaju-gbaja olorin highlife ile Nijiiria. Moji Olaiya bere ere ori-itage re pelu ile ise Wale Adenuga Super Story.[2] O kopa to laami laaka ninu awon osere Nollywood Yoruba ati Geesi lapapo.[3] Moji di gbaju-gbaja osere laarin awon akegbe re to ku latari ipa re to ko ninu ere Geesi ti a mo si No Pains No Gains, ni eyi ti o ti kopa gege bi Ireti, Sade Blade (2005), Nkan adun (2008) ati Omo iya meta leyi (2009). Bakan naa lo tun han ninu Agunbaniro. ni odun 2003. Won tun yaan fun ami eye idani-lola ti (The Reel Award Best Supporting Actress of the Year), bakan naa lo tun jawe olubori ninu idije ami eye 'Oserebinrin to dara julo' (Best New Actress Award) ni osu kejo odun 2016.[4]


ni odun 2016, Moji se fiimu ara kan jade,ti o pe ni, Iya Okomi,[5] to safiha awon osere akegbe re to ku bii: Foluke Daramola àti Funsho Adeolu, ni eyi ti won safihan re akoko ni gbongan ni Ilu-Eko ni osu keje.[6]

Igbesi Aye re[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Moji Olaiya se igbeyawo pelu Bayo Okesola ni odun 2007, ko pe ko jina won korawon sile.[7][8][9] Moji yi pada lati esin Kiristeni si esin Islam ni odun 2014 funra re.[10][11]

O ku ni ojo-ketadinlogun osu karun-un odun 2017, latari aisan Okan ni Ilu Canada, leyin osu meji ti o bimo keji.[12] ki olorun o bawa fOrun ke. O digba O di gbere.

Awon Ere ti O ti Kopa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Aje nile Olokun
 • Ojiji Aye
 • Apaadi
 • Omo Iya Meta leyi (2009)
 • Nkan adun (2008)
 • Sade Blade (2005)

Awon Itoni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Moji Olaiya: Photos from her 40th birthday bash". The Pulse. Retrieved 26 March 2015.  Unknown parameter |gauthor= ignored (help)
 2. "I was the breadwinner while my marriage lasted — Actress, Moji Olaiya". Nigerian Tribune. http://www.tribune.com.ng/news2013/index.php/en/component/k2/item/8979-i-was-the-breadwinner-while-my-marriage-lasted-actress-moji-olaiya. Retrieved 26 March 2015. 
 3. NONYE BEN-NWANKWO. "Fathia Balogun had nothing to do with my broken marriage – Moji Olaiya". The Punch. http://www.punchng.com/feature/moji-olaiya-on-her-broken-marriage-fathia-balogun-has-nothing-to-do-with-it/. 
 4. "Moji Olaiya". Naij.com. Retrieved 15 September 2016. 
 5. "Moji Olaiya’s movie “Iya Okomi” to premiere in July". Nigerian Pilot. 31 July 2016. Retrieved 15 September 2016. 
 6. "Moji Olaiya’s movie to premiere in July". Pulse. Retrieved 15 September 2016. 
 7. "Violence forced me out of Marriage". Modern Ghana. 31 January 2014. Retrieved 26 March 2015. 
 8. Mary Jane Eze. "I WISH I HAVE A MAN BESIDES ME @40- MOJI OLAIYA LAMENTS". Nigeria Films. 
 9. "Moji Olaiya left her husband because of domestic Violence". http://www.nollywoodmagazine.com/2015/01/moji-olaiya-actress-left-her-husband-because-of-domestic-violence.html. Retrieved 26 March 2015. 
 10. "Fabulous at 40! Fathia Balogun, Yomi Fash, Ronke Oshodi, Eniola Badmus, others party with Nollywood actress, Moji Olaiya (PHOTOS)". YNaija. Retrieved 26 March 2015. 
 11. "Nollywood Yoruba Movie Actress Moji Olaiya Cries ‘I don’t have any Alhaji lover’". Daily Mail. 3 November 2014. http://dailymail.com.ng/nollywood-yoruba-movie-actress-moji-olaiya-cries-i-dont-have-any-alhaji-lover/. Retrieved 16 March 2015. 
 12. "Veteran Yoruba movie actress, Moji Olaiya, is dead", by Jayne Augoye, Premium Times